Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Oníwàásù 12:1-14

12  Rántí Ẹlẹ́dàá+ rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí, ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin,+ kí àwọn ọjọ́ oníyọnu àjálù tó bẹ̀rẹ̀ sí dé,+ tàbí tí àwọn ọdún náà yóò dé nígbà tí ìwọ yóò wí pé: “Èmi kò ní inú dídùn sí wọn”;+  kí oòrùn àti ìmọ́lẹ̀ àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tó ṣókùnkùn,+ tí àwọn àwọsánmà sì ti padà, lẹ́yìn èyí tí eji wọwọ yóò rọ̀;  ní ọjọ́ tí àwọn olùtọ́jú ilé+ ń wárìrì, tí àwọn ọkùnrin tí ó ní ìmí sì tẹ ara wọn ba,+ tí àwọn obìnrin+ tí ń lọ nǹkan sì ti dáwọ́ iṣẹ́ dúró nítorí pé wọ́n ti kéré níye, tí àwọn ọmọge tí ń wòde lójú fèrèsé+ sì rí i pé òkùnkùn ṣú;  tí a sì ti ti+ àwọn ilẹ̀kùn tí ó jáde sí ojú pópó, nígbà tí ìró ọlọ ìlọ-nǹkan ti rẹlẹ̀,+ tí ènìyàn sì dìde nígbà ìró ẹyẹ, tí gbogbo àwọn ọmọbìnrin orin ń dún lọ́nà rírẹlẹ̀.+  Pẹ̀lúpẹ̀lù, wọ́n ti fòyà ohun tí ó ga, àwọn ohun ìpayà sì wà ní ọ̀nà. Igi álímọ́ńdì sì yọ àwọn ìtànná,+ tata sì ń wọ́ ara rẹ̀ lọ, àgbáyun kápérì sì bẹ́, nítorí pé ènìyàn ń rìn lọ sí ilé+ rẹ̀ pípẹ́ títí, àwọn apohùnréré ẹkún sì ti rìn yí ká ní ojú pópó;+  kí a tó mú okùn fàdákà kúrò, kí àwokòtò wúrà tó fọ́,+ kí ìṣà tí ó wà níbi ìsun tó fọ́, kí àgbá kẹ̀kẹ́ àfifami nídìí ìkùdu tó fọ́.  Nígbà náà ni ekuru yóò padà sí ilẹ̀,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti wà tẹ́lẹ̀, àní ẹ̀mí+ yóò sì padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run+ tòótọ́ tí ó fi í fúnni.+  “Asán pátápátá gbáà!” ni akónijọ+ wí, “Asán+ ni gbogbo rẹ̀.”  Ní àfikún sí òtítọ́ náà pé akónijọ di ọlọ́gbọ́n,+ ó tún ń kọ́ àwọn ènìyàn ní ìmọ̀ nígbà gbogbo,+ ó fẹ̀sọ̀ ronú, ó sì ṣe àyẹ̀wò fínnífínní,+ kí ó lè ṣètò ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe lọ́nà gígún régé.+ 10  Akónijọ wá ọ̀nà àtirí àwọn ọ̀rọ̀ dídùn+ àti àkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ títọ̀nà tí ó jẹ́ òtítọ́.+ 11  Ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n dà bí ọ̀pá kẹ́sẹ́ màlúù,+ àti gẹ́gẹ́ bí ìṣó tí a gbá wọlé+ ni àwọn tí ó jọ̀wọ́ ara wọn fún àkójọ àwọn gbólóhùn; láti ọ̀dọ̀ olùṣọ́ àgùntàn+ kan ni a ti fi wọ́n fúnni. 12  Ní ti ohunkóhun yàtọ̀ sí ìwọ̀nyí, ọmọ mi, gba ìkìlọ̀: Nínú ṣíṣe ìwé púpọ̀, òpin kò sí, fífi ara ẹni fún wọn lápọ̀jù sì ń mú ẹran ara ṣàárẹ̀.+ 13  Òpin ọ̀ràn náà, lẹ́yìn gbígbọ́ gbogbo rẹ̀, ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run+ tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.+ Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn. 14  Nítorí Ọlọ́run tòótọ́ tìkára rẹ̀ yóò mú gbogbo onírúurú iṣẹ́ wá sínú ìdájọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun fífarasin, ní ti bóyá ó dára tàbí ó burú.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé