Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Orin Sólómọ́nì 7:1-13

7  “Àwọn ìṣísẹ̀ rẹ mà lẹ́wà nínú sálúbàtà+ rẹ o, ìwọ ọmọbìnrin ọlọ́kàn ìmúratán!+ Ìyọlẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ itan rẹ dà bí àwọn ohun ọ̀ṣọ́,+ iṣẹ́ ọwọ́ oníṣọ̀nà.  Ìdodo rẹ jẹ́ àwokòtò róbótó. Má ṣe jẹ́ kí ó ṣaláìní àdàlù wáìnì.+ Ikùn rẹ jẹ́ òkìtì àlìkámà, tí a fi àwọn òdòdó lílì+ ṣe ọgbà yí ká.  Ọmú rẹ méjèèjì dà bí ọmọ méjì, ìbejì abo àgbàlàǹgbó.+  Ọrùn+ rẹ dà bí ilé gogoro eyín erin. Ojú+ rẹ dà bí odò adágún ní Hẹ́ṣíbónì,+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnubodè Bati-rábímù. Imú rẹ dà bí ilé gogoro Lẹ́bánónì, tí ó dojú kọ Damásíkù.  Orí rẹ lára rẹ dà bí Kámẹ́lì,+ àwọn jọ̀lọ̀mì+ irun orí rẹ sì dà bí irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró.+ Ìṣànwálẹ̀ rẹ̀ gbé ọba dè.+  O mà lẹ́wà o, o mà wuni o, ìwọ ọ̀dọ́mọbìnrin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, láàárín àwọn ohun tí ń mú inú dídùn kíkọyọyọ wá!+  Ìdúró rẹ yìí jọ igi+ ọ̀pẹ, ọmú+ rẹ sì jọ òṣùṣù èso déètì.+  Mo wí pé, ‘Èmi yóò gun igi ọ̀pẹ lọ, kí n lè di àwọn ọ̀pá èso déètì rẹ̀ mú.’ Jọ̀wọ́, kí ọmú rẹ dà bí òṣùṣù àjàrà, kí ìtasánsán imú rẹ sì dà bí àwọn èso ápù,  kí òkè ẹnu rẹ sì dà bí wáìnì+ tí ó dára jù lọ, èyí tí ń lọ tìnrín+ fún olólùfẹ́ mi, tí ó rọra ń ṣàn lórí ètè àwọn tí ó sùn.” 10  “Ti olólùfẹ́ mi ni èmi,+ ọ̀dọ̀ mi sì ni ọkàn rẹ̀ ń fà sí.+ 11  Wá, ìwọ olólùfẹ́ mi, jẹ́ kí a jáde lọ sí pápá;+ jẹ́ kí a wọ̀ sí àárín àwọn ewéko làálì.+ 12  Jẹ́ kí a dìde ní kùtùkùtù lọ sí àwọn ọgbà àjàrà, kí a lè rí i bóyá àjàrà ti rú jáde,+ bóyá ìtànná ti là,+ bóyá àwọn igi pómégíránétì ti yọ ìtànná òdòdó.+ Ibẹ̀ ni èmi yóò ti fún ọ ní àwọn ìfìfẹ́hàn mi.+ 13  Àwọn máńdírékì+ pàápàá ti tú ìtasánsán wọn jáde, gbogbo onírúurú èso+ tí ó jẹ́ ààyò jù lọ sì ń bẹ lẹ́bàá àwọn ẹnu ọ̀nà àbáwọlé wa. Àwọn tí ó jẹ́ tuntun àti ẹ̀gbẹ ni mo ti tò jọ pa mọ́ fún ọ, ìwọ olólùfẹ́ mi.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé