Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Róòmù 5:1-21

5  Nítorí náà, nísinsìnyí tí a ti polongo wa ní olódodo nítorí ìgbàgbọ́,+ ẹ jẹ́ kí a máa gbádùn àlàáfíà+ pẹ̀lú Ọlọ́run nípasẹ̀ Olúwa wa Jésù Kristi,  ẹni tí àwa pẹ̀lú tipasẹ̀ rẹ̀ rí ọ̀nà ìwọlé+ wa nípa ìgbàgbọ́ sínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí yìí nínú èyí tí àwa dúró nísinsìnyí; kí ẹ sì jẹ́ kí a máa yọ ayọ̀ ńláǹlà, lórí ìpìlẹ̀ ìrètí+ ògo Ọlọ́run.  Kì í sì í ṣe èyíinì nìkan, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nígbà tí a bá wà nínú ìpọ́njú,+ níwọ̀n bí a ti mọ̀ pé ìpọ́njú ń mú ìfaradà wá;+  ìfaradà, ní tirẹ̀, ipò ìtẹ́wọ́gbà;+ ipò ìtẹ́wọ́gbà, ní tirẹ̀, ìrètí,+  ìrètí náà kì í sì í ṣamọ̀nà sí ìjákulẹ̀;+ nítorí a ti tú ìfẹ́ Ọlọ́run+ jáde sínú ọkàn-àyà+ wa nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́,+ èyí tí a fi fún wa.  Nítorí, ní tòótọ́, nígbà tí àwa ṣì jẹ́ aláìlera,+ Kristi kú fún àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ní àkókò tí a yàn kalẹ̀.+  Nítorí èkukáká ni ẹnikẹ́ni yóò fi kú fún olódodo;+ ní tòótọ́, bóyá ni ẹnì kan á gbójúgbóyà láti kú+ fún ènìyàn rere.+  Ṣùgbọ́n Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́+ tirẹ̀ fún wa ní ti pé, nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.+  Mélòómélòó, nígbà náà, níwọ̀n bí a ti polongo wa ní olódodo nísinsìnyí nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀,+ ni a ó tipasẹ̀ rẹ̀ gbà wá là kúrò nínú ìrunú.+ 10  Nítorí bí ó bá jẹ́ pé, nígbà tí àwa jẹ́ ọ̀tá,+ a mú wa padà bá Ọlọ́run rẹ́ nípasẹ̀ ikú Ọmọ rẹ̀,+ mélòómélòó, nísinsìnyí tí a ti mú wa padà rẹ́, ni a ó gbà wá là nípasẹ̀ ìyè rẹ̀.+ 11  Kì í sì í ṣe èyíinì nìkan, ṣùgbọ́n a tún ń yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú Ọlọ́run nípasẹ̀ Olúwa wa Jésù Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí àwa nísinsìnyí ti rí ìpadàrẹ́+ gbà. 12  Ìdí nìyẹn tí ó fi jẹ́ pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan+ wọ ayé àti ikú+ nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀+—. 13  Nítorí kí Òfin tó dé ni ẹ̀ṣẹ̀ ti wà ní ayé, ṣùgbọ́n a kì í ka ẹ̀ṣẹ̀ sí ẹnikẹ́ni lọ́rùn nígbà tí kò bá sí òfin.+ 14  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ikú ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba láti ọ̀dọ̀ Ádámù títí dé ọ̀dọ̀ Mósè,+ àní lórí àwọn tí kò dẹ́ṣẹ̀ ní ìfarajọ ìrélànàkọjá Ádámù,+ ẹni tí ó ní ìjọra pẹ̀lú ẹni tí ń bọ̀.+ 15  Ṣùgbọ́n kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti rí pẹ̀lú ẹ̀bùn náà ni ó rí pẹ̀lú àṣemáṣe. Nítorí bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ bá kú nípasẹ̀ àṣemáṣe ọkùnrin kan, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run àti ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí nípasẹ̀ ọkùnrin kan+ Jésù Kristi pọ̀ gidigidi jù bẹ́ẹ̀ lọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn.+ 16  Pẹ̀lúpẹ̀lù, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti rí pẹ̀lú ẹ̀bùn ọ̀fẹ́+ náà ni ó rí pẹ̀lú ọ̀nà tí àwọn nǹkan gbà ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ ọkùnrin tí ó dẹ́ṣẹ̀.+ Nítorí ìdájọ́+ náà yọrí láti inú àṣemáṣe kan sí ìdálẹ́bi,+ ṣùgbọ́n ẹ̀bùn náà yọrí láti inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣemáṣe sí ìpolongo òdodo.+ 17  Nítorí bí ó bá jẹ́ nípa àṣemáṣe ọkùnrin kan+ ni ikú ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba+ nípasẹ̀ ẹni yẹn, mélòómélòó ni àwọn tí ń gba ọ̀pọ̀ yanturu inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ àti ẹ̀bùn ọ̀fẹ́+ òdodo yóò ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba+ nínú ìyè nípasẹ̀ ènìyàn kan, Jésù Kristi.+ 18  Nítorí bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ àṣemáṣe kan ìyọrísí náà fún onírúurú ènìyàn gbogbo jẹ́ ìdálẹ́bi,+ bákan náà pẹ̀lú ni ó jẹ́ pé nípasẹ̀ ìṣe ìdáláre+ kan ìyọrísí náà fún onírúurú ènìyàn gbogbo+ jẹ́ pípolongo wọn ní olódodo fún ìyè.+ 19  Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ àìgbọràn ènìyàn kan ọ̀pọ̀ ènìyàn+ ni a sọ di ẹlẹ́ṣẹ̀, bákan náà pẹ̀lú ni ó jẹ́ pé nípasẹ̀ ìgbọràn+ ènìyàn kan, ọ̀pọ̀ ènìyàn+ ni a ó sọ di olódodo.+ 20  Wàyí o, Òfin+ wọlé pẹ̀lú kí àṣemáṣe lè di púpọ̀ gidigidi.+ Ṣùgbọ́n ní ibi tí ẹ̀ṣẹ̀+ bá ti di púpọ̀ gidigidi, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ túbọ̀ di púpọ̀ gidigidi sí i. 21  Fún ète wo? Pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú ikú,+ bákan náà pẹ̀lú kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ lè ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba nípasẹ̀ òdodo pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun+ níwájú nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé