Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Oníwàásù 4:1-16

4  Èmi alára sì padà, kí n lè rí gbogbo ìwà ìninilára+ tí a ń hù lábẹ́ oòrùn, sì wò ó! omijé àwọn tí a ń ni lára,+ ṣùgbọ́n wọn kò ní olùtùnú;+ ọ̀dọ̀ àwọn tí ń ni wọ́n lára sì ni agbára wà, tí ó fi jẹ́ pé wọn kò ní olùtùnú.  Mo sì yọ̀ fún àwọn òkú tí ó ti kú jù fún àwọn alààyè tí ó ṣì wà láàyè.+  Nítorí náà, ẹni tí kò tíì sí,+ tí kò tíì rí iṣẹ́ oníyọnu àjálù tí a ń ṣe lábẹ́ oòrùn,+ sàn ju àwọn méjèèjì.  Èmi alára sì ti rí gbogbo iṣẹ́ àṣekára àti gbogbo ìgbóṣáṣá nínú iṣẹ́,+ pé ó túmọ̀ sí bíbá ẹnì kìíní-kejì díje;+ asán ni èyí pẹ̀lú àti lílépa ẹ̀fúùfù.  Arìndìn ká ọwọ́ rẹ̀ pọ̀,+ ó sì ń jẹ ẹran ara òun tìkára rẹ̀.+  Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílépa ẹ̀fúùfù.+  Èmi alára padà kí n lè rí asán tí ń bẹ lábẹ́ oòrùn:  Ẹnì kan ń bẹ, ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kejì;+ pẹ̀lúpẹ̀lù, kò ní ọmọ, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ará,+ ṣùgbọ́n gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ kò lópin. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ọrọ̀ kò tẹ́ ojú rẹ̀ lọ́rùn:+ “Tìtorí ta ni mo fi ń ṣiṣẹ́ kárakára tí mo sì ń mú kí ọkàn mi ṣaláìní àwọn ohun rere?”+ Asán ni èyí pẹ̀lú, iṣẹ́ àjókòótì+ oníyọnu àjálù sì ni.  Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan,+ nítorí pé wọ́n ní ẹ̀san rere fún iṣẹ́+ àṣekára wọn. 10  Nítorí, bí ọ̀kan nínú wọ́n bá ṣubú, èkejì lè gbé alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ dìde.+ Ṣùgbọ́n báwo ni yóò ṣe rí fún ẹnì kan ṣoṣo tí ó ṣubú nígbà tí kò sí ẹlòmíràn láti gbé e dìde?+ 11  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí ẹni méjì bá dùbúlẹ̀ pa pọ̀, wọn yóò sì móoru dájúdájú; ṣùgbọ́n báwo ni ẹyọ ẹnì kan ṣoṣo ṣe lè móoru?+ 12  Bí ẹnì kan bá sì lè borí ẹni tí ó dá wà, ẹni méjì tí ó wà pa pọ̀ lè mú ìdúró wọn láti dojú kọ ọ́.+ Okùn onífọ́nrán mẹ́ta ni a kò sì lè tètè fà já sí méjì. 13  Ọmọdé+ tí ó jẹ́ aláìní ṣùgbọ́n tí ó gbọ́n sàn ju ọba+ tí ó ti darúgbó ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ arìndìn, ẹni tí kò wá mọ̀ tó, tí a ó fi máa kìlọ̀ fún un mọ́.+ 14  Nítorí inú ilé ẹ̀wọ̀n ni ó ti jáde lọ di ọba,+ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nínú ipò ọba ẹni yìí, aláìnílọ́wọ́ ni a bí i.+ 15  Mo ti rí gbogbo àwọn alààyè tí ń rìn káàkiri lábẹ́ oòrùn, bí ó ti máa ń rí fún ọmọ, tí ó jẹ́ ìkejì, tí ó dìde dúró ní ipò èkejì rẹ̀.+ 16  Gbogbo àwọn ènìyàn náà kò lópin, gbogbo àwọn tí òun wà ṣáájú wọn;+ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn ẹ̀yìn ìgbà náà kì yóò yọ̀ nínú rẹ̀,+ nítorí asán ni èyí pẹ̀lú àti lílépa ẹ̀fúùfù.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé