Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Róòmù 9:1-33

9  Èmi ń sọ òtítọ́+ nínú Kristi; èmi kò purọ́,+ níwọ̀n bí ẹ̀rí-ọkàn mi ti ń jẹ́rìí pẹ̀lú mi nínú ẹ̀mí mímọ́,  pé mo ní ẹ̀dùn-ọkàn ńláǹlà àti ìrora tí kò dẹ́kun nínú ọkàn-àyà mi.+  Nítorí èmi ì bá fẹ́ pé kí a ya èmi fúnra mi sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni ègún kúrò lọ́dọ̀ Kristi nítorí àwọn arákùnrin mi,+ àwọn ìbátan mi lọ́nà ti ẹran ara,+  àwọn tí wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ àwọn tí ìsọdọmọ+ jẹ́ tiwọn àti ògo+ àti àwọn májẹ̀mú+ àti fífi Òfin+ fúnni àti iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀+ àti àwọn ìlérí;+  àwọn tí àwọn baba ńlá+ jẹ́ tiwọn àti láti ọ̀dọ̀ àwọn tí Kristi ti jáde wá lọ́nà ti ẹran ara:+ Ọlọ́run,+ ẹni tí ń bẹ lórí gbogbo gbòò, ni kí a fi ìbùkún fún títí láé. Àmín.  Bí ó ti wù kí ó rí, kì í ṣe bí ẹni pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti kùnà.+ Nítorí kì í ṣe gbogbo àwọn tí ó jáde wá láti inú Ísírẹ́lì ni “Ísírẹ́lì”+ ní ti gidi.  Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nítorí pé wọ́n jẹ́ irú-ọmọ Ábúráhámù ni gbogbo wọ́n fi jẹ́ ọmọ,+ ṣùgbọ́n: “Ohun tí a ó pè ní ‘irú-ọmọ rẹ’ yóò jẹ́ nípasẹ̀ Ísákì.”+  Ìyẹn ni pé, àwọn ọmọ nípa ti ara+ kì í ṣe àwọn ọmọ Ọlọ́run+ ní ti gidi, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ nípa ìlérí+ ni a kà sí irú-ọmọ náà.  Nítorí ọ̀rọ̀ ìlérí náà lọ báyìí pé: “Ní àkókò yìí, èmi yóò wá dájúdájú, Sárà yóò sì bí ọmọkùnrin kan.”+ 10  Síbẹ̀, kì í ṣe ọ̀ràn yẹn nìkan ṣoṣo, ṣùgbọ́n pẹ̀lú nígbà tí Rèbékà lóyún ìbejì+ fún ọkùnrin kan náà, Ísákì baba ńlá wa: 11  nítorí nígbà tí a kò tíì bí wọn tàbí tí wọn kò tíì ṣe ohunkóhun tí ó dára tàbí tí ó burú,+ kí ète Ọlọ́run nípa yíyàn má bàa máa sinmi lé àwọn iṣẹ́, bí kò ṣe lé Ẹni tí ń peni,+ 12  a sọ fún un pé: “Ẹ̀gbọ́n ni yóò jẹ́ ẹrú àbúrò.”+ 13  Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Jékọ́bù, ṣùgbọ́n Ísọ̀ ni mo kórìíra.”+ 14  Kí wá ni àwa yóò wí? Àìṣèdájọ́ òdodo ha wà pẹ̀lú Ọlọ́run bí?+ Kí èyíinì má ṣe rí bẹ́ẹ̀ láé! 15  Nítorí ó sọ fún Mósè pé: “Èmi yóò ṣe àánú fún ẹnì yòówù tí èmi yóò ṣe àánú fún, èmi yóò sì fi ìyọ́nú hàn sí ẹnì yòówù tí èmi yóò fi ìyọ́nú hàn sí.”+ 16  Nítorí bẹ́ẹ̀, kò sinmi lé ẹni tí ń fẹ́ tàbí lé ẹni tí ń sáré, bí kò ṣe lé Ọlọ́run,+ ẹni tí ń ṣe àánú.+ 17  Nítorí Ìwé Mímọ́ wí fún Fáráò pé: “Fún ìdí yìí gan-an ni mo ṣe jẹ́ kí o máa wà nìṣó, pé ní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí èmi lè fi agbára mi hàn, àti pé kí a lè polongo orúkọ mi ní gbogbo ilẹ̀ ayé.”+ 18  Nítorí bẹ́ẹ̀, ẹni tí ó bá fẹ́ ni ó ń ṣe àánú fún,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fẹ́ ni ó ń jẹ́ kí ó di olóríkunkun.+ 19  Nítorí náà, ìwọ yóò sọ fún mi pé: “Èé ṣe tí ó fi ń rí àléébù síbẹ̀? Nítorí ta ni ó ti dènà ìfẹ́ rẹ̀ ṣíṣe kedere?”+ 20  Ìwọ ènìyàn,+ ta wá ni ọ́ ní ti gidi, tí o fi ń ṣú Ọlọ́run lóhùn?+ Ǹjẹ́ ohun tí a mọ yóò ha sọ fún ẹni tí ó mọ ọ́n pé, “Èé ṣe tí o fi ṣe mí lọ́nà yìí?”+ 21  Kínla? Amọ̀kòkò+ kò ha ní ọlá àṣẹ lórí amọ̀ láti ṣe nínú ìṣùpọ̀ kan náà ohun èlò kan fún ìlò ọlọ́lá, òmíràn fún ìlò aláìlọ́lá?+ 22  Wàyí o, bí Ọlọ́run, bí ó tilẹ̀ ní ìfẹ́ láti fi ìrunú rẹ̀ hàn gbangba, kí ó sì sọ agbára rẹ̀ di mímọ̀, bá fi ọ̀pọ̀ ìpamọ́ra fàyè gba àwọn ohun èlò ìrunú tí a mú yẹ fún ìparun,+ 23  kí ó bàa lè sọ àwọn ọrọ̀+ ògo rẹ̀ di mímọ̀ lórí àwọn ohun èlò+ àánú, èyí tí ó pèsè sílẹ̀ tẹ́lẹ̀ fún ògo,+ 24  èyíinì ni, àwa, tí ó pè kì í ṣe láti àárín àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n láti àárín àwọn orílẹ̀-èdè+ pẹ̀lú, ìyẹn ńkọ́? 25  Ó rí bí ó ti sọ pẹ̀lú nínú Hóséà pé: “Àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi+ ni èmi yóò pè ní ‘àwọn ènìyàn mi,’ àti òun tí kì í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n tẹ́lẹ̀ ní ‘olùfẹ́ ọ̀wọ́n’;+ 26  àti ní ibi tí a ti sọ fún wọn pé, ‘Ẹ kì í ṣe ènìyàn mi,’ ibẹ̀ ni a ó ti pè wọ́n ní ‘àwọn ọmọ Ọlọ́run alààyè.’”+ 27  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Aísáyà ké jáde nípa Ísírẹ́lì pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè dà bí iyanrìn òkun,+ àṣẹ́kù kékeré ni a ó gbà là.+ 28  Nítorí Jèhófà yóò béèrè fún ìjíhìn lórí ilẹ̀ ayé, yóò parí rẹ̀, yóò sì ké e kúrú.”+ 29  Pẹ̀lúpẹ̀lù, gan-an gẹ́gẹ́ bí Aísáyà ti wí ní ìgbà ìṣáájú pé: “Bí kì í bá ṣe pé Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun+ ṣẹ́ irú-ọmọ kù sílẹ̀ fún wa, àwa ì bá ti dà bí Sódómù gan-an, à bá sì ti ṣe wa gẹ́gẹ́ bí Gòmórà+ gan-an.” 30  Kí wá ni àwa yóò wí? Pé àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò lépa òdodo, wọ́n bá òdodo,+ òdodo tí ń jẹyọ láti inú ìgbàgbọ́;+ 31  ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń lépa òfin òdodo, ọwọ́ rẹ̀ kò tẹ òfin náà.+ 32  Fún ìdí wo? Nítorí pé kò lépa rẹ̀ nípa ìgbàgbọ́, bí kò ṣe gẹ́gẹ́ bí nípa àwọn iṣẹ́.+ Wọ́n kọsẹ̀ lára “òkúta ìkọ̀sẹ̀” náà;+ 33  gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “Wò ó! Èmi yóò fi òkúta+ ìkọ̀sẹ̀ kan àti àpáta ràbàtà ìdìgbòlù+ kan lélẹ̀ ní Síónì, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ lé e kì yóò wá sí ìjákulẹ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé