Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Róòmù 14:1-23

14  Ẹ fi inú dídùn tẹ́wọ́ gba ẹni tí ó ní àwọn àìlera+ nínú ìgbàgbọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe láti ṣe àwọn ìpinnu lórí àwọn ìbéèrè tí a ń gbé dìde ní inú.+  Ẹnì kan ní ìgbàgbọ́ láti jẹ ohun gbogbo,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ó jẹ́ aláìlera ń jẹ àwọn ọ̀gbìn oko.  Kí ẹni tí ń jẹ má fojú tẹ́ńbẹ́lú ẹni tí kò jẹ,+ kí ẹni tí kò sì jẹ má ṣèdájọ́ ẹni tí ń jẹ, nítorí Ọlọ́run ti fi inú dídùn tẹ́wọ́ gba ẹni yẹn.  Ta ni ìwọ láti ṣèdájọ́ ìránṣẹ́ ilé ẹlòmíràn?+ Lọ́dọ̀ ọ̀gá òun fúnra rẹ̀ ni ó dúró tàbí ṣubú.+ Ní tòótọ́, a óò mú un dúró, nítorí Jèhófà lè mú un dúró.+  Ẹni kan ka ọjọ́ kan sí èyí tí ó ga ju òmíràn lọ;+ ẹlòmíràn ka ọjọ́ kan sí bí gbogbo àwọn yòókù;+ kí olúkúlùkù gbà gbọ́ ní kíkún nínú èrò inú òun fúnra rẹ̀.  Ẹni tí ń pa ọjọ́ mọ́ ń pa á mọ́ fún Jèhófà. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹni tí ń jẹun, ń jẹun fún Jèhófà,+ nítorí ó ń fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run;+ ẹni tí kò sì jẹun kò jẹun fún Jèhófà,+ síbẹ̀síbẹ̀, ó ń fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run.+  Kò sí ọ̀kan nínú wa, ní ti tòótọ́, tí ó wà láàyè nípa ti ara rẹ̀ nìkan,+ kò sì sí ẹni tí ó kú nípa ti ara rẹ̀ nìkan;  nítorí pé bí a bá wà láàyè, a wà láàyè fún Jèhófà,+ bí a bá sì kú, a kú fún Jèhófà.+ Nítorí náà, bí a bá wà láàyè àti bí a bá kú, a jẹ́ ti Jèhófà.+  Nítorí fún ète yìí ni Kristi kú, tí ó sì tún wá sí ìyè,+ kí ó lè jẹ́ Olúwa lórí àwọn òkú+ àti àwọn alààyè.+ 10  Ṣùgbọ́n èé ṣe tí o ń dá arákùnrin rẹ lẹ́jọ́? Tàbí èé ṣe tí o tún ń fojú tẹ́ńbẹ́lú arákùnrin rẹ?+ Nítorí gbogbo wa ni yóò dúró níwájú ìjókòó ìdájọ́+ Ọlọ́run; 11  nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “‘Bí èmi ti wà láàyè,’ ni Jèhófà wí,+ ‘gbogbo eékún yóò tẹ̀ ba fún mi, gbogbo ahọ́n yóò sì ṣe ìjẹ́wọ́ ní gbangba fún Ọlọ́run.’”+ 12  Nítorí bẹ́ẹ̀, olúkúlùkù wa ni yóò ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.+ 13  Nítorí náà, kí a má ṣe máa dá ara wa lẹ́jọ́+ mọ́ lẹ́nì kìíní-kejì, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ fi èyí ṣe ìpinnu yín,+ láti má ṣe fi ohun ìkọ̀sẹ̀+ tàbí okùnfà fún ìgbéniṣubú sí iwájú arákùnrin.+ 14  Mo mọ̀, mo sì gbà nínú Jésù Olúwa pé kò sí nǹkan kan tí ó jẹ́ ẹlẹ́gbin nínú ara rẹ̀;+ kìkì níbi tí ẹnì kan bá ti ka ohun kan sí ẹlẹ́gbin, òun ni ó di ẹlẹ́gbin fún.+ 15  Nítorí bí a bá ń kó ẹ̀dùn-ọkàn bá arákùnrin rẹ nítorí oúnjẹ, ìwọ kò rìn ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ mọ́.+ Má ṣe tipasẹ̀ oúnjẹ rẹ ṣe ẹni yẹn tí Kristi kú fún lọ́ṣẹ́.+ 16  Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí a sọ̀rọ̀ ohun rere tí ẹ ń ṣe láti mú ìbàjẹ́ ba yín. 17  Nítorí ìjọba Ọlọ́run+ kò túmọ̀ sí jíjẹ àti mímu,+ ṣùgbọ́n ó túmọ̀ sí òdodo+ àti àlàáfíà+ àti ìdùnnú+ pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́. 18  Nítorí ẹni tí ń sìnrú fún Kristi lọ́nà yìí ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run, ó sì ní ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ ènìyàn.+ 19  Nítorí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí a máa lépa àwọn ohun tí ń yọrí sí àlàáfíà+ àti àwọn ohun tí ń gbéni ró fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.+ 20  Dẹ́kun yíya iṣẹ́ Ọlọ́run lulẹ̀ kìkì nítorí oúnjẹ.+ Lóòótọ́, ohun gbogbo ni ó mọ́, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ohun aṣeniléṣe fún ẹni tí ń jẹun nínú àyè fún ìkọ̀sẹ̀.+ 21  Ó dára láti má ṣe jẹ ẹran tàbí mú wáìnì tàbí ṣe ohunkóhun tí yóò mú arákùnrin rẹ kọsẹ̀.+ 22  Ìgbàgbọ́ tí ìwọ ní, ní in ní ìbámu pẹ̀lú ara rẹ níwájú Ọlọ́run.+ Aláyọ̀ ni ẹni tí kò fi ara rẹ̀ sínú ìdájọ́ nípasẹ̀ ohun tí ó tẹ́wọ́ gbà. 23  Ṣùgbọ́n bí ó bá ń ní iyèméjì, a ti dá a lẹ́bi ná bí ó bá jẹ,+ nítorí kò jẹ láti inú ìgbàgbọ́. Ní tòótọ́, ohun gbogbo tí kò bá ti inú ìgbàgbọ́ wá, ẹ̀ṣẹ̀ ni.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé