Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Róòmù 13:1-14

13  Kí olúkúlùkù ọkàn wà lábẹ́+ àwọn aláṣẹ onípò gíga,+ nítorí kò sí ọlá àṣẹ+ kankan bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run;+ àwọn ọlá àṣẹ tí ó wà ni a gbé dúró sí àwọn ipò wọn aláàlà+ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+  Nítorí náà, ẹni tí ó bá tako ọlá àṣẹ ti mú ìdúró kan lòdì sí ìṣètò Ọlọ́run; àwọn tí wọ́n ti mú ìdúró kan lòdì sí i yóò gba ìdájọ́ fún ara wọn.+  Nítorí àwọn tí ń ṣàkóso jẹ́ ohun ẹ̀rù, kì í ṣe sí iṣẹ́ rere, bí kò ṣe sí búburú.+ Ṣé ìwọ, nígbà náà, kò fẹ́ láti ní ìbẹ̀rù kankan fún aláṣẹ? Máa ṣe rere,+ ìwọ yóò sì gba ìyìn láti ọ̀dọ̀ rẹ̀;  nítorí òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni ó jẹ́ sí ọ fún ire rẹ.+ Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń ṣe ohun tí ó burú,+ kí o máa bẹ̀rù: nítorí kì í ṣe láìsí ète ni ó gbé idà; nítorí òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni, olùgbẹ̀san+ láti fi ìrunú hàn sí ẹni tí ń fi ohun tí ó burú ṣe ìwà hù.  Nítorí náà, ìdí tí ń múni lọ́ranyàn wà fún yín láti wà lábẹ́ àṣẹ, kì í ṣe ní tìtorí ìrunú yẹn nìkan, ṣùgbọ́n ní tìtorí ẹ̀rí-ọkàn yín pẹ̀lú.+  Nítorí ìdí nìyẹn tí ẹ fi ń san owó orí pẹ̀lú; nítorí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run sí gbogbo ènìyàn+ ní sísìn nígbà gbogbo fún ète yìí gan-an.  Ẹ fi ẹ̀tọ́ gbogbo ènìyàn fún wọn, ẹni tí ó béèrè fún owó orí, ẹ fún un ní owó orí;+ ẹni tí ó béèrè fún owó òde, ẹ fún un ní owó òde; ẹni tí ó béèrè fún ìbẹ̀rù, ẹ fún un ní irúfẹ́ ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀;+ ẹni tí ó béèrè fún ọlá, ẹ fún un ní irúfẹ́ ọlá bẹ́ẹ̀.+  Kí ẹ má ṣe máa jẹ ẹnikẹ́ni ní gbèsè ẹyọ ohun kan,+ àyàfi láti nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì;+ nítorí ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀ ti mú òfin ṣẹ.+  Nítorí àkójọ òfin náà, “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà,+ Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣìkà pànìyàn,+ Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jalè,+ Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣojúkòkòrò,”+ àti àṣẹ mìíràn yòówù kí ó wà, ni a ṣàkópọ̀ rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ yìí, èyíinì ni, “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.”+ 10  Ìfẹ́+ kì í ṣiṣẹ́ ibi sí aládùúgbò ẹni;+ nítorí náà, ìfẹ́ ni ìmúṣẹ òfin.+ 11  Ẹ ṣe èyí, pẹ̀lú, nítorí pé ẹ mọ àsìkò, pé wákàtí ti tó nísinsìnyí fún yín láti jí+ lójú oorun, nítorí ìgbàlà wa sún mọ́lé nísinsìnyí ju ìgbà tí a di onígbàgbọ́.+ 12  Òru ti lọ jìnnà; ojúmọ́+ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ mọ́. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a bọ́ àwọn iṣẹ́ tí ó jẹ́ ti òkùnkùn+ kúrò, kí a sì gbé àwọn ohun ìjà+ ìmọ́lẹ̀ wọ̀. 13  Gẹ́gẹ́ bí ní ìgbà ọ̀sán, ẹ jẹ́ kí a máa rìn lọ́nà bíbójúmu,+ kì í ṣe nínú àwọn àríyá aláriwo àti mímu àmuyíràá,+ kì í ṣe nínú ìbádàpọ̀ tí ó tàpá sófin àti ìwà àìníjàánu,+ kì í ṣe nínú gbọ́nmi-si omi-ò-to+ àti owú. 14  Ṣùgbọ́n ẹ gbé Olúwa Jésù Kristi wọ̀,+ ẹ má sì máa wéwèé tẹ́lẹ̀ fún àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ẹran ara.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé