Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Róòmù 1:1-32

1  Pọ́ọ̀lù, ẹrú+ Jésù Kristi, tí a sì pè+ láti jẹ́ àpọ́sítélì,+ tí a yà sọ́tọ̀ fún ìhìn rere Ọlọ́run,+  èyí tí òun ṣèlérí ní ìgbà ìṣáájú nípasẹ̀ àwọn wòlíì+ rẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́,  nípa Ọmọ rẹ̀, ẹni tí ó jáde wá láti inú irú-ọmọ Dáfídì+ lọ́nà ti ẹran ara,+  ṣùgbọ́n ẹni tí a polongo ní Ọmọ+ Ọlọ́run pẹ̀lú agbára+ ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí+ ìjẹ́mímọ́ nípasẹ̀ àjíǹde láti inú òkú+—bẹ́ẹ̀ ni, Jésù Kristi Olúwa wa,  nípasẹ̀ ẹni tí a rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ àti iṣẹ́ àpọ́sítélì+ gbà, kí ìgbọràn ìgbàgbọ́ lè wà láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè+ nípa orúkọ rẹ̀,  láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ̀yin pẹ̀lú jẹ́ àwọn tí a pè láti jẹ́ ti Jésù Kristi—  sí gbogbo àwọn tí ó wà ní Róòmù gẹ́gẹ́ bí olùfẹ́ ọ̀wọ́n fún Ọlọ́run, tí a pè+ láti jẹ́ ẹni mímọ́:+ Kí ẹ ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà+ láti ọ̀dọ̀ Baba wa Ọlọ́run àti Jésù Kristi Olúwa.+  Lákọ̀ọ́kọ́ ná, mo fi ọpẹ́+ fún Ọlọ́run mi nípasẹ̀ Jésù Kristi nítorí gbogbo yín, nítorí a ń sọ̀rọ̀ nípa+ ìgbàgbọ́ yín jákèjádò ayé.  Nítorí Ọlọ́run, ẹni tí mo ń fi ẹ̀mí mi ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìhìn rere nípa Ọmọ rẹ̀, ni ẹlẹ́rìí+ mi nípa bí mo ṣe ń dárúkọ yín nígbà gbogbo láìṣíwọ́ nínú àwọn àdúrà mi,+ 10  ní bíbẹ̀bẹ̀ pé bí ó bá ṣeé ṣe lọ́nà kan ṣá, kí èmi nísinsìnyí lè ṣàṣeyọrí nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín nínú ìfẹ́+ Ọlọ́run láti lè wá sọ́dọ̀ yín. 11  Nítorí aáyun ń yun mí láti rí yín,+ kí n lè fi ẹ̀bùn ẹ̀mí+ díẹ̀ fún yín, kí a lè fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in; 12  tàbí, kí a kúkú wí pé, kí pàṣípààrọ̀ ìṣírí+ lè wà láàárín yín, láti ọ̀dọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ẹnì kejì,+ tiyín àti tèmi. 13  Ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ kí ẹ kùnà láti mọ̀, ẹ̀yin ará,+ pé mo pète lọ́pọ̀ ìgbà láti wá sọ́dọ̀ yín,+ ṣùgbọ́n a tí dí mi lọ́wọ́ títí di ìsinsìnyí, kí n lè rí èso+ díẹ̀ pẹ̀lú láàárín yín àní gẹ́gẹ́ bí láàárín ìyókù àwọn orílẹ̀-èdè. 14  Èmi jẹ́ ajigbèsè sí àwọn Gíríìkì àti àwọn Aláìgbédè, sí àwọn ọlọ́gbọ́n+ àti àwọn òpònú: 15  nítorí náà, ìháragàgà wà ní ìhà ọ̀dọ̀ mi láti polongo ìhìn rere+ pẹ̀lú fún ẹ̀yin tí ẹ wà ní Róòmù.+ 16  Nítorí èmi kò tijú+ ìhìn rere; ní ti tòótọ́, ó jẹ́ agbára Ọlọ́run+ fún ìgbàlà sí gbogbo ẹni tí ó ní ìgbàgbọ́,+ fún Júù lákọ̀ọ́kọ́+ àti pẹ̀lú fún Gíríìkì;+ 17  nítorí nínú rẹ̀ ni a ti ń ṣí òdodo+ Ọlọ́run payá nítorí ìgbàgbọ́+ àti sí ìgbàgbọ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Ṣùgbọ́n ẹni tí í ṣe olódodo—nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ni yóò yè.”+ 18  Nítorí ìrunú+ Ọlọ́run ni a ń ṣí payá láti ọ̀run lòdì sí gbogbo àìṣèfẹ́ Ọlọ́run àti àìṣòdodo+ àwọn ènìyàn tí wọ́n ń tẹ òtítọ́+ rì ní ọ̀nà àìṣòdodo,+ 19  nítorí pé ohun tí a lè mọ̀ nípa Ọlọ́run fara hàn kedere láàárín wọn,+ nítorí Ọlọ́run mú kí ó fara hàn kedere sí wọn.+ 20  Nítorí àwọn ànímọ́ rẹ̀ tí a kò lè rí+ ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú,+ nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá,+ àní agbára ayérayé+ àti jíjẹ́ Ọlọ́run+ rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní àwíjàre;+ 21  nítorí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ Ọlọ́run, wọn kò yìn ín lógo gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀,+ ṣùgbọ́n wọ́n di olórí òfìfo+ nínú èrò wọn, ọkàn-àyà wọn tí kò mòye sì di èyí tí ó ṣókùnkùn.+ 22  Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń tẹnu mọ́ ọn pé àwọn jẹ́ ọlọ́gbọ́n, wọ́n ya òmùgọ̀,+ 23  wọ́n sì yí ògo+ Ọlọ́run tí kò lè díbàjẹ́ dà sí ohun kan tí ó dà bí àwòrán+ ènìyàn tí ó lè díbàjẹ́ àti àwọn ẹyẹ àti àwọn ẹ̀dá ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin àti àwọn ohun tí ń rákò.+ 24  Nítorí náà, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn tí ó wà nínú ọkàn-àyà wọn, Ọlọ́run jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́ fún ìwà àìmọ́,+ kí wọ́n lè tàbùkù sí ara+ wọn láàárín wọn,+ 25  àní àwọn tí wọ́n fi irọ́+ ṣe pàṣípààrọ̀ òtítọ́+ Ọlọ́run, tí wọ́n ń júbà, tí wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún ìṣẹ̀dá dípò Ẹni tí ó ṣẹ̀dá, tí ó jẹ́ ẹni ìbùkún títí láé. Àmín. 26  Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́ fún ìdálọ́rùn tí ń dójú tini fún ìbálòpọ̀ takọtabo,+ nítorí àwọn obìnrin wọn yí ìlò ara wọn lọ́nà ti ẹ̀dá padà sí èyí tí ó lòdì sí ìwà ẹ̀dá;+ 27  bákan náà, àní àwọn ọkùnrin fi ìlò obìnrin+ lọ́nà ti ẹ̀dá sílẹ̀, wọ́n sì di ẹni tí a mú ara wọn gbiná lọ́nà lílenípá nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn sí ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì, àwọn ọkùnrin pẹ̀lú ọkùnrin,+ ń ṣe ohun ìbàjẹ́,+ wọ́n sì ń gba èrè iṣẹ́+ kíkún nínú ara wọn, èyí tí ó yẹ fún ìṣìnà wọn.+ 28  Àti pé gan-an gẹ́gẹ́ bí wọn kò ti tẹ́wọ́ gba mímọ Ọlọ́run nínú ìmọ̀ pípéye,+ Ọlọ́run jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́ fún ipò èrò-orí+ tí kò ní ìtẹ́wọ́gbà, láti ṣe àwọn ohun tí kò yẹ,+ 29  bí wọ́n ti kún fún gbogbo àìṣòdodo,+ ìwà burúkú,+ ojúkòkòrò,+ ìwà búburú,+ wọ́n kún fún ìlara,+ ìṣìkàpànìyàn,+ gbọ́nmi-si omi-ò-to,+ ẹ̀tàn,+ inú burúkú,+ wọ́n jẹ́ asọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́,+ 30  àwọn asọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn,+ olùkórìíra Ọlọ́run, aláfojúdi,+ onírera,+ ajọra-ẹni-lójú,+ olùhùmọ̀ ohun aṣeniléṣe,+ aṣàìgbọràn sí òbí,+ 31  aláìní òye,+ olùyẹ àdéhùn,+ aláìní ìfẹ́ni àdánidá,+ aláìláàánú.+ 32  Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn wọ̀nyí mọ àṣẹ àgbékalẹ̀ òdodo Ọlọ́run+ dunjú, pé àwọn tí ń fi irú nǹkan báwọ̀nyí ṣe ìwà hù yẹ fún ikú,+ kì í ṣe pé wọ́n ń bá a nìṣó ní ṣíṣe wọ́n nìkan ni ṣùgbọ́n wọ́n tún fohùn ṣọ̀kan+ pẹ̀lú àwọn tí ń fi wọ́n ṣe ìwà hù.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé