Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Orin Sólómọ́nì 2:1-17

2  “Ìtànná sáfúrónì+ lásán-làsàn ti pẹ̀tẹ́lẹ̀ etí òkun+ ni mo jẹ́, òdòdó lílì ti àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀.”+  “Bí òdòdó lílì láàárín àwọn èpò ẹlẹ́gùn-ún, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀dọ́mọbìnrin alábàákẹ́gbẹ́ mi láàárín àwọn ọmọbìnrin.”+  “Bí igi ápù+ láàárín àwọn igi igbó, bẹ́ẹ̀ ni olólùfẹ́ mi rí láàárín àwọn ọmọkùnrin.+ Ojú mi wọ ibòji rẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ onígbòónára, ibẹ̀ sì ni mo jókòó, èso rẹ̀ sì dùn mọ́ òkè ẹnu mi.  Ó mú mi wá sínú ilé wáìnì,+ ìfẹ́+ sì ni ọ̀págun+ rẹ̀ lórí mi.  Ẹ fi ìṣù èso àjàrà gbígbẹ tù mí lára,+ ẹ fi èso ápù gbé mi ró; nítorí àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí.+  Ọwọ́ òsì rẹ̀ wà lábẹ́ orí mi; àti ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀—ó gbá mi mọ́ra.+  Mo ti mú kí ẹ wá sábẹ́ ìbúra,+ ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù, nípasẹ̀ àwọn abo àgbàlàǹgbó+ tàbí nípasẹ̀ àwọn egbin+ inú pápá, pé kí ẹ má gbìyànjú láti jí tàbí ru ìfẹ́ sókè nínú mi, títí yóò fi ní ìtẹ̀sí láti ru sókè.+  “Ìró olólùfẹ́+ mi! Wò ó! Ẹni yìí ń bọ̀,+ ó ń gun àwọn òkè ńláńlá, ó ń tọ lórí àwọn òkè kéékèèké.  Olólùfẹ́ mi jọ àgbàlàǹgbó+ tàbí ọmọ akọ àgbọ̀nrín. Wò ó! Ẹni yìí dúró lẹ́yìn ògiri wa, ó ń yọjú lójú fèrèsé, ó ń wò fírífírí lójú àgánrándì fèrèsé.+ 10  Olólùfẹ́ mi dáhùn, ó sì wí fún mi pé, ‘Dìde, ìwọ ọ̀dọ́mọbìnrin alábàákẹ́gbẹ́ mi, arẹwà mi,+ sì jáde ká lọ.+ 11  Nítorí, wò ó! ìgbà+ òjò pàápàá ti kọjá, eji wọwọ ti kásẹ̀ nílẹ̀, ó ti bá ọ̀nà rẹ̀ lọ. 12  Àwọn ìtànná pàápàá ti fara hàn lórí ilẹ̀,+ àkókò náà gan-an fún gígé+ ọwọ́ àjàrà ti dé, ohùn oriri+ ni a sì ti gbọ́ ní ilẹ̀ wa. 13  Ní ti igi+ ọ̀pọ̀tọ́, ó ti ní àwọ̀ tí ó fi hàn pé àwọn ọ̀pọ̀tọ́+ rẹ̀ àkọ́kọ́ ti gbó; àwọn àjàrà sì ti yọ ìtànná òdòdó, wọ́n ti tú ìtasánsán wọn jáde. Dìde, máa bọ̀, ìwọ ọ̀dọ́mọbìnrin alábàákẹ́gbẹ́ mi,+ arẹwà mi, sì jáde ká lọ. 14  Ìwọ àdàbà+ mi tí ó wà ní àwọn ibi kọ́lọ́fín àpáta gàǹgà, ní ibi tí ó lùmọ́ ní ọ̀nà tí ó dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́, fi ìrísí+ rẹ hàn mí, jẹ́ kí n gbọ́ ohùn rẹ, nítorí ohùn rẹ gbádùn mọ́ni, ìrísí rẹ sì dára rèǹtè-rente.’”+ 15  “Ẹ gbá àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ mú fún wa, àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀+ kéékèèké tí ń fi àwọn ọgbà àjàrà ṣe ìjẹ, níwọ̀n bí àwọn ọgbà àjàrà wa ti yọ ìtànná òdòdó.”+ 16  “Tèmi ni olólùfẹ́ mi, tirẹ̀ sì ni èmi.+ Ó ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn+ láàárín àwọn òdòdó lílì.+ 17  Títí ọjọ́ yóò fi fẹ́ yẹ́ẹ́, tí òjìji yóò sì sá lọ, yí padà, ìwọ olólùfẹ́ mi; kí ìwọ kí ó dà bí àgbàlàǹgbó+ tàbí bí ọmọ akọ àgbọ̀nrín lórí àwọn òkè ńlá ìyàsọ́tọ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé