Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Róòmù 8:1-39

8  Nítorí náà, àwọn tí wọ́n wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù kò ní ìdálẹ́bi kankan.+  Nítorí òfin+ ẹ̀mí+ yẹn, èyí tí ń fúnni ní ìyè+ ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù ti dá ọ sílẹ̀+ kúrò lọ́wọ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ti ikú.+  Nítorí, níwọ̀n bí àìgbéṣẹ́ ti wà níhà ti Òfin,+ nígbà tí ó jẹ́ aláìlera+ nípasẹ̀ ẹran ara, Ọlọ́run dá ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́bi nínú ẹran ara, nípa rírán Ọmọ+ tirẹ̀ ní ìrí ẹran ara+ ẹ̀ṣẹ̀ àti nítorí ẹ̀ṣẹ̀,+  kí a bàa lè mú ohun òdodo tí Òfin béèrè ṣẹ+ nínú àwa tí a ń rìn, kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara, bí kò ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí.+  Nítorí àwọn tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara gbé èrò inú wọn ka àwọn ohun ti ẹran ara,+ ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí gbé e ka àwọn ohun ti ẹ̀mí.+  Nítorí gbígbé èrò inú ka ẹran ara túmọ̀ sí ikú,+ ṣùgbọ́n gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí+ túmọ̀ sí ìyè àti àlàáfíà;  nítorí pé gbígbé èrò inú ka ẹran ara túmọ̀ sí ìṣọ̀tá+ pẹ̀lú Ọlọ́run, nítorí kò sí lábẹ́+ òfin Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni, ní ti gidi, kò lè rí bẹ́ẹ̀.  Nítorí náà, àwọn tí wọ́n wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara+ kò lè wu Ọlọ́run.  Àmọ́ ṣá o, ẹ̀yin kò sí ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara, bí kò ṣe pẹ̀lú ẹ̀mí,+ bí ó bá jẹ́ pé òótọ́ ni ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú yín.+ Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni kò bá ní ẹ̀mí Kristi,+ ẹni yìí kì í ṣe tirẹ̀. 10  Ṣùgbọ́n bí Kristi bá wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú yín,+ ara jẹ́ òkú ní tòótọ́ ní tìtorí ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀mí jẹ́ ìyè+ ní tìtorí òdodo. 11  Wàyí o, bí ẹ̀mí ẹni tí ó gbé Jésù dìde kúrò nínú òkú bá ń gbé inú yín, ẹni tí ó gbé Kristi Jésù dìde kúrò nínú òkú+ yóò sọ ara kíkú yín di ààyè+ pẹ̀lú nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀ tí ń gbé inú yín. 12  Nítorí bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ará, àwa wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe, kì í ṣe sí ẹran ara láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara;+ 13  nítorí bí ẹ bá ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara, ó dájú pé ẹ óò kú;+ ṣùgbọ́n bí ẹ bá fi ikú+ pa àwọn ìṣe ti ara nípasẹ̀ ẹ̀mí, ẹ ó yè. 14  Nítorí gbogbo àwọn tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń ṣamọ̀nà, àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Ọlọ́run.+ 15  Nítorí ẹ kò gba ẹ̀mí ìsìnrú tí ó tún ń fa ìbẹ̀rù,+ ṣùgbọ́n ẹ̀yin gba ẹ̀mí+ ìsọdọmọ,+ nípasẹ̀ ẹ̀mí tí àwa ń ké jáde pé: “Ábà,+ Baba!” 16  Ẹ̀mí+ tìkára rẹ̀ ń jẹ́rìí+ pẹ̀lú ẹ̀mí+ wa pé àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run.+ 17  Nígbà náà, bí àwa bá jẹ́ ọmọ, ajogún ni wá pẹ̀lú: àwọn ajogún Ọlọ́run ní tòótọ́, ṣùgbọ́n àwọn ajùmọ̀jogún+ pẹ̀lú Kristi, kìkì bí a bá jọ jìyà+ pa pọ̀, kí a lè ṣe wá lógo pa pọ̀ pẹ̀lú.+ 18  Nítorí náà, mo ṣírò rẹ̀ pé àwọn ìjìyà+ àsìkò ìsinsìnyí kò jámọ́ ohunkóhun ní ìfiwéra pẹ̀lú ògo+ tí a óò ṣí payá nínú wa. 19  Nítorí ìfojúsọ́nà+ oníhàáragàgà ìṣẹ̀dá+ ń dúró de ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run.+ 20  Nítorí a tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo,+ kì í ṣe nípasẹ̀ ìfẹ́ òun fúnra rẹ̀, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ẹni tí ó tẹ̀ ẹ́ lórí ba, nítorí ìrètí+ 21  pé a óò dá ìṣẹ̀dá+ tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sílẹ̀+ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run. 22  Nítorí àwa mọ̀ pé gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀ títí di ìsinsìnyí. 23  Kì í ṣe èyíinì nìkan, ṣùgbọ́n àwa fúnra wa pẹ̀lú tí a ní àkọ́so,+ èyíinì ni, ẹ̀mí náà, bẹ́ẹ̀ ni, àwa fúnra wa ń kérora+ nínú ara wa, bí a ti ń fi taratara dúró de ìsọdọmọ,+ ìtúsílẹ̀ kúrò nínú ara wa nípasẹ̀ ìràpadà. 24  Nítorí a gbà wá là nínú ìrètí yìí;+ ṣùgbọ́n ìrètí tí a bá rí kì í ṣe ìrètí mọ́, nítorí nígbà tí ẹnì kan bá rí ohun kan, ó ha máa ń retí rẹ̀ bí? 25  Ṣùgbọ́n bí a bá ń retí+ ohun tí a kò rí,+ a óò máa bá a nìṣó ní dídúró dè é pẹ̀lú ìfaradà.+ 26  Lọ́nà kan náà, ẹ̀mí+ pẹ̀lú dara pọ̀ mọ́ ìrànlọ́wọ́ fún àìlera wa;+ nítorí ìṣòro ohun tí àwa ì bá máa gbàdúrà fún bí ó ti yẹ kí a ṣe ni àwa kò mọ̀,+ ṣùgbọ́n ẹ̀mí+ tìkára rẹ̀ ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wa pẹ̀lú àwọn ìkérora tí a kò sọ jáde. 27  Síbẹ̀síbẹ̀, ẹni tí ń wá inú ọkàn-àyà+ mọ ohun tí ẹ̀mí+ túmọ̀ sí, nítorí ó ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú Ọlọ́run fún àwọn ẹni mímọ́.+ 28  Wàyí o, a mọ̀ pé Ọlọ́run ń mú kí gbogbo iṣẹ́+ rẹ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ fún ire àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí í ṣe àwọn tí a pè ní ìbámu pẹ̀lú ète rẹ̀;+ 29  nítorí àwọn tí ó fún ní àkànṣe àfiyèsí+ rẹ̀ àkọ́kọ́ ni ó yàn ṣáájú+ pẹ̀lú láti ṣe wọ́n ní+ àwòrán+ Ọmọ rẹ̀, kí ó lè jẹ́ àkọ́bí+ láàárín ọ̀pọ̀ arákùnrin.+ 30  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn tí ó yàn ṣáájú+ ni àwọn tí ó pè pẹ̀lú;+ àwọn tí ó sì pè ni àwọn tí ó polongo ní olódodo pẹ̀lú.+ Níkẹyìn, àwọn tí ó polongo ní olododo ni àwọn tí ó ṣe lógo pẹ̀lú.+ 31  Kí wá ni àwa yóò sọ sí nǹkan wọ̀nyí? Bí Ọlọ́run bá wà fún wa, ta ni yóò wà lòdì sí wa?+ 32  Ẹni tí kò dá Ọmọ+ tirẹ̀ pàápàá sí, ṣùgbọ́n tí ó jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ fún gbogbo wa,+ èé ṣe tí òun kò ní tún fi inú rere fún wa ní gbogbo ohun yòókù pẹ̀lú rẹ̀?+ 33  Ta ni yóò fi ẹ̀sùn kan àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run?+ Ọlọ́run ni Ẹni tí ó polongo wọn ní olódodo.+ 34  Ta ni ẹni tí yóò dáni lẹ́bi? Kristi Jésù ni ẹni tí ó kú, bẹ́ẹ̀ ni, jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹni tí a gbé dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún+ Ọlọ́run, ẹni tí ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wa pẹ̀lú.+ 35  Ta ni yóò yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kristi?+ Ṣé ìpọ́njú ni tàbí wàhálà tàbí inúnibíni tàbí ebi tàbí ìhòòhò tàbí ewu tàbí idà?+ 36  Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “Nítorí tìrẹ ni a ṣe ń fi ikú pa wá láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀, a ti kà wá sí àgùntàn fún pípa.”+ 37  Kàkà bẹ́ẹ̀, nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, àwa ń di ajagunmólú+ pátápátá nípasẹ̀ ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ wa. 38  Nítorí mo gbà gbọ́ dájú pé kì í ṣe ikú tàbí ìyè+ tàbí àwọn áńgẹ́lì+ tàbí àwọn ìjọba+ tàbí àwọn ohun tí ó wà níhìn-ín nísinsìnyí tàbí àwọn ohun tí ń bọ̀ tàbí àwọn agbára+ 39  tàbí ibi gíga tàbí ibi jíjìn tàbí ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn ni yóò lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà nínú Kristi Jésù Olúwa wa.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé