Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Oníwàásù 5:1-20

5  Ṣọ́ ẹsẹ̀+ rẹ nígbàkigbà tí o bá ń lọ sí ilé Ọlọ́run tòótọ́; kí sísúnmọ́ tòsí láti gbọ́ sì wà,+ dípò mímú ẹbọ wá gẹ́gẹ́ bí àwọn arìndìn ti ń ṣe,+ nítorí wọn kò kíyè sí pé àwọn ń ṣe ohun tí ó burú.+  Má ṣe kánjú ní ti ẹnu rẹ; àti ní ti ọkàn-àyà+ rẹ, kí ó má ṣe kánjú láti mú ọ̀rọ̀ jáde níwájú Ọlọ́run+ tòótọ́. Nítorí pé Ọlọ́run tòótọ́ wà ní ọ̀run+ ṣùgbọ́n ìwọ wà lórí ilẹ̀ ayé. Ìdí nìyẹn tí ó fi yẹ kí ọ̀rọ̀ rẹ mọ níba.+  Nítorí ó dájú pé àlá máa ń wáyé nítorí ọ̀pọ̀ yanturu iṣẹ́ àjókòótì,+ àti ohùn arìndìn nítorí ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀rọ̀.+  Nígbàkigbà tí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Ọlọ́run, má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti san án,+ nítorí pé kò sí níní inú dídùn sí àwọn arìndìn.+ Ohun tí o jẹ́jẹ̀ẹ́, san án.+  Ó sàn kí o má ṣe jẹ́jẹ̀ẹ́+ ju pé kí o jẹ́jẹ̀ẹ́, kí o má sì san án.+  Má ṣe jẹ́ kí ẹnu rẹ mú ẹran ara rẹ ṣẹ̀,+ má ṣe wí níwájú áńgẹ́lì+ pé àṣìṣe ni.+ Èé ṣe tí ìkannú Ọlọ́run tòótọ́ yóò fi ru ní tìtorí ohùn rẹ, tí yóò sì ní láti fọ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ bàjẹ́?+  Nítorí pé ní tìtorí ọ̀pọ̀ yanturu iṣẹ́ àjókòótì ni àwọn àlá+ fi máa ń wà, asán àti ọ̀rọ̀ sì máa ń wà ní ọ̀pọ̀ yanturu. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tòótọ́ ni kí o bẹ̀rù.+  Bí ìwọ bá rí ìnilára èyíkéyìí tí a ṣe sí ẹni tí ó jẹ́ aláìnílọ́wọ́ àti fífi ipá mú ìdájọ́+ àti òdodo kúrò ní àgbègbè abẹ́ àṣẹ, má ṣe jẹ́ kí kàyéfì ṣe ọ́ lórí àlámọ̀rí+ náà, nítorí ẹni tí ó ga ju ẹni+ gíga ń wò ó,+ àwọn tí ó ga sì ń bẹ lókè wọn.  Pẹ̀lúpẹ̀lù, èrè ilẹ̀ ayé wà láàárín gbogbo wọn;+ a sì ṣiṣẹ́ sin ọba tìkára rẹ̀ nítorí pápá.+ 10  Olùfẹ́ fàdákà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olùfẹ́ ọlà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú owó tí ń wọlé wá.+ Asán+ ni èyí pẹ̀lú. 11  Nígbà tí àwọn ohun rere bá di púpọ̀,+ dájúdájú àwọn tí ń jẹ wọ́n a di púpọ̀. Àǹfààní wo sì ni ó jẹ́ fún olúwa wọn atóbilọ́lá, bí kò ṣe pé kí ó máa fi ojú ara rẹ̀ wò wọ́n?+ 12  Dídùn ni oorun+ ẹni tí ń ṣiṣẹ́ sìn, ì báà jẹ́ oúnjẹ díẹ̀ tàbí púpọ̀ ni ó jẹ; ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ tí ó jẹ́ ti ọlọ́rọ̀ kì í jẹ́ kí ó sùn. 13  Ìyọnu àjálù ńláǹlà wà tí mo ti rí lábẹ́ oòrùn: ọrọ̀ tí a fi pa mọ́ fún olúwa wọn atóbilọ́lá sí ìyọnu àjálù+ rẹ̀. 14  Ọrọ̀ wọnnì sì ti ṣègbé+ nítorí iṣẹ́ àjókòótì oníyọnu àjálù, ó sì ti bí ọmọ nígbà tí kò sí nǹkan kan rárá lọ́wọ́ rẹ̀.+ 15  Gan-an gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe jáde wá láti inú ikùn ìyá rẹ̀, ìhòòhò ni ènìyàn yóò tún lọ,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe wá; ènìyàn kò sì lè kó+ nǹkan kan lọ rárá nínú iṣẹ́ àṣekára rẹ̀, èyí tí ó lè mú dání lọ ní ọwọ́ rẹ̀. 16  Ìyọnu àjálù ńláǹlà sì ni èyí pẹ̀lú pé: gan-an gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe wá, bẹ́ẹ̀ náà ni ènìyàn yóò lọ; kí sì ni èrè tí ń bẹ fún ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ kárakára fún ẹ̀fúùfù?+ 17  Pẹ̀lúpẹ̀lù, inú òkùnkùn ni ó ti ń jẹun ní gbogbo ọjọ́ rẹ̀, pẹ̀lú pákáǹleke+ púpọ̀ gan-an, tòun ti àìsàn àti ìdí fún ìkannú. 18  Wò ó! Ohun tí ó dára jù lọ tí èmi alára ti rí, èyí tí ó ṣe rèterète, ni pé kí ènìyàn máa jẹ kí ó sì máa mu kí ó sì rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́+ àṣekára rẹ̀, èyí tí ó fi ń ṣiṣẹ́ kárakára lábẹ́ oòrùn ní iye ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ̀ tí Ọlọ́run tòótọ́ fi fún un, nítorí ìyẹn ni ìpín rẹ̀. 19  Pẹ̀lúpẹ̀lù, olúkúlùkù ẹni tí Ọlọ́run tòótọ́ fi ọrọ̀ àti àwọn ohun ìní+ ti ara fún, ó tilẹ̀ ti fún un lágbára láti jẹ nínú rẹ̀+ àti láti kó ìpín tirẹ̀ lọ àti láti máa yọ̀ nínú iṣẹ́+ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí.+ 20  Nítorí, kì í ṣe ìgbà gbogbo ni yóò máa rántí àwọn ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ̀, nítorí pé Ọlọ́run tòótọ́ mú ọwọ́ rẹ̀ dí pẹ̀lú ayọ̀ yíyọ̀ ọkàn-àyà rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé