Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Orin Sólómọ́nì 3:1-11

3  “Lórí ibùsùn mi ní òru, mo wá ẹni tí ọkàn mi nífẹ̀ẹ́.+ Mo wá ọkùnrin náà, ṣùgbọ́n n kò rí i.  Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n dìde kí n sì lọ yí po nínú ìlú ńlá;+ ní àwọn ojú pópó àti ní àwọn ojúde+ ìlú, jẹ́ kí n wá ẹni tí ọkàn mi nífẹ̀ẹ́. Mo wá a, ṣùgbọ́n n kò rí i.  Àwọn olùṣọ́+ tí ń lọ yí ká nínú ìlú ńlá rí mi, ‘Ẹ ha rí ẹni tí ọkàn mi nífẹ̀ẹ́ bí?’  Gẹ́rẹ́ tí mo kọjá ọ̀dọ̀ wọn ni mo rí ẹni tí ọkàn mi nífẹ̀ẹ́. Mo gbá a mú, n kò sì jẹ́ kí ó lọ, títí mo fi mú un wá sínú ilé ìyá mi àti sínú yàrá inú lọ́hùn-ún ti ẹni tí ó lóyún mi.  Mo ti mú kí ẹ wá sábẹ́ ìbúra,+ ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù, nípasẹ̀ àwọn abo àgbàlàǹgbó tàbí nípasẹ̀ àwọn egbin inú pápá,+ pé kí ẹ má gbìyànjú láti jí tàbí ru ìfẹ́ sókè nínú mi, títí yóò fi ní ìtẹ̀sí láti ru sókè.”+  “Kí ni ohun yìí tí ń jáde bọ̀ láti aginjù bí àwọn ìṣùpọ̀ èéfín adúró bí ọwọ̀n, tí a fi òjíá àti oje igi tùràrí+ mú lóòórùn dídùn, àní pẹ̀lú gbogbo onírúurú àtíkè olóòórùn dídùn ti oníṣòwò?”+  “Wò ó! Àga ìrọ̀gbọ̀kú rẹ̀ ni, èyí tí í ṣe ti Sólómọ́nì. Ọgọ́ta ọkùnrin alágbára ńlá ni ó yí i ká, lára àwọn ọkùnrin alágbára ńlá ti Ísírẹ́lì,+  gbogbo wọn ni ó ní idà, a ti kọ́ wọn ní ogun jíjà, olúkúlùkù pẹ̀lú idà rẹ̀ ní itan rẹ̀ nítorí ìbẹ̀rùbojo ní òru.”+  “Àkéte ìrọ̀gbọ̀kú tí Sólómọ́nì Ọba fi àwọn igi Lẹ́bánónì+ ṣe fún ara rẹ̀ ni. 10  Ó fi fàdákà ṣe ọwọ̀n rẹ̀, ó fi wúrà ṣe ìgbéró rẹ̀. Ó fi irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró ṣe ìjókòó rẹ̀, àwọn ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù ni wọ́n fi tìfẹ́tìfẹ́ pèsè ohun tí ó nílò ní inú rẹ̀.” 11  “Ẹ jáde lọ, ẹ̀yin ọmọbìnrin Síónì, kí ẹ sì wo Sólómọ́nì Ọba tòun ti ọ̀ṣọ́ òdòdó+ tí ìyá+ rẹ̀ hun fún un ní ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀ àti ní ọjọ́ ayọ̀ yíyọ̀ ọkàn-àyà rẹ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé