Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Rúùtù 3:1-18

3  Wàyí o, Náómì ìyá ọkọ rẹ̀ sọ fún un pé: “Ọmọbìnrin mi, kò ha yẹ kí èmi wá ibi ìsinmi+ fún ọ, kí nǹkan lè lọ dáadáa fún ọ?  Wàyí o, ẹbí+ wa ọkùnrin ha kọ́ ni Bóásì, ẹni tí ìwọ ti wà pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́bìnrin rẹ̀? Wò ó! Òun yóò fẹ́+ ọkà bálì ní ilẹ̀ ìpakà ní òru òní.  Kí o sì wẹ̀, kí o sì fi òróró+ pa ara rẹ, kí o sì fi aṣọ àlàbora rẹ sára,+ kí o sì sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ilẹ̀ ìpakà náà. Má sọ ara rẹ di mímọ̀ fún ọkùnrin náà títí di ìgbà tí ó bá parí jíjẹ àti mímu.  Kí ó sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí ó bá dùbúlẹ̀, kí ìwọ pẹ̀lú ṣàkíyèsí ibi tí ó dùbúlẹ̀ sí; kí o sì wá, kí o ká aṣọ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀, kí o sì dùbúlẹ̀; òun ní tirẹ̀, yóò sì sọ ohun tí ó yẹ kí o ṣe fún ọ.”  Látàrí ìyẹn, ó wí fún un pé: “Gbogbo ohun tí o sọ fún mi ni èmi yóò ṣe.”  Ó sì tẹ̀ síwájú láti sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ilẹ̀ ìpakà, ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí ìyá ọkọ rẹ̀ ti pa láṣẹ fún un.  Láàárín àkókò náà, Bóásì mu, ó sì jẹ, ọkàn-àyà rẹ̀ sì jẹ̀gbádùn.+ Nígbà náà ni ó lọ dùbúlẹ̀ ní ìkángun òkìtì ọkà. Lẹ́yìn ìyẹn, ọmọbìnrin náà yọ́ lọ, ó sì ká aṣọ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì dùbúlẹ̀.  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọ̀gànjọ́ òru pé, ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí wárìrì. Nítorí náà, ó tẹ̀ sí iwájú, sì wò ó! obìnrin kan dùbúlẹ̀ síbi ẹsẹ̀ rẹ̀!  Nígbà náà ni ó wí pé: “Ta ni ọ́?” Ẹ̀wẹ̀, òun wí pé: “Èmi ni Rúùtù ẹrúbìnrin rẹ, kí o sì na apá gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ rẹ bo ẹrúbìnrin rẹ, nítorí ìwọ jẹ́ olùtúnnirà.”+ 10  Látàrí ìyẹn, ó wí pé: “Alábùkún ni ìwọ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà,+ ọmọbìnrin mi. Ìwọ ti fi inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́+ hàn lọ́nà tí ó dára ní ìgbà ìkẹyìn ju ti ìgbà àkọ́kọ́+ lọ, ní ti pé ìwọ kò tẹ̀ lé àwọn ọ̀dọ́ ènìyàn yálà ẹni rírẹlẹ̀ tàbí ọlọ́rọ̀. 11  Wàyí o, ọmọbìnrin mi, má fòyà. Gbogbo ohun tí o sọ ni èmi yóò ṣe fún ọ,+ nítorí gbogbo ẹni tí ó wà ní ẹnubodè àwọn ènìyàn mi mọ̀ pé ìwọ jẹ́ obìnrin+ títayọ lọ́lá. 12  Wàyí o, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òtítọ́ ni pé olùtúnnirà+ ni mo jẹ́, olùtúnnirà kan tún wà tí ó bá ọ tan tímọ́tímọ́ jù mí lọ.+ 13  Wọ̀ sí ìhín ní òru òní, kí ó sì ṣẹlẹ̀ ní òwúrọ̀ pé bí òun yóò bá tún ọ rà, ó dára púpọ̀! Jẹ́ kí ó ṣe àtúnrà+ náà. Ṣùgbọ́n bí kò bá ní inú dídùn sí títún ọ rà, nígbà náà, èmi yóò tún ọ rà, èmi fúnra mi, dájúdájú bí Jèhófà ti ń bẹ.+ Sùn títí di òwúrọ̀.” 14  Ó sì dùbúlẹ̀ síbi ẹsẹ̀ rẹ̀ títí di òwúrọ̀, lẹ́yìn náà, ó dìde kí ẹnì kan tó dá ẹnì kejì  mọ̀. Wàyí o, ó wí pé: “Má ṣe jẹ́ kí ó di mímọ̀ pé obìnrin kan wá sí ilẹ̀ ìpakà.”+ 15  Ọkùnrin náà sì ń bá a lọ láti wí pé: “Mú aṣọ ìlékè tí ó wà lára rẹ wá, kí o sì tẹ́ ẹ.” Nítorí náà, ó tẹ́ ẹ, ọkùnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí wọn òṣùwọ̀n mẹ́fà ọkà bálì, ọkùnrin náà sì gbé e rù ú, lẹ́yìn èyí, ọkùnrin náà lọ sínú ìlú ńlá. 16  Ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ ìyá ọkọ rẹ̀, ẹni tí ó sọ wàyí pé: “Ta ni ọ́, ọmọbìnrin mi?” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó sọ fún un nípa gbogbo ohun tí ọkùnrin náà ṣe fún òun. 17  Ó sì ń bá a lọ pé: “Òṣùwọ̀n mẹ́fà ọkà bálì yìí ni ó fún mi, nítorí ó wí fún mi pé, ‘Má lọ lọ́wọ́ òfo sọ́dọ̀ ìyá ọkọ+ rẹ.’” 18  Látàrí ìyẹn, ó wí pé: “Jókòó jẹ́ẹ́, ọmọbìnrin mi, títí di ìgbà tí o bá mọ ibi tí ọ̀ràn náà yóò já sí, nítorí ọkùnrin náà kì yóò sinmi, láìjẹ́ pé ó mú ọ̀ràn náà wá sí òpin lónìí.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé