Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Róòmù 3:1-31

3  Nígbà náà, ìlọ́lájù wo ni àwọn Júù ní,+ tàbí kí ni àǹfààní ìdádọ̀dọ́?+  Ó pọ̀ gan-an ní gbogbo ọ̀nà. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, nítorí a fi àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run sí ìkáwọ́ wọn.+  Nígbà náà, kí ni ọ̀ràn náà? Bí àwọn kan kò bá fi ìgbàgbọ́ hàn,+ ó ha lè jẹ́ pé àìnígbàgbọ́ wọn yóò sọ ìṣòtítọ́+ Ọlọ́run di aláìgbéṣẹ́ bí?+  Kí èyíinì má ṣẹlẹ̀ láé! Ṣùgbọ́n jẹ́ kí a rí Ọlọ́run ní olóòótọ́,+ bí a tilẹ̀ rí olúkúlùkù ènìyàn ní òpùrọ́,+ àní gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “Kí a lè fi ọ́ hàn ní olódodo nínú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ àti kí ìwọ lè jàre nígbà tí a bá ń ṣèdájọ́ rẹ.”+  Bí ó ti wù kí ó rí, bí àìṣòdodo wa bá mú òdodo+ Ọlọ́run wá sí ipò iwájú, kí ni àwa yóò wí? Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣèdájọ́ òdodo+ nígbà tí ó bá tú ìrunú rẹ̀ jáde, àbí? (Èmi ń sọ̀rọ̀ bí ènìyàn+ ṣe ń sọ̀rọ̀.)  Kí èyíinì má ṣẹlẹ̀ láé! Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe ṣèdájọ́ ayé?+  Síbẹ̀, bí ó bá jẹ́ pé nítorí irọ́ mi, òtítọ́ Ọlọ́run+ ni a ti mú kí ó túbọ̀ yọrí ọlá sí ògo rẹ̀, èé ṣe tí a tún fi ń ṣèdájọ́ mi síbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ṣẹ̀?+  Àti pé, èé ṣe tí a kò wí, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti fi wá sùn+ lọ́nà èké àti gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan ti sọ pé àwa wí pé: “Ẹ jẹ́ kí a ṣe àwọn ohun búburú kí àwọn ohun rere lè wá”?+ Ìdájọ́+ lòdì sí àwọn ènìyàn wọnnì wà ní ìbámu pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo.+  Kí ni nígbà náà? Àwa ha wà ní ipò tí ó sàn jù bí?+ Kì í ṣe bẹ́ẹ̀ rárá! Nítorí lókè, a ti fẹ̀sùn sùn pé àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì ni gbogbo wọ́n wà lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀;+ 10  gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “Kò sí olódodo kan, kò tilẹ̀ sí ẹyọ kan;+ 11  kò sí ẹni tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye kankan, kò sí ẹni tí ń wá Ọlọ́run.+ 12  Gbogbo ènìyàn ti yapa lọ, gbogbo wọn lápapọ̀ ti di aláìníláárí; kò sí ẹni tí ń ṣe inú rere, kò tilẹ̀ sí ẹyọ kan péré.”+ 13  “Sàréè tí ó ṣí sílẹ̀ ni ọ̀fun wọn, wọ́n ti fi ahọ́n wọn ṣe ẹ̀tàn.”+ “Oró ejò gùǹte wà lẹ́yìn ètè wọn.”+ 14  “Ẹnu wọ́n sì kún fún ègún àti gbólóhùn ọ̀rọ̀ kíkorò.”+ 15  “Ẹsẹ̀ wọ́n yára kánkán láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.”+ 16  “Ìparun àti ìṣẹ́ ń bẹ ní àwọn ọ̀nà wọn,+ 17  wọn kò sì tíì mọ ọ̀nà àlàáfíà.”+ 18  “Kò sí ìbẹ̀rù Ọlọ́run níwájú wọn.”+ 19  Wàyí o, àwa mọ̀ pé gbogbo nǹkan tí Òfin+ ń sọ ni ó ń darí sí àwọn tí ó wà lábẹ́ Òfin, kí a lè pa gbogbo ẹnu mọ́,+ kí gbogbo ayé sì lè yẹ+ fún ìyà+ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. 20  Nítorí náà, nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ òfin, kò sí ẹran ara tí a ó polongo ní olódodo+ níwájú rẹ̀, nítorí nípasẹ̀ òfin+ ni ìmọ̀ pípéye nípa ẹ̀ṣẹ̀+ fi wà. 21  Ṣùgbọ́n nísinsìnyí láìsí òfin, òdodo+ Ọlọ́run ni a ti fi hàn kedere, gẹ́gẹ́ bí a ti jẹ́rìí+ sí i nípasẹ̀ Òfin+ àti àwọn Wòlíì;+ 22  bẹ́ẹ̀ ni, òdodo Ọlọ́run nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi,+ fún gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́.+ Nítorí kò sí ìyàtọ̀.+ 23  Nítorí gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀,+ wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run,+ 24  a sì ń polongo wọn ní olódodo gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́+ nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ rẹ̀ nípasẹ̀ ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà+ tí Kristi Jésù san. 25  Ọlọ́run gbé e kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fún ìpẹ̀tù+ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.+ Èyí jẹ́ láti fi òdodo tirẹ̀ hàn, nítorí òun ń dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀+ tí ó wáyé ní ìgbà tí ó ti kọjá jì nígbà tí Ọlọ́run ń lo ìmúmọ́ra;+ 26  kí òun lè fi òdodo+ tirẹ̀ hàn ní àsìkò ìsinsìnyí, kí òun bàa lè jẹ́ olódodo àní nígbà tí ó bá ń polongo ènìyàn tí ó ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù ní olódodo.+ 27  Ìṣògo+ náà wá dà? A ti sé e mọ́ ìta. Nípasẹ̀ òfin wo?+ Ti àwọn iṣẹ́ ni bí?+ Rárá o, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ òfin ìgbàgbọ́.+ 28  Nítorí a ṣírò rẹ̀ pé a ń polongo ènìyàn ní olódodo nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ láìka àwọn iṣẹ́ òfin sí.+ 29  Àbí Ọlọ́run àwọn Júù nìkan ni òun í ṣe?+ Òun kì í ha ṣe Ọlọ́run àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú bí?+ Bẹ́ẹ̀ ni, ti àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú,+ 30  bí ó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run jẹ́ ọ̀kan,+ ẹni tí yóò polongo àwọn ènìyàn tí ó dádọ̀dọ́+ ní olódodo nítorí ìgbàgbọ́ àti àwọn aláìdádọ̀dọ́+ ní olódodo nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ wọn. 31  Ǹjẹ́ àwa, nígbà náà, ha fi òpin sí òfin nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ wa?+ Kí èyíinì má ṣẹlẹ̀ láé! Kàkà bẹ́ẹ̀, àwa fìdí òfin múlẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé