Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Róòmù 4:1-25

4  Bí èyíinì ti rí bẹ́ẹ̀, kí ni àwa yóò sọ nípa Ábúráhámù baba ńlá wa+ lọ́nà ti ẹran ara?  Fún àpẹẹrẹ, bí a bá polongo Ábúráhámù ní olódodo nítorí àwọn iṣẹ́,+ òun yóò ní ìdí fún ṣíṣògo; ṣùgbọ́n kì í ṣe lọ́dọ̀ Ọlọ́run.  Nítorí kí ni ìwé mímọ́ wí? “Ábúráhámù ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, a sì kà á sí òdodo fún un.”+  Wàyí o, lójú ẹni tí ń ṣiṣẹ́,+ owó iṣẹ́ ni a kò kà sí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí,+ ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí gbèsè.+  Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, fún ènìyàn tí kò ṣiṣẹ́ ṣùgbọ́n tí ó ní ìgbàgbọ́+ nínú ẹni tí ó polongo aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ní olódodo, ìgbàgbọ́ rẹ̀ ni a kà sí òdodo.+  Gan-an gẹ́gẹ́ bí Dáfídì pẹ̀lú ti sọ̀rọ̀ nípa ayọ̀ ènìyàn tí Ọlọ́run ka òdodo fún láìka àwọn iṣẹ́ sí, pé:  “Aláyọ̀ ni àwọn tí a ti dárí àwọn ìṣe àìlófin wọn jì,+ tí a sì ti bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀;+  aláyọ̀ ni ènìyàn tí Jèhófà kì yóò ka ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sí lọ́rùn lọ́nàkọnà.”+  Ǹjẹ́ ayọ̀ yìí, nígbà náà, ha wá sórí àwọn ènìyàn tí ó dádọ̀dọ́ tàbí sórí àwọn aláìdádọ̀dọ́+ pẹ̀lú? Nítorí a sọ pé: “Ìgbàgbọ́ rẹ̀ ni a kà sí òdodo fún Ábúráhámù.”+ 10  Lábẹ́ àwọn ipò wo ni a ti kà á nígbà náà? Nígbà tí ó wà ní ipò ìdádọ̀dọ́ ni tàbí ní ipò àìdádọ̀dọ́?+ Kì í ṣe ní ipò ìdádọ̀dọ́, bí kò ṣe ní ipò àìdádọ̀dọ́. 11  Ó sì gba àmì kan,+ èyíinì ni, ìdádọ̀dọ́, gẹ́gẹ́ bí èdìdì òdodo nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ tí ó ní nígbà tí ó wà ní ipò àìdádọ̀dọ́ rẹ̀, kí ó bàa lè jẹ́ baba+ gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́+ nígbà tí wọ́n wà ní àìdádọ̀dọ́, kí a bàa lè ka òdodo fún wọn; 12  àti baba fún àwọn ọmọ tí ó dádọ̀dọ́, kì í ṣe kìkì fún àwọn tí wọ́n rọ̀ mọ́ ìdádọ̀dọ́, ṣùgbọ́n pẹ̀lú fún àwọn tí ń rìn létòletò ní ipasẹ̀ ìgbàgbọ́ náà tí baba+ wa Ábúráhámù ní nígbà tí ó wà ní ipò àìdádọ̀dọ́. 13  Nítorí kì í ṣe nípasẹ̀ òfin ni Ábúráhámù tàbí irú-ọmọ rẹ̀ gba ìlérí+ pé òun yóò jẹ́ ajogún ayé kan, ṣùgbọ́n ó jẹ́ láti inú òdodo nípasẹ̀ ìgbàgbọ́.+ 14  Nítorí bí àwọn tí wọ́n rọ̀ mọ́ òfin bá jẹ́ ajogún, ìgbàgbọ́ ni a ti sọ di aláìwúlò, a sì ti fi òpin sí ìlérí náà.+ 15  Ní ti gidi, Òfin ń mú ìrunú wá,+ ṣùgbọ́n níbi tí òfin kò bá sí, ìrélànàkọjá kankan kò sí pẹ̀lú.+ 16  Ní tìtorí èyí, ó jẹ́ nítorí ìgbàgbọ́, kí ó bàa lè jẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí,+ kí ìlérí+ náà lè dájú fún gbogbo irú-ọmọ rẹ̀,+ kì í ṣe kìkì fún èyí tí ó rọ̀ mọ́ Òfin, ṣùgbọ́n pẹ̀lú fún èyí tí ó rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ Ábúráhámù. (Òun ni baba+ gbogbo wa, 17  gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “Mo ti yàn ọ́ ṣe baba ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.”)+ Èyí jẹ́ lójú Ẹni náà nínú ẹni tí òun ní ìgbàgbọ́, àní Ọlọ́run, tí ń sọ òkú di ààyè,+ tí ó sì ń pe àwọn ohun tí kò sí bí ẹni pé wọ́n wà.+ 18  Bí ó tilẹ̀ ré kọjá ìrètí, síbẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ ìrètí, ó ní ìgbàgbọ́,+ kí ó lè di baba ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè+ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a ti sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni irú-ọmọ rẹ yóò rí.”+ 19  Àti pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò di aláìlera nínú ìgbàgbọ́, ó ronú nípa ara tirẹ̀, tí a ti sọ di òkú nísinsìnyí,+ bí ó ti jẹ́ ẹni nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún,+ àti kíkú ilé ọlẹ̀ Sárà+ pẹ̀lú. 20  Ṣùgbọ́n nítorí ìlérí+ Ọlọ́run, kò mikàn nínú àìnígbàgbọ́,+ ṣùgbọ́n ó di alágbára nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ rẹ̀,+ ó ń fi ògo fún Ọlọ́run, 21  ó sì gbà gbọ́ ní kíkún pé ohun tí ó ti ṣèlérí ni ó lè ṣe pẹ̀lú.+ 22  Nítorí náà, “a kà á sí òdodo fún un.”+ 23  Bí ó ti wù kí ó rí, pé “a kà á+ fún un” ni a kọ, kì í ṣe nítorí rẹ̀ nìkan,+ 24  ṣùgbọ́n ní tìtorí àwa pẹ̀lú tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti kà á fún, nítorí àwa gba ẹni náà gbọ́ tí ó gbé Jésù Olúwa wa dìde kúrò nínú òkú.+ 25  A jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ nítorí àwọn àṣemáṣe wa,+ a sì gbé e dìde nítorí kí a lè polongo wa ní olódodo.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé