Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Orin Sólómọ́nì 6:1-13

6  “Ibo ni olólùfẹ́ rẹ lọ, ìwọ arẹwà jù lọ nínú àwọn obìnrin?+ Ibo ni olólùfẹ́ rẹ yíjú sí, kí a lè bá ọ wá a?”  “Olólùfẹ́ mi ti sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ọgbà rẹ̀,+ síbi àwọn ebè títẹ́ fún àwọn ọ̀gbìn+ eléròjà títa sánsán ti inú ọgbà, láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn+ láàárín àwọn ọgbà, àti láti já àwọn òdòdó lílì.  Ti olólùfẹ́ mi ni èmi, tèmi sì ni olólùfẹ́ mi.+ Ó ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn+ láàárín àwọn òdòdó lílì.”  “Ìwọ lẹ́wà, ìwọ ọ̀dọ́mọbìnrin alábàákẹ́gbẹ́ mi,+ bí Ìlú Ńlá Wíwuni,+ tí ó dára rèǹtè-rente bí Jerúsálẹ́mù,+ tí ó kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ bí àwùjọ ẹgbẹ́+ tí ó kóra jọ yí àwọn ọ̀págun+ ká.  Yí ojú+ rẹ kúrò ní iwájú mi, nítorí wọ́n ti mú mi jí gìrì. Irun rẹ dà bí agbo àwọn ewúrẹ́ tí ó tọ kúṣọ́ sílẹ̀ láti Gílíádì.+  Eyín rẹ dà bí agbo àwọn abo àgùntàn tí ó gòkè wá láti ibi ìwẹ̀, tí gbogbo wọ́n ń bí ìbejì, láìsí ìkankan nínú wọn tí ó pàdánù àwọn ọmọ rẹ̀ rí.+  Bí awẹ́ pómégíránétì ni àwọn ẹ̀bátí rẹ rí lábẹ́ ìbòjú+ rẹ.  Ọgọ́ta ayaba lè wà àti ọgọ́rin wáhàrì àti àwọn omidan tí kò níye.+  Ọ̀kan ṣoṣo ni àdàbà+ tèmi, onítèmi aláìlẹ́gàn.+ Ọ̀kan ṣoṣo ni ó jẹ́ ti ìyá rẹ̀. Òun ni ẹni mímọ́ gaara tí ó jẹ́ ti ẹni tí ó bí i lọ́mọ. Àwọn ọmọbìnrin rí i, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pè é ní aláyọ̀; àwọn ayaba àti wáhàrì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí yìn ín pé,+ 10  ‘Ta ni obìnrin yìí+ tí ń bojú wolẹ̀ bí ọ̀yẹ̀,+ tí ó lẹ́wà bí òṣùpá+ àrànmọ́jú, tí ó mọ́ gaara bí oòrùn+ tí ń ràn yòò, tí ó kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ bí àwùjọ ẹgbẹ́ tí ó kóra jọ yí àwọn ọ̀págun+ ká?’” 11  “Ọgbà+ àwọn igi oníkóró èso ni mo sọ̀ kalẹ̀ lọ, láti rí àwọn ìrudi ní àfonífojì+ olójú ọ̀gbàrá, láti rí bóyá àjàrà ti rú jáde, bóyá àwọn igi pómégíránétì ti yọ ìtànná.+ 12  Kí n tó mọ̀, ọkàn mi ti gbé mi sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin àwọn ènìyàn mi ọlọ́kàn ìmúratán.” 13  “Padà wá, padà wá, ìwọ Ṣúlámáítì! Padà wá, padà wá, kí a lè wò ọ́!”+ “Kí ni ẹ ń wò lára Ṣúlámáítì?”+ “Ohun kan bí ijó ibùdó méjì ni!”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé