Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Róòmù 10:1-21

10  Ẹ̀yin ará, ìfẹ́ rere ọkàn-àyà mi àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ mi sí Ọlọ́run fún wọn, ní tòótọ́, jẹ́ fún ìgbàlà wọn.+  Nítorí mo jẹ́rìí wọn pé wọ́n ní ìtara+ fún Ọlọ́run; ṣùgbọ́n kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye;+  nítorí, fún ìdí náà pé wọn kò mọ òdodo Ọlọ́run,+ ṣùgbọ́n tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti gbé tiwọn kalẹ̀,+ wọn kò fi ara wọn sábẹ́ òdodo Ọlọ́run.+  Nítorí Kristi ni òpin Òfin,+ kí olúkúlùkù ẹni tí ń lo ìgbàgbọ́ lè ní òdodo.+  Nítorí Mósè kọ̀wé pé ènìyàn tí ó bá ti ṣe òdodo Òfin yóò yè nípa rẹ̀.+  Ṣùgbọ́n òdodo tí ń jẹyọ láti inú ìgbàgbọ́ ń sọ̀rọ̀ lọ́nà yìí: “Má ṣe sọ nínú ọkàn-àyà rẹ pé,+ ‘Ta ni yóò gòkè re ọ̀run?’+ èyíinì ni, láti mú Kristi+ sọ̀ kalẹ̀ wá;  tàbí, ‘Ta ni yóò sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀?’+ èyíinì ni, láti mú Kristi gòkè wá láti inú òkú.”+  Ṣùgbọ́n kí ni ó wí? “Ọ̀rọ̀ náà wà nítòsí rẹ, ní ẹnu ìwọ alára àti ní ọkàn-àyà ìwọ alára”;+ èyíinì ni, “ọ̀rọ̀”+ ìgbàgbọ́, tí a ń wàásù.+  Nítorí bí ìwọ bá polongo ‘ọ̀rọ̀ yẹn tí ń bẹ ni ẹnu ìwọ alára’+ ní gbangba, pé Jésù ni Olúwa,+ tí o sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú ọkàn-àyà rẹ pé Ọlọ́run gbé e dìde kúrò nínú òkú,+ a ó gbà ọ́ là.+ 10  Nítorí ọkàn-àyà+ ni a fi ń lo ìgbàgbọ́ fún òdodo, ṣùgbọ́n ẹnu ni a fi ń ṣe ìpolongo ní gbangba+ fún ìgbàlà. 11  Nítorí Ìwé Mímọ́ wí pé: “Kò sí ẹni tí ó gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ lé e+ tí a óò já kulẹ̀.”+ 12  Nítorí kò sí ìyàtọ̀ láàárín Júù àti Gíríìkì,+ nítorí Olúwa kan náà ní ń bẹ lórí gbogbo wọn, ẹni tí ó jẹ́ ọlọ́rọ̀+ sí gbogbo àwọn tí ń ké pè é. 13  Nítorí “olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.”+ 14  Àmọ́ ṣá o, báwo ni wọn yóò ṣe ké pe ẹni tí wọn kò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀?+ Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe ní ìgbàgbọ́ nínú ẹni tí wọn kò gbọ́ nípa rẹ̀? Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe gbọ́ láìsí ẹnì kan láti wàásù?+ 15  Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe wàásù láìjẹ́ pé a rán wọn jáde?+ Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “Ẹsẹ̀ àwọn tí ń polongo ìhìn rere àwọn ohun rere mà dára rèǹtè-rente o!”+ 16  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, gbogbo wọn kọ́ ni wọ́n ṣègbọràn sí ìhìn rere.+ Nítorí Aísáyà wí pé: “Jèhófà, ta ni ó ti lo ìgbàgbọ́ nínú ohun tí a gbọ́ láti ọ̀dọ̀ wa?”+ 17  Nítorí náà, ìgbàgbọ́ ń tẹ̀ lé ohun tí a gbọ́.+ Ẹ̀wẹ̀, ohun tí a gbọ́ jẹ́ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ nípa Kristi.+ 18  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ mo béèrè, Wọn kò kùnà láti gbọ́, àbí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀? Họ́wù, ní ti tòótọ́, “ìró wọ́n jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀ ayé,+ àsọjáde wọn sì jáde lọ sí àwọn ìkángun ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.”+ 19  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ mo béèrè, Ísírẹ́lì kò kùnà láti mọ̀, àbí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀?+ Lákọ̀ọ́kọ́, Mósè wí pé: “Ṣe ni èmi yóò ru yín lọ́kàn sókè sí owú nípasẹ̀ èyíinì tí kì í ṣe orílẹ̀-èdè; ṣe ni èmi yóò ru yín lọ́kàn sókè sí ìbínú lílenípá nípasẹ̀ orílẹ̀-èdè arìndìn.”+ 20  Ṣùgbọ́n Aísáyà di aláìṣojo rárá, ó sì wí pé: “Àwọn tí kò wá mi rí mi;+ mo fara hàn kedere sí àwọn tí kò béèrè mi.”+ 21  Ṣùgbọ́n nípa Ísírẹ́lì, ó wí pé: “Lati òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ni mo ti tẹ́ ọwọ́ mi sí àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ aláìgbọràn+ àti agbónilẹ́nu.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé