Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Rúùtù 1:1-22

1  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé, ní àwọn ọjọ́ tí àwọn onídàájọ́+ ń ṣe ìdájọ́, ìyàn+ kan mú ní ilẹ̀ náà, ọkùnrin kan sì tẹ̀ síwájú láti kúrò ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ ní Júdà láti máa gbé gẹ́gẹ́ bí àtìpó ní pápá Móábù,+ òun àti aya rẹ̀ àti ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì .  Orúkọ ọkùnrin náà ń jẹ́ Élímélékì, orúkọ aya rẹ̀ sì ń jẹ́ Náómì, orúkọ ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì  sì ń jẹ́ Málónì àti Kílíónì, wọ́n jẹ́ ará Éfúrátà+ láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní Júdà. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n dé àwọn pápá Móábù, wọ́n sì ń bá a lọ láti wà níbẹ̀.  Nígbà tí ó ṣe, Élímélékì ọkọ Náómì kú, tí obìnrin náà fi wá wà pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì.  Lẹ́yìn náà, àwọn ọkùnrin náà fẹ́ aya fún ara wọn, àwọn obìnrin ará Móábù.+ Orúkọ ọ̀kan ń jẹ́ Ópà, orúkọ èkejì  sì ń jẹ́ Rúùtù.+ Wọ́n sì gbé ibẹ̀ fún nǹkan bí ọdún mẹ́wàá.  Nígbà tí ó ṣe, àwọn méjèèjì , Málónì àti Kílíónì, kú pẹ̀lú, tí obìnrin náà fi wà láìsí àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì  àti ọkọ rẹ̀.  Ó sì dìde pẹ̀lú àwọn aya ọmọ rẹ̀, ó sì padà láti àwọn pápá Móábù, nítorí ó ti gbọ́ ní pápá Móábù pé Jèhófà ti yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ̀+ nípa fífún wọn ní oúnjẹ.+  Ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ kúrò níbi tí ó wà tẹ́lẹ̀,+ àwọn aya ọmọ rẹ̀ méjèèjì  sì wà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì ń bá a lọ ní rírìn ní ojú ọ̀nà láti padà sí ilẹ̀ Júdà.  Níkẹyìn, Náómì sọ fún àwọn aya ọmọ rẹ̀ méjèèjì  pé: “Ẹ lọ, ẹ padà, olúkúlùkù sí ilé ìyá rẹ̀. Kí Jèhófà ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí yín,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe é sí àwọn ọkùnrin tí ó ti kú àti sí èmi.+  Kí Jèhófà fún yín ní ẹ̀bùn,+ kí ẹ sì rí ibi ìsinmi,+ olúkúlùkù ní ilé ọkọ rẹ̀.” Ó sì fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì ń sunkún. 10  Wọ́n sì ń wí fún un pé: “Rárá, ṣùgbọ́n àwa yóò bá ọ padà sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ.”+ 11  Ṣùgbọ́n Náómì wí pé: “Ẹ padà, ẹ̀yin ọmọbìnrin mi. Èé ṣe tí ẹ ó fi bá mi lọ? Èmi ha ṣì ní àwọn ọmọkùnrin síbẹ̀ ní ìhà inú mi, wọn yóò ha sì di ọkọ yín bí?+ 12  Ẹ padà, ẹ̀yin ọmọbìnrin mi, ẹ máa lọ, nítorí mo ti dàgbà jù láti ní ọkọ. Bí mo bá sọ pé mo ní ìrètí pẹ̀lú pé èmi yóò ní ọkọ dájúdájú ní òru òní, tí èmi yóò sì bí àwọn ọmọkùnrin pẹ̀lú,+ 13  ẹ ó ha dúró dè wọ́n títí wọn yóò fi dàgbà bí? Ẹ ó ha pa ara yín mọ́ sọ́tọ̀ fún wọn, kí ẹ má di ti ọkọ? Rárá, ẹ̀yin ọmọbìnrin mi, nítorí ó korò gan-an fún mi nítorí tiyín, pé ọwọ́ Jèhófà jáde lòdì sí mi.”+ 14  Látàrí ìyẹn, wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sunkún púpọ̀ sí i, lẹ́yìn èyí, Ópà fi ẹnu ko ìyá ọkọ rẹ̀ lẹ́nu. Ní ti Rúùtù, ó fà mọ́ ọn.+ 15  Nítorí náà, ó wí pé: “Wò ó! aya arákùnrin ọkọ rẹ tí ó ti di opó ti padà sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ àti àwọn ọlọ́run+ rẹ̀. Bá aya arákùnrin ọkọ rẹ+ tí ó ti di opó padà.” 16  Rúùtù sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Má rọ̀ mí láti pa ọ́ tì, láti padà lẹ́yìn rẹ; nítorí ibi tí o bá lọ ni èmi yóò lọ, ibi tí o bá sì sùn mọ́jú ni èmi yóò sùn mọ́jú.+ Àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi,+ Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi.+ 17  Ibi tí o bá kú sí ni èmi yóò kú sí,+ ibẹ̀ sì ni ibi tí a ó sin mí sí. Kí Jèhófà ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi, kí ó sì fi kún un,+ bí ohunkóhun yàtọ̀ sí ikú bá ya èmi àti ìwọ.” 18  Nígbà tí ó wá rí i pé, ó tẹpẹlẹ mọ́ bíbá òun lọ,+ nígbà náà, ó dẹ́kun bíbá a sọ̀rọ̀. 19  Àwọn méjèèjì  sì ń bá ọ̀nà wọn lọ títí wọ́n fi dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.+ Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí wọ́n dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ìrusókè bẹ́ sílẹ̀ ní gbogbo ìlú ńlá náà nítorí wọn,+ àwọn obìnrin sì ń wí ṣáá pé: “Ṣé Náómì+ nìyí?” 20  Òun a sì wí fún àwọn obìnrin náà pé: “Ẹ má pè mí ní Náómì. Márà ni kí ẹ máa pè mí, nítorí Olódùmarè+ ti mú kí ó korò gan-an fún mi.+ 21  Mo kún nígbà tí mo lọ,+ ní ọwọ́ òfo sì ni Jèhófà mú kí n padà.+ Èé ṣe tí ẹ̀yin yóò fi máa pè mí ní Náómì, nígbà tí ó jẹ́ pé Jèhófà ni ó tẹ́ mi lógo,+ Olódùmarè ni ó sì mú ìyọnu àjálù bá mi?”+ 22  Báyìí ni Náómì padà, Rúùtù obìnrin ará Móábù, aya ọmọ rẹ̀, wà pẹ̀lú rẹ̀ nígbà tí ó padà láti àwọn pápá Móábù;+ wọ́n sì wá sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ nígbà ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà bálì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé