Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Róòmù 6:1-23

6  Nítorí náà, kí ni àwa yóò wí? Àwa yóò ha máa bá a lọ nínú ẹ̀ṣẹ̀, kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí lè di púpọ̀ gidigidi bí?+  Kí èyíinì má ṣẹlẹ̀ láé! Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé a kú ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀,+ báwo ni àwa yóò ṣe tún máa wà láàyè nìṣó nínú rẹ̀?+  Tàbí ẹ kò mọ̀ pé gbogbo wa tí a ti batisí sínú Kristi Jésù+ ni a batisí sínú ikú rẹ̀?+  Nítorí náà, a sin+ wá pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípasẹ̀ ìbatisí wa sínú ikú rẹ̀, kí ó bàa lè jẹ́ pé gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti gbé Kristi dìde kúrò nínú òkú nípasẹ̀ ògo Baba,+ kí àwa pẹ̀lú lè máa rìn bákan náà nínú ọ̀tun ìwàláàyè.+  Nítorí bí a bá ti di sísopọ̀ ṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀ ní ìfarajọ ikú rẹ̀,+ dájúdájú, a ó so wá pọ̀ ṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀ ní ìfarajọ àjíǹde rẹ̀ pẹ̀lú;+  nítorí àwa mọ̀ pé ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà wa ni a kàn mọ́gi pẹ̀lú rẹ̀,+ kí a lè sọ ara wa tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀ di aláìṣiṣẹ́,+ kí a má ṣe tún máa bá a lọ ní jíjẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.+  Nítorí ẹni tí ó bá ti kú ni a ti dá sílẹ̀ pátápátá kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.+  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí àwa bá ti kú pẹ̀lú Kristi, a gbà gbọ́ pé a óò tún wà láàyè pẹ̀lú rẹ̀.+  Nítorí a mọ̀ pé Kristi, nísinsìnyí tí a ti gbé e dìde kúrò nínú òkú,+ kò tún kú mọ́;+ ikú kò tún jẹ́ ọ̀gá lórí rẹ̀ mọ́. 10  Nítorí ikú tí ó kú, ni ó kú ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún kú mọ́ láé;+ ṣùgbọ́n ìgbésí ayé tí ó ń gbé, ni ó ń gbé ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.+ 11  Bákan náà pẹ̀lú ni ẹ̀yin: ẹ ka ara yín sí òkú+ ní tòótọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ ṣùgbọ́n alààyè+ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi Jésù. 12  Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ máa bá a lọ láti ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba+ nínú àwọn ara kíkú yín, tí ẹ ó fi máa ṣègbọràn sí àwọn ìfẹ́-ọkàn wọn.+ 13  Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe máa bá a lọ ní jíjọ̀wọ́ àwọn ẹ̀yà ara yín fún ẹ̀ṣẹ̀+ bí àwọn ohun ìjà àìṣòdodo,+ ṣùgbọ́n ẹ jọ̀wọ́ ara yín fún Ọlọ́run bí àwọn tí ó wà láàyè+ láti inú òkú, àti àwọn ẹ̀yà ara yín pẹ̀lú fún Ọlọ́run bí àwọn ohun ìjà+ òdodo. 14  Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ kò gbọ́dọ̀ jẹ ọ̀gá lórí yín, níwọ̀n bí ẹ kò ti sí lábẹ́ òfin+ bí kò ṣe lábẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí.+ 15  Kí ní tẹ̀ lé e? Àwa yóò ha dá ẹ̀ṣẹ̀ nítorí a kò sí lábẹ́ òfin+ bí kò ṣe lábẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí?+ Kí èyíinì má ṣẹlẹ̀ láé! 16  Ẹ kò ha mọ̀ pé bí ẹ bá ń jọ̀wọ́ ara yín fún ẹnikẹ́ni bí ẹrú láti ṣègbọràn sí i, ẹ̀yin jẹ́ ẹrú rẹ̀ nítorí ẹ ń ṣègbọràn sí i,+ yálà ti ẹ̀ṣẹ̀+ pẹ̀lú ikú níwájú+ tàbí ti ìgbọràn+ pẹ̀lú òdodo+ níwájú? 17  Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run pé ẹ̀yin ti jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí, ṣùgbọ́n ẹ di onígbọràn láti inú ọkàn-àyà wá sí irú ẹ̀kọ́ tí a fi yín lé lọ́wọ́.+ 18  Bẹ́ẹ̀ ni, níwọ̀n bí a ti dá yín sílẹ̀+ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, ẹ di ẹrú+ fún òdodo.+ 19  Èmi ń sọ̀rọ̀ ní ìsọ̀rọ̀ ẹ̀dá ènìyàn nítorí àìlera ẹran ara yín:+ nítorí àní gẹ́gẹ́ bí ẹ ti jọ̀wọ́ àwọn ẹ̀yà ara yín+ bí ẹrú fún ìwà àìmọ́+ àti ìwà àìlófin pẹ̀lú ìwà àìlófin níwájú,+ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí ẹ jọ̀wọ́ àwọn ẹ̀yà ara yín nísinsìnyí bí ẹrú fún òdodo pẹ̀lú ìjẹ́mímọ́ níwájú. 20  Nítorí nígbà tí ẹ jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀,+ ẹ jẹ́ òmìnira ní ti òdodo. 21  Kí wá ni èso+ tí ẹ máa ń so ní àkókò yẹn? Àwọn ohun+ tí ń tì yín lójú nísinsìnyí. Nítorí òpin nǹkan wọnnì ikú ni.+ 22  Àmọ́ ṣá o, nísinsìnyí, nítorí pé a ti dá yín sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n tí ẹ ti di ẹrú fún Ọlọ́run,+ ẹ ń so èso+ yín lọ́nà ìjẹ́mímọ́, ìyè àìnípẹ̀kun sì ni òpin rẹ̀.+ 23  Nítorí owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú,+ ṣùgbọ́n ẹ̀bùn+ tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun+ nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé