Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Oníwàásù 2:1-26

2  Èmi, àní èmi, sọ nínú ọkàn-àyà+ mi pé: “Wá nísinsìnyí, jẹ́ kí n fi ayọ̀ yíyọ̀+ dán ọ wò. Pẹ̀lúpẹ̀lù, rí ohun rere.”+ Sì wò ó! asán ni èyíinì pẹ̀lú.  Mo sọ fún ẹ̀rín pé: “Ìsínwín!”+ àti fún ayọ̀ yíyọ̀+ pé: “Kí ni eléyìí ń ṣe?”  Mo fi ọkàn-àyà mi ṣàyẹ̀wò nípa fífi wáìnì+ pàápàá mú ara mi yá gágá, bí mo ti ń fi ọgbọ́n+ ṣamọ̀nà ọkàn-àyà mi, àní láti gbá ìwà ẹ̀gọ̀ mú títí èmi yóò fi rí ohun rere tí ó wà fún àwọn ọmọ aráyé nínú ohun tí wọ́n ṣe lábẹ́ ọ̀run ní iye ọjọ́ ìgbésí ayé wọn.+  Mo kó wọnú àwọn iṣẹ́ ńláǹlà.+ Mo kọ́ àwọn ilé fún ara mi;+ mo gbin àwọn ọgbà àjàrà fún ara mi.+  Mo ṣe àwọn ọgbà àti ọgbà ìtura fún ara mi,+ mo sì gbin gbogbo onírúurú igi eléso sínú wọn.  Mo ṣe àwọn adágún omi fún ara mi,+ láti máa fi wọ́n bomi rin igbó tí ń mú àwọn igi jáde.+  Mo ní àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin,+ mo sì wá ní àwọn ọmọ agbo ilé.+ Pẹ̀lúpẹ̀lù, mo wá ní àwọn ohun ọ̀sìn, màlúù àti agbo ẹran ní ìwọ̀n púpọ̀ rẹpẹtẹ, mo ní wọn ju gbogbo àwọn tí ó wà ṣáájú mi ní Jerúsálẹ́mù.+  Mo tún kó fàdákà àti wúrà jọ rẹpẹtẹ fún ara mi,+ àti dúkìá tí ó jẹ́ àkànṣe ìní àwọn ọba àti àwọn àgbègbè+ abẹ́ àṣẹ. Mo kó àwọn ọkùnrin akọrin àti àwọn obìnrin akọrin+ jọ fún ara mi àti àwọn ohun tí ó jẹ́ inú dídùn kíkọyọyọ+ fún àwọn ọmọ aráyé, ọmọge, àní àwọn ọmọge.+  Mo tóbi, mo sì pọ̀ sí i ju ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ pé ó wà ṣáájú mi ní Jerúsálẹ́mù.+ Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọgbọ́n tèmi ṣì jẹ́ tèmi síbẹ̀.+ 10  Ohunkóhun tí ojú mi sì béèrè ni èmi kò fi dù ú.+ Èmi kò fawọ́ ayọ̀ yíyọ̀ èyíkéyìí sẹ́yìn fún ọkàn-àyà mi, nítorí pé ọkàn-àyà mi kún fún ìdùnnú nítorí gbogbo iṣẹ́+ àṣekára mi, èyí sì wá jẹ́ ìpín mi nínú gbogbo iṣẹ́+ àṣekára mi. 11  Èmi, àní èmi, sì yíjú sí gbogbo iṣẹ́ mi tí ọwọ́ mi ti ṣe, àti sí iṣẹ́ àṣekára tí mo ti ṣiṣẹ́ kárakára láti ṣe ní àṣeparí,+ sì wò ó! asán ni gbogbo rẹ̀ àti lílépa ẹ̀fúùfù,+ kò sì sí nǹkan kan tí ó ní àǹfààní lábẹ́ oòrùn.+ 12  Èmi, àní èmi, sì yí padà láti wo ọgbọ́n+ àti ìṣiwèrè àti ìwà ẹ̀gọ̀;+ nítorí pé kí ni ará ayé tí ń wọlé bọ̀ lẹ́yìn ọba lè ṣe? Ohun tí àwọn ènìyàn ti ṣe tẹ́lẹ̀ ni. 13  Èmi, àní èmi, sì rí i pé àǹfààní púpọ̀ wà fún ọgbọ́n jù fún ìwà ẹ̀gọ̀,+ bí àǹfààní púpọ̀ ti wà fún ìmọ́lẹ̀ jù fún òkùnkùn.+ 14  Ní ti ọlọ́gbọ́n, ojú rẹ̀ wà ní orí+ rẹ̀; ṣùgbọ́n arìndìn ń rìn lọ nínú ògédé òkùnkùn.+ Mo sì ti wá mọ̀, èmi pẹ̀lú, pé àtúbọ̀tán kan ṣoṣo ni ó wà tí ó jẹ́ àtúbọ̀tán gbogbo wọn.+ 15  Èmi alára sì wí nínú ọkàn-àyà+ mi pé: “Irú àtúbọ̀tán kan náà tí ó dé bá arìndìn+ ni yóò jẹ́ àtúbọ̀tán mi, bẹ́ẹ̀ ni, èmi.”+ Kí wá ni ìdí tí mo fi jẹ́ ọlọ́gbọ́n, tí mo jẹ́ bẹ́ẹ̀ púpọ̀ jù+ ní àkókò yẹn? Mo sì sọ ní ọkàn-àyà mi pé: “Asán ni èyí pẹ̀lú.” 16  Nítorí a kì í rántí ọlọ́gbọ́n ju arìndìn fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ Ní àwọn ọjọ́ tí ń wọlé bọ̀ nísinsìnyí, olúkúlùkù ni a ti gbàgbé dájúdájú; báwo sì ni ọlọ́gbọ́n yóò ṣe kú? Pa pọ̀ pẹ̀lú arìndìn+ ni. 17  Mo sì kórìíra ìwàláàyè,+ nítorí pé iṣẹ́ tí a ti ṣe lábẹ́ oòrùn jẹ́ oníyọnu àjálù ní ojú ìwòye+ mi, nítorí asán ni gbogbo rẹ̀ àti lílépa ẹ̀fúùfù.+ 18  Èmi, àní èmi, sì kórìíra gbogbo iṣẹ́ àṣekára mi tí mo ṣe kárakára lábẹ́ oòrùn,+ tí èmi yóò fi sílẹ̀ sẹ́yìn fún ènìyàn tí yóò wá wà lẹ́yìn mi.+ 19  Ta sì ni ó mọ̀ bóyá yóò jẹ́ ọlọ́gbọ́n tàbí òmùgọ̀?+ Síbẹ̀, òun ni yóò ṣe àkóso gbogbo iṣẹ́ àṣekára mi tí mo ṣe kárakára, tí mo sì fi ọgbọ́n hàn nídìí rẹ̀ lábẹ́ oòrùn.+ Asán ni èyí pẹ̀lú. 20  Èmi alára sì yí padà sí mímú kí ọkàn-àyà mi bọ́hùn+ nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára tí mo ṣe kárakára lábẹ́ oòrùn. 21  Nítorí ènìyàn kan wà tí iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ jẹ́ pẹ̀lú ọgbọ́n àti pẹ̀lú ìmọ̀ àti pẹ̀lú ìgbóṣáṣá,+ ṣùgbọ́n ènìyàn tí kò ṣiṣẹ́ kára nídìí irúfẹ́ nǹkan bẹ́ẹ̀ ni a ó fi ìpín ẹni yẹn fún.+ Asán ni èyí pẹ̀lú àti ìyọnu àjálù+ ńlá. 22  Nítorí pé kí ni ènìyàn wá ní nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ àti nítorí ìlàkàkà ọkàn-àyà rẹ̀ èyí tí ó fi ń ṣiṣẹ́ kárakára lábẹ́ oòrùn?+ 23  Nítorí ní gbogbo ọjọ́ rẹ̀, iṣẹ́ àjókòótì rẹ̀ jẹ́ ìrora àti pákáǹleke,+ pẹ̀lúpẹ̀lù ọkàn-àyà rẹ̀ kò jẹ́ sùn ní òru.+ Asán gbáà ni èyí pẹ̀lú. 24  Fún ènìyàn, kò sí ohun tí ó sàn ju pé kí ó máa jẹ kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì jẹ́ kí ọkàn òun rí ohun rere nítorí iṣẹ́+ àṣekára rẹ̀. Èyí pẹ̀lú ni èmi ti rí, àní èmi, pé ọwọ́ Ọlọ́run+ tòótọ́ ni èyí ti wá. 25  Nítorí ta ni ó ń jẹ,+ ta sì ni ó ń mu ohun tí ó dára tó tèmi?+ 26  Nítorí ó ti fún ènìyàn tí ó jẹ́ ẹni rere níwájú rẹ̀+ ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ àti ayọ̀ yíyọ̀,+ ṣùgbọ́n ó ti fún ẹlẹ́ṣẹ̀ ní iṣẹ́ àjókòótì ti kíkó jọ àti ṣíṣà jọ, kìkì láti fi fún ẹni rere níwájú Ọlọ́run+ tòótọ́. Asán ni èyí pẹ̀lú àti lílépa ẹ̀fúùfù.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé