Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Róòmù 7:1-25

7  Ó ha lè jẹ́ pé ẹ kò mọ̀, ẹ̀yin ará, (nítorí àwọn tí ó mọ òfin ni èmi ń bá sọ̀rọ̀,) pé Òfin jẹ́ ọ̀gá lórí ènìyàn kan níwọ̀n ìgbà tí ó bá wà láàyè?+  Fún àpẹẹrẹ, òfin de obìnrin tí a gbé níyàwó mọ́ ọkọ rẹ̀ nígbà tí ọkùnrin náà wà láàyè; ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá kú, a dá a sílẹ̀ kúrò nínú òfin ọkọ rẹ̀.+  Nítorí bẹ́ẹ̀, nígbà tí ọkọ rẹ̀ wà láàyè, a ó pè é ní panṣágà obìnrin bí ó bá di ti ọkùnrin mìíràn.+ Ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó di òmìnira kúrò nínú òfin rẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé kì í ṣe panṣágà obìnrin bí ó bá di ti ọkùnrin mìíràn.+  Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi, ẹ̀yin pẹ̀lú ni a sọ di òkú sí Òfin+ nípasẹ̀ ara Kristi, kí ẹ lè di ti ẹlòmíràn,+ ti ẹni tí a gbé dìde kúrò nínú òkú,+ kí a lè so èso+ fún Ọlọ́run.  Nítorí nígbà tí àwa wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara,+ àwọn ìfẹ́ onígbòónára tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀ tí Òfin ru sókè wà lẹ́nu iṣẹ́ nínú àwọn ẹ̀yà ara wa, kí a lè mú èso jáde fún ikú.+  Ṣùgbọ́n nísinsìnyí a ti dá wa sílẹ̀ kúrò nínú Òfin,+ nítorí a ti kú+ sí èyíinì tí a fi ń dè wá pinpin tẹ́lẹ̀ rí, kí a lè jẹ́ ẹrú+ ní ọ̀nà tuntun nípasẹ̀ ẹ̀mí,+ kì í sì í ṣe ní ọ̀nà àtijọ́ nípasẹ̀ àkójọ òfin tí a kọ sílẹ̀.+  Kí wá ni àwa yóò wí? Òfin ha jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ bí?+ Kí èyíinì má ṣe rí bẹ́ẹ̀ láé! Ní ti gidi, èmi kì bá wá mọ ẹ̀ṣẹ̀+ bí kì í bá ṣe nítorí Òfin; àti pé, fún àpẹẹrẹ, èmi kì bá mọ ojúkòkòrò+ bí kì í bá ṣe pé Òfin wí pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣojúkòkòrò.”+  Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀, ní gbígba ìsúnniṣe nípasẹ̀ àṣẹ,+ ṣiṣẹ́ yọrí sí onírúurú ojúkòkòrò gbogbo nínú mi, nítorí láìsí òfin, ẹ̀ṣẹ̀ di òkú.+  Ní ti tòótọ́, mo wà láàyè nígbà kan rí láìsí òfin;+ ṣùgbọ́n nígbà tí àṣẹ dé,+ ẹ̀ṣẹ̀ tún wá sí ìyè, ṣùgbọ́n èmi kú.+ 10  Àṣẹ tí ó sì jẹ́ sí ìyè,+ èyí ni èmi rí pé ó jẹ́ sí ikú.+ 11  Nítorí ẹ̀ṣẹ̀, ní gbígba ìsúnniṣe nípasẹ̀ àṣẹ, sún mi dẹ́ṣẹ̀,+ ó sì pa mí nípasẹ̀ rẹ̀. 12  Nítorí náà, ní tirẹ̀, Òfin jẹ́ mímọ́,+ àṣẹ sì jẹ́ mímọ́, ó sì jẹ́ òdodo,+ ó sì dára.+ 13  Ǹjẹ́, nígbà náà, ohun rere ha di ikú fún mi bí? Kí èyíinì má ṣẹlẹ̀ láé! Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ dà bẹ́ẹ̀, kí a lè fi í hàn bí ẹ̀ṣẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ yọrí sí ikú fún mi nípasẹ̀ èyíinì tí ó jẹ́ rere;+ kí ẹ̀ṣẹ̀ bàa lè túbọ̀ kún fún ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ sí i nípasẹ̀ àṣẹ.+ 14  Nítorí a mọ̀ pé Òfin jẹ́ ti ẹ̀mí;+ ṣùgbọ́n èmi jẹ́ ẹlẹ́ran ara, tí a ti tà sábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.+ 15  Nítorí ohun tí mo ń ṣe ni èmi kò mọ̀. Nítorí ohun tí mo ń fẹ́, èyí ni èmi kò fi ṣe ìwà hù; ṣùgbọ́n ohun tí mo kórìíra ni èmi ń ṣe. 16  Bí ó ti wù kí ó rí, bí ó bá jẹ́ pé ohun tí èmi kò fẹ́ ni èmi ń ṣe,+ mo gbà pé Òfin dára púpọ̀.+ 17  Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ẹni tí ń ṣe é kì í ṣe èmi mọ́, bí kò ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mi.+ 18  Nítorí mo mọ̀ pé nínú mi, èyíinì ni, nínú ẹran ara mi, kò sí ohun rere tí ń gbé ibẹ̀;+ nítorí agbára àti-fẹ́-ṣe+ wà pẹ̀lú mi, ṣùgbọ́n agbára àtiṣe+ ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ kò sí. 19  Nítorí rere tí mo fẹ́ ni èmi kò ṣe,+ ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò fẹ́ ni èmi fi ń ṣe ìwà hù. 20  Wàyí o, bí ó bá jẹ́ pé ohun tí èmi kò fẹ́ ni èmi ń ṣe, ẹni tí ń ṣe é kì í ṣe èmi mọ́, bí kò ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mi.+ 21  Mo wá rí òfin yìí nínú ọ̀ràn tèmi: pé nígbà tí mo bá fẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́,+ ohun tí ó burú a máa wà pẹ̀lú mi.+ 22  Ní ti gidi, mo ní inú dídùn+ sí òfin Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ẹni+ tí mo jẹ́ ní inú, 23  ṣùgbọ́n mo rí òfin mìíràn nínú àwọn ẹ̀yà ara mi+ tí ń bá òfin èrò inú+ mi jagun,+ tí ó sì ń mú mi lọ ní òǹdè fún òfin ẹ̀ṣẹ̀+ tí ó wà nínú àwọn ẹ̀yà ara mi. 24  Èmi abòṣì ènìyàn! Ta ni yóò gbà mí lọ́wọ́ ara tí ń kú ikú yìí?+ 25  Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa!+ Nítorí bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú èrò inú mi, èmi fúnra mi jẹ́ ẹrú fún òfin Ọlọ́run,+ ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹran ara mi, mo jẹ́ ẹrú fún òfin ẹ̀ṣẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé