Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Oníwàásù 6:1-12

6  Ìyọnu àjálù kan wà tí mo ti rí lábẹ́ oòrùn, ó sì ṣe lemọ́lemọ́ láàárín aráyé:  ọkùnrin tí Ọlọ́run tòótọ́ fún ní ọrọ̀ àti àwọn ohun ìní ti ara àti ògo,+ tí kò sì ṣaláìní ohunkóhun tí òun ń ní ìyánhànhàn fún+ nítorí ọkàn rẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀ tí Ọlọ́run tòótọ́ kò fún un lágbára láti jẹ nínú rẹ̀,+ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ilẹ̀ òkèèrè+ lè jẹ ẹ́. Asán ni èyí, àìsàn búburú sì ni.  Bí ọkùnrin kan bá bímọ ní ọgọ́rùn-ún ìgbà,+ tí ó sì wà láàyè fún ọ̀pọ̀ ọdún, tí ó fi jẹ́ pé iye ọjọ́ ọdún rẹ̀ di púpọ̀,+ síbẹ̀ tí ọkàn rẹ̀ kò rí ìtẹ́lọ́rùn ní ti àwọn ohun rere,+ tí sàréè pàápàá kò sì di tirẹ̀,+ èmi yóò sọ pé ọmọ ìṣẹ́nú sàn jù ú lọ.+  Nítorí pé lásán ni ẹni yìí wá, ó sì lọ nínú òkùnkùn, a ó sì fi òkùnkùn bo orúkọ rẹ̀ mọ́lẹ̀.+  Àní kò rí oòrùn pàápàá, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n.+ Ẹni yìí ni ó sinmi, kì í ṣe ẹni ti ìṣáájú.+  Ká tilẹ̀ sọ pé ó ti wà láàyè fún ẹgbẹ̀rún ọdún ní ìlọ́po méjì, síbẹ̀síbẹ̀ tí kò rí ohun rere,+ kì í ha ṣe ibì kan náà ni gbogbo ènìyàn ń lọ?+  Gbogbo iṣẹ́ àṣekára aráyé jẹ́ fún ẹnu wọn,+ ṣùgbọ́n ọkàn tiwọn pàápàá kì í ní ìtẹ́lọ́rùn.  Nítorí pé àǹfààní wo ni ọlọ́gbọ́n ní lórí arìndìn?+ Kí ni ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ ní, ní mímọ bí a ti ń rìn ní iwájú àwọn alààyè?  Fífi ojú rí sàn ju kí ọkàn+ máa rìn káàkiri. Asán ni èyí pẹ̀lú àti lílépa ẹ̀fúùfù.+ 10  Ohun yòówù tí ó ti wà, a ti dá orúkọ rẹ̀, ohun tí ènìyàn jẹ́ sì ti di mímọ̀;+ kò sì lè ro ẹjọ́ ara rẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí ó lágbára jù ú lọ.+ 11  Nítorí pé ohun púpọ̀ ni ó wà tí ń fa ọ̀pọ̀ asán,+ àǹfààní wo ni ènìyàn ní? 12  Nítorí pé ta ní ń bẹ tí ó mọ ohun rere tí ènìyàn ní nínú ìgbésí ayé+ fún iye ọjọ́ ìgbésí ayé asán rẹ̀, nígbà tí ó ń lò ó bí òjìji?+ Nítorí pé ta ní lè sọ fún ènìyàn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀ lábẹ́ oòrùn?+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé