Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Róòmù 2:1-29

2  Nítorí náà ìwọ kò ní àwíjàre, ìwọ ènìyàn,+ ẹnì yòówù kí o jẹ́, bí ìwọ bá ń ṣèdájọ́;+ nítorí nínú ohun tí ìwọ ń ṣèdájọ́ ẹlòmíràn, ìwọ ń dá ara rẹ lẹ́bi, níwọ̀n bí ìwọ tí ń ṣèdájọ́+ ti ń fi ohun kan náà ṣe ìwà hù.+  Wàyí o, àwa mọ̀ pé ìdájọ́ Ọlọ́run, ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́,+ lòdì sí àwọn tí ń fi irúfẹ́ àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣe ìwà hù.  Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ìwọ ní èrò-ọkàn yìí, ìwọ ènìyàn,+ nígbà tí o ń ṣèdájọ́ àwọn tí ń fi irúfẹ́ àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣe ìwà hù, síbẹ̀ tí ìwọ náà ń ṣe wọ́n, pé ìwọ yóò yè bọ́ nínú ìdájọ́ Ọlọ́run?+  Tàbí ìwọ tẹ́ńbẹ́lú ọrọ̀ inú rere+ àti ìmúmọ́ra+ àti ìpamọ́ra+ rẹ̀, nítorí ìwọ kò mọ̀ pé ànímọ́ onínúrere Ọlọ́run ń gbìyànjú láti ṣamọ̀nà rẹ sí ìrònúpìwàdà?+  Ṣùgbọ́n ní ìbámu pẹ̀lú líle+ rẹ àti àìronúpìwàdà ọkàn-àyà,+ ìwọ ń to ìrunú+ jọ fún ara rẹ ní ọjọ́ ìrunú+ àti ìṣípayá+ ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run.+  Òun yóò sì san án fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ rẹ̀:+  ìyè àìnípẹ̀kun fún àwọn tí ń wá ògo àti ọlá àti àìlèdíbàjẹ́+ nípasẹ̀ ìfaradà nínú iṣẹ́ rere;  bí ó ti wù kí ó rí, fún àwọn tí wọ́n jẹ́ alásọ̀,+ tí wọ́n sì ń ṣàìgbọràn sí òtítọ́,+ ṣùgbọ́n tí wọ́n ń ṣègbọràn sí àìṣòdodo ni ìrunú àti ìbínú+ yóò wà,  ìpọ́njú àti wàhálà, lórí ọkàn olúkúlùkù ènìyàn tí ń ṣe ohun aṣeniléṣe, ti Júù+ lákọ̀ọ́kọ́ àti ti Gíríìkì+ pẹ̀lú; 10  ṣùgbọ́n ògo àti ọlá àti àlàáfíà fún gbogbo ẹni tí ń ṣe ohun rere,+ fún Júù lákọ̀ọ́kọ́+ àti fún Gíríìkì+ pẹ̀lú. 11  Nítorí kò sí ojúsàájú lọ́dọ̀ Ọlọ́run.+ 12  Fún àpẹẹrẹ, gbogbo àwọn tí ó ṣẹ̀ láìsí òfin ni yóò ṣègbé pẹ̀lú láìsí òfin;+ ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ó ṣẹ̀ lábẹ́ òfin+ ni a óò dá lẹ́jọ́ nípasẹ̀ òfin.+ 13  Nítorí kì í ṣe àwọn olùgbọ́ òfin ni olódodo níwájú Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àwọn olùṣe+ ohun tí òfin wí ni a ó polongo ní olódodo.+ 14  Nítorí nígbàkigbà tí àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè+ tí kò ní òfin+ bá ṣe àwọn ohun tí ó jẹ́ ti òfin+ lọ́nà ti ẹ̀dá, àwọn ènìyàn wọ̀nyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò ní òfin, jẹ́ òfin fún ara wọn. 15  Àwọn gan-an ni àwọn tí wọ́n fi ọ̀ràn òfin hàn gbangba pé a kọ ọ́ sínú ọkàn-àyà wọn,+ nígbà tí ẹ̀rí-ọkàn+ wọn ń jẹ́ wọn lẹ́rìí àti, láàárín ìrònú tiwọn fúnra wọn, a ń fẹ̀sùn kàn wọ́n+ tàbí a ń gbè wọ́n lẹ́yìn pàápàá. 16  Èyí yóò jẹ́ ní ọjọ́ tí Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi Jésù yóò ṣèdájọ́+ àwọn ohun ìkọ̀kọ̀+ aráyé,+ ní ìbámu pẹ̀lú ìhìn rere tí mo ń polongo.+ 17  Wàyí o, bí ìwọ bá jẹ́ Júù ní orúkọ,+ tí o sì ń sinmi lé òfin,+ tí o sì ń yangàn nínú Ọlọ́run,+ 18  tí o sì mọ ìfẹ́ rẹ̀,+ tí o sì tẹ́wọ́ gba àwọn ohun títayọ lọ́lá nítorí ọ̀rọ̀ ẹnu ni a fi fún ọ ní ìtọ́ni láti inú Òfin;+ 19  o sì gbà pé ìwọ ni afinimọ̀nà fún àwọn afọ́jú,+ ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó wà nínú òkùnkùn,+ 20  olùtọ́ àwọn aláìlọ́gbọ́n-nínú+ sọ́nà, olùkọ́ àwọn ọmọ kéékèèké,+ tí o sì ní kókó+ ìmọ̀ àti ti òtítọ́+ inú Òfin— 21  bí ó ti wù kí ó rí, ǹjẹ́ ìwọ, ẹni tí ń kọ́ ẹlòmíràn, kò kọ́ ara rẹ?+ Ìwọ, ẹni tí ń wàásù pé “Má jalè,”+ ìwọ ha ń jalè bí?+ 22  Ìwọ, ẹni tí ń sọ pé “Má ṣe panṣágà,”+ ìwọ ha ń ṣe panṣágà bí? Ìwọ, ẹni tí ń fi ìkórìíra tẹ̀gàntẹ̀gàn hàn sí àwọn òrìṣà, ìwọ ha ń ja àwọn tẹ́ńpìlì lólè+ bí? 23  Ìwọ, ẹni tí ń yangàn nínú òfin, ǹjẹ́ ìwọ nípasẹ̀ ríré tí o ń ré Òfin+ kọjá ha ń tàbùkù sí Ọlọ́run bí? 24  Nítorí “orúkọ Ọlọ́run ni a ń sọ̀rọ̀ òdì sí ní tìtorí yín láàárín àwọn orílẹ̀-èdè”;+ gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀. 25  Ní ti tòótọ́, ìdádọ̀dọ́+ ṣàǹfààní kìkì bí ìwọ bá fi òfin ṣe ìwà hù;+ ṣùgbọ́n bí ìwọ bá jẹ́ olùré òfin kọjá, ìdádọ̀dọ́+ rẹ ti di àìdádọ̀dọ́.+ 26  Nítorí náà, bí aláìdádọ̀dọ́+ bá pa ohun òdodo tí Òfin béèrè mọ́,+ àìdádọ̀dọ́ rẹ̀ ni a ó kà sí ìdádọ̀dọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?+ 27  Àti pé aláìdádọ̀dọ́ tí ó jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ́nà ti ẹ̀dá, nípa pípa Òfin mọ́, yóò ṣèdájọ́ ìwọ+ tí o ní àkójọ rẹ̀ tí a kọ sílẹ̀ àti ìdádọ̀dọ́ tí o jẹ́ olùré òfin kọjá. 28  Nítorí òun kì í ṣe Júù ẹni tí ó jẹ́ bẹ́ẹ̀ ní òde ara,+ bẹ́ẹ̀ ni ìdádọ̀dọ́ kì í ṣe èyí tí ó wà ní òde ara.+ 29  Ṣùgbọ́n òun jẹ́ Júù ẹni tí ó jẹ́ bẹ́ẹ̀ ní inú,+ ìdádọ̀dọ́ rẹ̀ sì jẹ́ ti ọkàn-àyà+ nípasẹ̀ ẹ̀mí, kì í sì í ṣe nípasẹ̀ àkójọ òfin tí a kọ sílẹ̀.+ Ìyìn+ ẹni yẹn kò wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn, bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé