Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Orin Sólómọ́nì 4:1-16

4  “Wò ó! Ìwọ lẹ́wà,+ ìwọ ọ̀dọ́mọbìnrin alábàákẹ́gbẹ́ mi. Wò ó! Ìwọ lẹ́wà. Ojú àdàbà+ ni ojú rẹ, lábẹ́ ìbòjú rẹ.+ Irun rẹ dà bí agbo àwọn ewúrẹ́+ tí ó tọ kúṣọ́ sílẹ̀ láti ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Gílíádì.+  Eyín rẹ dà bí agbo àwọn abo àgùntàn+ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ rẹ́ irun wọn, àwọn tí ó gòkè wá láti ibi ìwẹ̀, tí gbogbo wọ́n ń bí ìbejì, láìsí ìkankan nínú wọn tí ó pàdánù àwọn ọmọ rẹ̀ rí.  Ètè rẹ rí bí fọ́nrán òwú rírẹ̀dòdò, ìsọ̀rọ̀ rẹ sì wuni.+ Bí awẹ́ pómégíránétì ni àwọn ẹ̀bátí rẹ rí lábẹ́ ìbòjú+ rẹ.  Ọrùn+ rẹ dà bí ilé gogoro+ Dáfídì, tí a kọ́ sí àwọn ipa ọ̀nà olókùúta, ara èyí tí a gbé ẹgbẹ̀rún apata kọ́ sí, gbogbo àwọn apata+ bìrìkìtì ti àwọn ọkùnrin alágbára ńlá.  Ọmú+ rẹ méjèèjì dà bí ọmọ méjì, ìbejì abo àgbàlàǹgbó, tí ń jẹun láàárín àwọn òdòdó lílì.”+  “Títí ọjọ́ yóò fi fẹ́ yẹ́ẹ́,+ tí òjìji yóò sì sá lọ, èmi yóò bá ọ̀nà mi lọ sí òkè ńlá òjíá àti sí òkè kékeré oje igi tùràrí.”+  “Ìwọ lẹ́wà+ látòkè délẹ̀, ìwọ ọ̀dọ́mọbìnrin alábàákẹ́gbẹ́ mi, kò sì sí àbùkù kankan lára rẹ.+  Bá mi ká lọ láti Lẹ́bánónì, ìwọ ìyàwó,+ bá mi ká lọ láti Lẹ́bánónì.+ Kí o sọ̀ kalẹ̀ láti téńté Anti-Lẹ́bánónì, láti téńté Sénírì,+ àní Hámónì,+ láti ibi tí àwọn kìnnìún ń gbé, láti àwọn òkè ńlá àmọ̀tẹ́kùn.  O ti mú ọkàn-àyà mi lù kìkì, ìwọ arábìnrin mi,+ ìyàwó+ mi, o ti mú ọkàn-àyà mi lù kìkì nípasẹ̀ ọ̀kan lára àwọn ojú rẹ,+ nípasẹ̀ dogbodógbó kan lára ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ. 10  Àwọn ìfìfẹ́hàn rẹ̀ mà lẹ́wà o,+ ìwọ arábìnrin mi, ìyàwó mi! Àwọn ìfìfẹ́hàn rẹ̀ mà kúkú dára ju wáìnì o, ìtasánsán àwọn òróró rẹ sì dára ju gbogbo onírúurú lọ́fínńdà!+ 11  Afárá oyin ń kán tótó+ ní ètè rẹ, ìwọ ìyàwó mi. Oyin+ àti wàrà wà lábẹ́ ahọ́n rẹ, ìtasánsán ẹ̀wù rẹ sì dà bí ìtasánsán+ Lẹ́bánónì. 12  Ọgbà tí a gbégi dínà rẹ̀ ni arábìnrin mi,+ ìyàwó mi, ọgbà tí a gbégi dínà rẹ̀, ìsun tí a fi èdídí dí. 13  Awọ ara rẹ jẹ́ párádísè àwọn pómégíránétì, tòun ti àwọn èso+ tí ó jẹ́ ààyò jù lọ, àwọn ewéko làálì pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ewéko sípíkénádì;+ 14  sípíkénádì+ àti ìtànná sáfúrónì,+ ewéko onípòròpórò+ àti igi sínámónì,+ pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo onírúurú igi tí ó ní oje igi tùràrí, òjíá àti àwọn igi álóè,+ pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn lọ́fínńdà+ tí ó dára jù lọ; 15  àti ìsun àwọn ọgbà, kànga omi mímu,+ àti àwọn odò kéékèèké tí ń ṣàn láti Lẹ́bánónì.+ 16  Jí, ìwọ ẹ̀fúùfù àríwá, sì wọlé wá, ìwọ ẹ̀fúùfù+ gúúsù. Fẹ́ yẹ́ẹ́ sórí ọgbà mi.+ Jẹ́ kí àwọn lọ́fínńdà rẹ̀ máa tú jáde.” “Jẹ́ kí olólùfẹ́ mi wá sínú ọgbà rẹ̀ kí ó sì jẹ àwọn èso rẹ̀ tí ó jẹ́ ààyò jù lọ.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé