Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Róòmù 16:1-27

16  Mo dámọ̀ràn Fébè arábìnrin wa fún ìtẹ́wọ́gbà yín, ẹni tí ó jẹ́ òjíṣẹ́+ ìjọ tí ó wà ní Kẹnkíríà,+  kí ẹ lè fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà+ á nínú Olúwa lọ́nà tí ó yẹ àwọn ẹni mímọ́, kí ẹ sì lè ṣèrànwọ́ fún un nínú ọ̀ràn èyíkéyìí tí ó ti lè nílò yín,+ nítorí òun fúnra rẹ̀ jẹ́ olùgbèjà fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni, fún èmi tìkára mi.  Ẹ bá mi kí Pírísíkà àti Ákúílà+ àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀+ mi nínú Kristi Jésù,  tí wọ́n fi ọrùn+ ara wọn wewu nítorí ọkàn mi, àwọn ẹni tí kì í ṣe èmi nìkan ṣùgbọ́n tí gbogbo ìjọ àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú ń fi ọpẹ́ fún;+  ẹ sì kí ìjọ tí ó wà ní ilé wọn.+ Ẹ kí olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n Épénétù, ẹni tí ó jẹ́ àkọ́so+ Éṣíà fún Kristi.  Ẹ kí Màríà, ẹni tí ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ òpò fún yín.  Ẹ kí Androníkọ́sì àti Júníásì àwọn ìbátan mi+ àti òǹdè ẹlẹgbẹ́ mi,+ tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin olókìkí láàárín àwọn àpọ́sítélì, tí wọ́n sì ti pẹ́ jù mí lọ nínú ìrẹ́pọ̀+ pẹ̀lú Kristi.  Ẹ bá mi kí+ Áńpílíátù olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n nínú Olúwa.  Ẹ kí Úbánọ́sì alábàáṣiṣẹ́pọ̀ wa nínú Kristi, àti olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n Sítákísì. 10  Ẹ kí+ Ápélésì, ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà nínú Kristi. Ẹ kí àwọn ti agbo ilé Àrísítóbúlù. 11  Ẹ kí Hẹ́ródíónì ìbátan mi.+ Ẹ kí àwọn wọnnì láti agbo ilé Nákísọ́sì tí wọ́n wà nínú Olúwa.+ 12  Ẹ kí Tírífénà àti Tírífósà, àwọn obìnrin tí ń ṣiṣẹ́ kára nínú Olúwa. Ẹ kí obìnrin náà Pésísì olùfẹ́ wa ọ̀wọ́n, nítorí ó ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ òpò nínú Olúwa. 13  Ẹ kí Rúfọ́ọ̀sì ẹni àyànfẹ́ nínú Olúwa, àti ìyá rẹ̀ tí ó jẹ́ tèmi náà. 14  Ẹ kí Asinkirítọ́sì, Fílégónì, Hẹ́mísì, Pátíróbásì, Hẹ́másì, àti àwọn ará tí wọ́n wà pẹ̀lú wọn. 15  Ẹ kí Fílólógọ́sì àti Júlíà, Néréúsì àti arábìnrin rẹ̀, àti Òlíńpásì, àti gbogbo ẹni mímọ́ tí ń bẹ pẹ̀lú wọn.+ 16  Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.+ Gbogbo àwọn ìjọ Kristi kí yín. 17  Wàyí o, mo gbà yín níyànjú, ẹ̀yin ará, láti máa ṣọ́ àwọn tí ń fa ìpínyà+ àti àwọn àyè fún ìkọ̀sẹ̀ lòdì sí ẹ̀kọ́+ tí ẹ ti kọ́, ẹ sì yẹra fún wọn.+ 18  Nítorí irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ẹrú Olúwa wa Kristi, bí kò ṣe ti ikùn tiwọn;+ àti pé ọ̀rọ̀ dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in+ àti ọ̀rọ̀ ìyinni+ ni wọ́n fi ń sún ọkàn-àyà àwọn aláìlẹ́tàn dẹ́ṣẹ̀. 19  Nítorí ìgbọràn yín ti wá sí àfiyèsí gbogbo ènìyàn.+ Nítorí náà, mo yọ̀ nítorí yín. Ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n+ ní ti ohun rere, ṣùgbọ́n ọlọ́wọ́-mímọ́+ ní ti ohun tí ó jẹ́ ibi.+ 20  Ní tirẹ̀, Ọlọ́run tí ń fúnni ní àlàáfíà+ yóò tẹ Sátánì+ rẹ́ lábẹ́ ẹsẹ̀ yín láìpẹ́. Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Olúwa wa Jésù wà pẹ̀lú yín.+ 21  Tímótì alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi kí yín, Lúkíọ́sì àti Jásónì àti Sósípátérì àwọn ìbátan mi+ sì ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. 22  Èmi, Tẹ́tíọ́sì, tí mo kọ lẹ́tà yìí, kí yín nínú Olúwa. 23  Gáyọ́sì,+ ẹni tí ó gba èmi àti gbogbo ìjọ lálejò, kí yín. Érásítù ìríjú ìlú ńlá+ kí yín, Kúátọ́sì arákùnrin rẹ̀ sì ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. 24  —— 25  Nísinsìnyí fún ẹni náà+ tí ó lè fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in ní ìbámu pẹ̀lú ìhìn rere tí mo ń polongo àti ìwàásù Jésù Kristi, gẹ́gẹ́ bí ìṣípayá àṣírí ọlọ́wọ̀+ tí a ti pa mọ́ ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ tipẹ́tipẹ́ 26  ṣùgbọ́n tí a ti fi hàn kedere nísinsìnyí,+ tí a sì ti sọ di mímọ̀ láàárín gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè nípasẹ̀ àwọn ìwé mímọ́ alásọtẹ́lẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ Ọlọ́run àìnípẹ̀kun láti gbé ìgbọràn ga síwájú sí i nípasẹ̀ ìgbàgbọ́;+ 27  Ọlọ́run, ẹnì kan ṣoṣo tí ó gbọ́n,+ ni kí ògo+ wà fún nípasẹ̀ Jésù Kristi+ títí láé. Àmín.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé