Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Orin Sólómọ́nì 1:1-17

1  Orin+ tí ó dùn jù lọ, tí í ṣe ti Sólómọ́nì:+  “Kí ó fi ìfẹnukonu ẹnu rẹ̀ kò mí lẹ́nu,+ nítorí àwọn ìfìfẹ́hàn rẹ dára ju wáìnì.+  Àwọn òróró+ rẹ dára ní ti ìtasánsán. Orúkọ rẹ dà bí òróró tí a dà jáde.+ Ìdí nìyẹn tí àwọn omidan pàápàá fi nífẹ̀ẹ́ rẹ.  Fà mí ká lọ;+ jẹ́ kí a sáré. Ọba ti mú mi wá sínú àwọn yàrá rẹ̀ inú lọ́hùn-ún!+ Jẹ́ kí a kún fún ìdùnnú, kí a sì yọ̀ nínú rẹ. Jẹ́ kí a mẹ́nu kan àwọn ìfìfẹ́hàn rẹ ju wáìnì.+ Lọ́nà yíyẹ, wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ.+  “Ọ̀dọ́mọbìnrin tí ó jẹ́ adúláwọ̀ ni mí, ṣùgbọ́n mo dára rèǹtè-rente, ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù,+ bí àwọn àgọ́ Kídárì,+ síbẹ̀ bí àwọn aṣọ+ àgọ́ Sólómọ́nì.  Ẹ má wò mí nítorí pé mo jẹ́ aláwọ̀ dúdú, nítorí pé oòrùn ti tajú kán wò mí. Àwọn ọmọ ìyá mi bínú sí mi; wọ́n yàn mí ṣe olùtọ́jú àwọn ọgbà àjàrà,+ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọgbà àjàrà mi, èyí tí ó jẹ́ tèmi, ni èmi kò tọ́jú.  “Sọ fún mi, ìwọ ẹni tí ọkàn mi nífẹ̀ẹ́,+ ibi tí o ti ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn,+ ibi tí o ti ń mú kí agbo ẹran dùbúlẹ̀ ní ọjọ́kanrí. Èé ṣe tí mo fi ní láti dà bí obìnrin tí ọ̀fọ̀ ti bò mọ́lẹ̀ láàárín àwọn agbo ẹran ọ̀sìn ti àwọn alájọṣe rẹ?”  “Bí ìwọ kò bá mọ̀ fúnra rẹ, ìwọ arẹwà jù lọ nínú àwọn obìnrin,+ jáde lọ fúnra rẹ tọ ojú ẹsẹ̀ agbo ẹran lọ, kí o sì kó àwọn ọmọ ewúrẹ́ rẹ jẹ koríko lẹ́gbẹ̀ẹ́ àgọ́ àwọn olùṣọ́ àgùntàn.”  “Èmi fi ọ́ wé abo ẹṣin tèmi nínú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin Fáráò,+ ìwọ ọ̀dọ́mọbìnrin alábàákẹ́gbẹ́ mi.+ 10  Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dára rèǹtè-rente láàárín àwọn ìdì irun, ọrùn rẹ dára rèǹtè-rente nínú okùn ìlẹ̀kẹ̀.+ 11  Àwa yóò ṣe àwọn ohun ọ̀ṣọ́ rìbìtì-rìbìtì ti wúrà fún ọ,+ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn òníní tí a fi fàdákà ṣe.” 12  “Níwọ̀n ìgbà tí ọba wà nídìí tábìlì rẹ̀ tí ó rí rìbìtì, sípíkénádì+ tèmi ń tú ìtasánsán rẹ̀ jáde.+ 13  Bí àpò òjíá+ ni olólùfẹ́ mi rí lójú mi; àárín ọmú+ mi ni yóò sùn mọ́jú. 14  Bí òṣùṣù làálì+ ni olólùfẹ́ mi rí lójú mi, láàárín àwọn ọgbà àjàrà Ẹ́ń-gédì.”+ 15  “Wò ó! Ìwọ lẹ́wà, ọ̀dọ́mọbìnrin alábàákẹ́gbẹ́ mi.+ Wò ó! Ìwọ lẹ́wà. Ojú àdàbà ni ojú rẹ.”+ 16  “Wò ó! Ìwọ lẹ́wà,+ olólùfẹ́ mi, ìwọ wuni pẹ̀lú. Àga ìnàyìn+ wa pẹ̀lú jẹ́ ti eléwé. 17  Àwọn ìtì igi ilé wa títóbi lọ́lá jẹ́ kédárì,+ àwọn igi ìrólé wa jẹ́ igi júnípà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé