Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Róòmù 11:1-36

11  Mo béèrè, nígbà náà, Ọlọ́run kò kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ tì, àbí ó ṣe bẹ́ẹ̀?+ Kí èyíinì má ṣẹlẹ̀ láé! Nítorí èmi pẹ̀lú jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì,+ ti irú-ọmọ Ábúráhámù, ti ẹ̀yà Béńjámínì.+  Ọlọ́run kò kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ tì, àwọn ẹni tí òun kọ́kọ́ fún ní àkànṣe àfiyèsí.+ Họ́wù, ṣé ẹ kò mọ ohun tí Ìwé Mímọ́ wí ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Èlíjà ni, bí ó ti ń rọ Ọlọ́run lòdì sí Ísírẹ́lì?+  “Jèhófà, wọ́n ti pa àwọn wòlíì rẹ, wọ́n ti hú àwọn pẹpẹ rẹ kúrò, èmi nìkan ṣoṣo sì ni ó ṣẹ́ kù, wọ́n sì ń wá ọkàn mi.”+  Síbẹ̀, kí ni ọ̀rọ̀ ìkéde àtọ̀runwá+ náà wí fún un? “Èmi ti ṣẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin ọkùnrin kù fún ara mi, àwọn ọkùnrin tí wọn kò tẹ eékún wọn ba fún Báálì.”+  Nítorí náà, lọ́nà yìí, ní àsìkò ìsinsìnyí pẹ̀lú, àṣẹ́kù kékeré+ ti fara hàn ní ìbámu pẹ̀lú yíyàn+ nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí.  Wàyí o, bí ó bá jẹ́ nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí,+ kì í tún ṣe nítorí àwọn iṣẹ́ mọ́;+ bí bẹ́ẹ̀ kọ́, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí náà kò tún ní jẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí mọ́.+  Kí wá ni? Ohun náà gan-an tí Ísírẹ́lì ń fi taratara wá ni kò rí gbà,+ ṣùgbọ́n àwọn tí a yàn+ rí i gbà. Agbára ìmòye àwọn yòókù ni a mú kú tipiri;+  gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “Ọlọ́run ti fún wọn ni ẹ̀mí oorun àsùnwọra,+ ojú kí wọ́n má lè ríran àti etí kí wọ́n má lè gbọ́, títí di òní yìí gan-an.”+  Pẹ̀lúpẹ̀lù, Dáfídì wí pé: “Jẹ́ kí tábìlì wọ́n di ìdẹkùn àti pańpẹ́ àti ohun ìkọ̀sẹ̀ àti ẹ̀san iṣẹ́ fún wọn;+ 10  jẹ́ kí ojú wọn di èyí tí ó ṣókùnkùn kí wọ́n má lè ríran, sì mú ẹ̀yìn wọn tẹ̀ba nígbà gbogbo.”+ 11  Nítorí náà, mo béèrè, Wọ́n ha kọsẹ̀ tí wọ́n fi ṣubú+ pátápátá ni bí? Kí èyíinì má ṣẹlẹ̀ láé! Ṣùgbọ́n nípa ìṣisẹ̀gbé wọn,+ ìgbàlà wà fún àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè,+ láti ru wọ́n lọ́kàn sókè sí owú.+ 12  Wàyí o, bí ìṣisẹ̀gbé wọn bá túmọ̀ sí ọrọ̀ fún ayé, tí pípẹ̀dín wọ́n sì túmọ̀ sí ọrọ̀ fún àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè,+ mélòómélòó ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye+ wọn yóò túmọ̀ sí i! 13  Wàyí o, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè ni mo ń bá sọ̀rọ̀. Níwọ̀n bí èmi, ní ti gidi, ti jẹ́ àpọ́sítélì+ fún àwọn orílẹ̀-èdè,+ mo ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́+ mi lógo,+ 14  bí èmi, lọ́nà èyíkéyìí, bá lè ru àwọn tí wọ́n jẹ́ ẹran ara tèmi lọ́kàn sókè sí owú, kí n sì gba+ díẹ̀ láàárín wọn+ là. 15  Nítorí bí títa wọ́n nù+ bá túmọ̀ sí ìpadàrẹ́+ fún ayé, kí ni gbígbà wọ́n yóò túmọ̀ sí bí kò ṣe ìyè kúrò nínú òkú? 16  Síwájú sí i, bí apá tí a mú gẹ́gẹ́ bí àkọ́so+ bá jẹ́ mímọ́, ìṣùpọ̀ náà jẹ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú; bí gbòǹgbò bá sì jẹ́ mímọ́,+ àwọn ẹ̀ka náà jẹ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. 17  Bí ó ti wù kí ó rí, bí a bá ṣẹ́ àwọn ẹ̀ka kan kúrò ṣùgbọ́n tí a lọ́ ìwọ sí àárín wọn,+ bí o tilẹ̀ jẹ́ ólífì ìgbẹ́, tí o sì wá di alájọpín nínú gbòǹgbò ọ̀rá+ ólífì+ náà, 18  má ṣe máa yọ ayọ̀ ńláǹlà lórí àwọn ẹ̀ka náà. Ṣùgbọ́n, bí ìwọ bá ń yọ ayọ̀ ńláǹlà lórí wọn,+ kì í ṣe ìwọ ni o gbé gbòǹgbò dúró,+ ṣùgbọ́n gbòǹgbò ni ó gbé ọ dúró.+ 19  Nígbà náà, ìwọ yóò wí pé: “Àwọn ẹ̀ka ni a ṣẹ́ kúrò,+ kí a lè lọ́ mi wọlé.”+ 20  Ó dára! Nítorí àìnígbàgbọ́ wọn,+ a ṣẹ́ wọn kúrò, ṣùgbọ́n ìwọ dúró nípasẹ̀ ìgbàgbọ́.+ Jáwọ́ nínú níní àwọn èrò-ọkàn gíga fíofío,+ ṣùgbọ́n bẹ̀rù.+ 21  Nítorí bí Ọlọ́run kò bá dá àwọn ẹ̀ka àdánidá sí, kì yóò dá ìwọ náà sí.+ 22  Nítorí náà, wo inú rere+ àti ìmúnájanjan+ Ọlọ́run. Síhà ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n ṣubú ni ìmúnájanjan wà,+ ṣùgbọ́n síhà ọ̀dọ̀ rẹ ni inú rere Ọlọ́run wà, kìkì bí o bá dúró+ nínú inú rere rẹ̀; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìwọ pẹ̀lú ni a óò ké kúrò.+ 23  Àwọn pẹ̀lú ni a óò lọ́ wọlé bí wọn kò bá dúró nínú àìnígbàgbọ́ wọn;+ nítorí Ọlọ́run lè tún lọ́ wọn wọlé. 24  Nítorí bí ó bá jẹ́ pé a ké ọ kúrò lára igi ólífì tí ó jẹ́ ti ìgbẹ́ lọ́nà ti ẹ̀dá, tí a sì lọ́+ ìwọ lọ́nà tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá sínú igi ólífì ọgbà, mélòómélòó ni a óò lọ́ àwọn wọ̀nyí tí wọ́n jẹ́ ti àdánidá sínú igi ólífì tiwọn!+ 25  Nítorí èmi kò fẹ́ kí ẹ̀yin, ará, ṣe aláìmọ àṣírí ọlọ́wọ̀ yìí,+ kí ẹ má bàa jẹ́ olóye lójú ara yín: pé ìpòkúdu agbára ìmòye+ ti ṣẹlẹ̀ lápá kan sí Ísírẹ́lì títí di ìgbà tí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye+ àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè bá ti wọlé,+ 26  àti pé lọ́nà yìí ni a ó gba gbogbo Ísírẹ́lì+ là. Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “Olùdáǹdè yóò jáde wá láti Síónì,+ yóò sì yí àwọn ìṣe àìṣèfẹ́ Ọlọ́run padà kúrò lọ́dọ̀ Jékọ́bù.+ 27  Èyí sì ni májẹ̀mú náà níhà ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú wọn,+ nígbà tí mo bá mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò.”+ 28  Lóòótọ́, ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìhìn rere, ọ̀tá ni wọ́n jẹ́ nítorí yín,+ ṣùgbọ́n ní ìsopọ̀ pẹ̀lú yíyàn [ti Ọlọ́run] olùfẹ́ ọ̀wọ́n ni wọ́n jẹ́ nítorí àwọn baba ńlá wọn.+ 29  Nítorí àwọn ẹ̀bùn àti ìpè Ọlọ́run kì í ṣe àwọn ohun tí òun yóò pèrò dà lé lórí.+ 30  Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti jẹ́ aláìgbọràn+ nígbà kan rí sí Ọlọ́run, ṣùgbọ́n tí a ti fi àánú+ hàn sí yín nísinsìnyí nítorí àìgbọràn wọn,+ 31  bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, àwọn wọ̀nyí ti jẹ́ aláìgbọràn nísinsìnyí, tí ó yọrí sí àánú fún yín,+ kí a bàa lè fi àánú hàn sí àwọn tìkára wọn pẹ̀lú nísinsìnyí. 32  Nítorí Ọlọ́run ti sé gbogbo wọn mọ́ lápapọ̀ nínú àìgbọràn,+ kí ó bàa lè fi àánú hàn sí gbogbo wọn.+ 33  Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀+ àti ọgbọ́n+ àti ìmọ̀+ Ọlọ́run mà pọ̀ o! Àwọn ìdájọ́+ rẹ̀ ti jẹ́ àwámáridìí tó, àwọn ọ̀nà rẹ̀ sì ré kọjá àwákàn! 34  Nítorí “ta ni ó ti wá mọ èrò inú Jèhófà,+ tàbí ta ní ti di agbani-nímọ̀ràn rẹ̀?”+ 35  Tàbí, “Ta ní ti kọ́kọ́ fi fún un, tí a fi gbọ́dọ̀ san án padà fún un?”+ 36  Nítorí pé láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ohun gbogbo ti wá àti nípasẹ̀ rẹ̀ àti fún un.+ Òun ni kí ògo wà fún títí láé.+ Àmín.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé