Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Oníwàásù 1:1-18

1  Àwọn ọ̀rọ̀ akónijọ,+ ọmọkùnrin Dáfídì tí í ṣe ọba ní Jerúsálẹ́mù.+  “Asán+ pátápátá gbáà!” ni akónijọ sọ, “asán pátápátá gbáà! Asán+ ni gbogbo rẹ̀!”  Èrè kí ni ènìyàn jẹ nínú gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ tí ó ń ṣe+ kárakára lábẹ́ oòrùn?+  Ìran kan ń lọ,+ ìran kan sì ń bọ̀;+ ṣùgbọ́n ilẹ̀ ayé dúró àní fún àkókò tí ó lọ kánrin.+  Oòrùn pẹ̀lú ti yọ, oòrùn sì wọ̀,+ ó ń mí hẹlẹhẹlẹ sáré bọ̀ ní ipò rẹ̀ níbi tí yóò ti yọ.+  Ẹ̀fúùfù ń lọ sí gúúsù, ó sì ń yí bírí lọ sí àríwá.+ Yí ká àti yí ká ni ó ń yí bírí+ nígbà gbogbo, àwọn ibi ìyíbírí+ rẹ̀ gan-an ni ẹ̀fúùfù sì ń padà sí.  Gbogbo ọ̀gbàrá+ ìgbà òtútù ń ṣàn lọ sínú òkun,+ síbẹ̀síbẹ̀ òkun kò kún.+ Ibi tí àwọn ọ̀gbàrá ìgbà òtútù ti ń ṣàn jáde lọ, ibẹ̀ ni wọ́n ń padà sí, kí wọ́n bàa lè ṣàn jáde lọ.+  Ohun gbogbo ní ń mú kí àárẹ̀ múni;+ kò sí ẹni tí ó lè sọ nípa rẹ̀. Ojú kì í ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú rírí,+ bẹ́ẹ̀ ni etí kì í kún nítorí gbígbọ́.+  Èyí tí ó ti wà, òun ni yóò wà;+ èyí tí a sì ti ṣe, òun ni a ó ṣe; nítorí náà, kò sí ohun tuntun lábẹ́ oòrùn.+ 10  Ohunkóhun ha wà tí ẹnì kan lè sọ nípa rẹ̀ pé: “Wo èyí; tuntun ni”? Ó ti wà tẹ́lẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin;+ ohun tí ó ti wà jẹ́ láti àkókò tí ó ti wà ṣáájú wa.+ 11  Kò sí ìrántí àwọn ènìyàn ìgbà àtijọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ti àwọn tí yóò wá wà lẹ́yìn náà pẹ̀lú.+ Àní kì yóò sí ìrántí wọn láàárín àwọn tí yóò tún wá wà lẹ́yìn náà.+ 12  Ó ṣẹlẹ̀ pé èmi, akónijọ, jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì ní Jerúsálẹ́mù.+ 13  Mo sì gbé ọkàn-àyà mi lé wíwá àti títọsẹ̀ ọgbọ́n+ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ohun gbogbo tí a ti ṣe lábẹ́ ọ̀run—iṣẹ́ àjókòótì oníyọnu àjálù tí Ọlọ́run ti fi fún àwọn ọmọ aráyé láti jókòó tì.+ 14  Mo rí gbogbo iṣẹ́ tí a ṣe lábẹ́ oòrùn,+ sì wò ó! asán ni gbogbo rẹ̀ àti lílépa ẹ̀fúùfù.+ 15  Èyí tí a ṣe ní wíwọ́ ni a kò lè mú tọ́,+ èyí tí ó sì kù káàtó ni kò ṣeé ṣe láti kà. 16  Èmi, àní èmi, bá ọkàn-àyà+ mi sọ̀rọ̀, pé: “Wò ó! Èmi fúnra mi ti pọ̀ sí i gidigidi nínú ọgbọ́n ju ẹnikẹ́ni tí ó wà ṣáájú mi ní Jerúsálẹ́mù,+ ọkàn-àyà tèmi sì rí ọgbọ́n àti ìmọ̀ púpọ̀ gan-an.”+ 17  Mo sì tẹ̀ síwájú láti fi ọkàn-àyà mi fún mímọ ọgbọ́n àti fún mímọ ìṣiwèrè,+ mo sì ti wá mọ ìwà ẹ̀gọ̀,+ pé eléyìí pẹ̀lú jẹ́ lílépa ẹ̀fúùfù.+ 18  Nítorí pé pákáǹleke+ púpọ̀ yanturu wà nínú ọgbọ́n púpọ̀ yanturu, tí ó fi jẹ́ pé ẹni tí ń mú ìmọ̀ pọ̀ sí i ń mú ìrora+ pọ̀ sí i.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé