Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Oníwàásù 11:1-10

11  Fọ́n oúnjẹ+ rẹ sí ojú omi,+ nítorí lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ìwọ yóò tún rí i.+  Fi ìpín fún àwọn méje, tàbí fún àwọn mẹ́jọ pàápàá,+ nítorí ìwọ kò mọ ìyọnu àjálù tí yóò ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.+  Bí àwọsánmà bá kún fún omi, wọn a tú kìkìdá eji wọwọ dà sórí ilẹ̀ ayé;+ bí igi kan bá sì ṣubú sí gúúsù tàbí sí àríwá, ibi tí igi+ náà ṣubú sí, ibẹ̀ ni yóò wà.  Ẹni tí ó bá ń ṣọ́ ẹ̀fúùfù kì yóò fún irúgbìn; ẹni tí ó bá sì ń wo àwọsánmà kì yóò kárúgbìn.+  Gan-an gẹ́gẹ́ bí ìwọ kò ti mọ̀ nípa ohun tí ó jẹ́ ọ̀nà ẹ̀mí inú àwọn egungun nínú ikùn aboyún,+ ní ọ̀nà kan náà, ìwọ kò mọ iṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́, ẹni tí ń ṣe ohun gbogbo.+  Ní òwúrọ̀, fún irúgbìn rẹ àti títí di ìrọ̀lẹ́, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ sinmi;+ nítorí ìwọ kò mọ ibi tí èyí yóò ti ṣe àṣeyọrí sí rere,+ yálà níhìn-ín tàbí lọ́hùn-ún, tàbí kẹ̀, bóyá àwọn méjèèjì ni yóò dára bákan náà.  Ìmọ́lẹ̀ dùn pẹ̀lú, ó sì dára kí ojú rí oòrùn;+  nítorí bí ènìyàn kan bá tilẹ̀ wà láàyè fún ọ̀pọ̀ ọdún, kí ó máa fi gbogbo rẹ̀ yọ̀.+ Kí ó sì rántí àwọn ọjọ́ òkùnkùn,+ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè pọ̀; asán ni gbogbo ọjọ́ tí ó ti wọlé dé.+  Máa yọ̀,+ ọ̀dọ́kùnrin, ní ìgbà èwe rẹ, sì jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ ṣe ọ́ ní ire ní àwọn ọjọ́ ìgbà ọ̀dọ́kùnrin rẹ, kí o sì máa rìn ní àwọn ọ̀nà ọkàn-àyà rẹ àti nínú àwọn ohun tí ojú rẹ bá rí.+ Ṣùgbọ́n mọ̀ pé ní tìtorí gbogbo ìwọ̀nyí ni Ọlọ́run tòótọ́ yóò ṣe mú ọ wá sínú ìdájọ́.+ 10  Nítorí náà, mú pákáǹleke kúrò ní ọkàn-àyà rẹ, kí o sì taari ìyọnu àjálù kúrò ní ẹran ara+ rẹ; nítorí pé asán+ ni ìgbà èwe àti ìgbà ọ̀ṣìngín nínú ìgbésí ayé.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé