Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Nehemáyà 9:1-38

9  Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù yìí,+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó ara wọn jọpọ̀ nínú gbígbààwẹ̀+ àti nínú aṣọ àpò ìdọ̀họ+ pẹ̀lú ìdọ̀tí+ lára wọn.  Àwọn irú-ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí ya ara wọn sọ́tọ̀+ kúrò lára gbogbo ọmọ ilẹ̀ òkèèrè,+ wọ́n sì dúró láti jẹ́wọ́+ ẹ̀ṣẹ̀+ wọn àti ìṣìnà àwọn baba+ wọn.  Lẹ́yìn náà, wọ́n dìde dúró ní ipò wọn,+ wọ́n sì fi ìdá mẹ́rin ọjọ́+ ka ìwé òfin+ Jèhófà Ọlọ́run wọn sókè; ìdá mẹ́rin ni wọ́n sì fi ń jẹ́wọ́,+ tí wọ́n sì ń tẹrí ba mọ́lẹ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run wọn.+  Jéṣúà àti Bánì, Kádímíélì, Ṣebanáyà, Búnì, Ṣerebáyà,+ Bánì àti Kénánì sì bẹ̀rẹ̀ sí dìde lórí pèpéle+ àwọn ọmọ Léfì, wọ́n sì ké jáde ní ohùn rara+ sí Jèhófà Ọlọ́run wọn.  Àwọn ọmọ Léfì, Jéṣúà, àti Kádímíélì, Bánì, Haṣabanéáyà, Ṣerebáyà, Hodáyà, Ṣebanáyà àti Petaháyà sì wí pé: “Ẹ dìde, ẹ fi ìbùkún+ fún Jèhófà Ọlọ́run yín láti àkókò tí ó lọ kánrin dé àkókò tí ó lọ kánrin.+ Kí wọ́n sì fi ìbùkún fún orúkọ+ rẹ ológo, èyí tí a gbé ga lékè gbogbo ìbùkún àti ìyìn.  “Ìwọ nìkan ṣoṣo ni Jèhófà;+ ìwọ alára ṣe ọ̀run,+ àní ọ̀run àwọn ọ̀run, àti gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn,+ ilẹ̀ ayé+ àti ohun gbogbo tí ó wà lórí rẹ̀,+ àwọn òkun+ àti ohun gbogbo tí ó wà nínú wọn;+ ìwọ sì ń pa gbogbo wọn mọ́ láàyè; ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run+ sì ń tẹrí ba fún ọ.  Ìwọ ni Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, ẹni tí ó yan Ábúrámù,+ tí ó sì mú un jáde kúrò ní Úrì ti àwọn ará Kálídíà,+ tí ó sì sọ orúkọ rẹ̀ di Ábúráhámù.+  Ìwọ sì rí i pé ọkàn-àyà rẹ̀ jẹ́ aṣeégbíyèlé níwájú rẹ;+ nítorí náà, dídá májẹ̀mú+ kan pẹ̀lú rẹ̀ wáyé láti fún un ní ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì àti àwọn Pérísì àti àwọn ará Jébúsì àti àwọn Gẹ́gáṣì, láti fi í fún irú-ọmọ rẹ̀;+ ìwọ sì bẹ̀rẹ̀ sí mú ọ̀rọ̀ rẹ ṣẹ, nítorí pé ìwọ jẹ́ olódodo.+  “Ìwọ sì rí+ ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ àwọn baba ńlá wa níṣẹ̀ẹ́ ní Íjíbítì, o sì gbọ́+ igbe ẹkún wọn ní Òkun Pupa. 10  Nígbà náà ni ìwọ pèsè àwọn àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu lòdì sí Fáráò àti gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ àti gbogbo ènìyàn ilẹ̀ rẹ̀,+ nítorí o mọ̀ pé wọ́n fi ìkùgbù+ gbé ìgbésẹ̀ sí wọn; ìwọ sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe orúkọ+ fún ara rẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí yìí. 11  Ìwọ sì pín òkun níyà+ níwájú wọn, tí wọ́n fi gba àárín òkun sọdá lórí ilẹ̀ gbígbẹ;+ àwọn tí ń lépa wọn ni ìwọ sì fi sọ̀kò sínú ibú+ bí òkúta+ nínú omi tí ó lágbára.+ 12  Ọwọ̀n àwọsánmà sì ni o fi ṣamọ̀nà wọn ní ọ̀sán,+ àti ọwọ̀n iná ní òru,+ láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀+ ní ọ̀nà tí wọn yóò rìn. 13  Ìwọ sì sọ kalẹ̀+ sórí Òkè Ńlá Sínáì, o sì bá wọn sọ̀rọ̀ láti ọ̀run,+ o sì tẹ̀ síwájú láti fún wọn ní àwọn ìpinnu ìdájọ́ dídúróṣánṣán+ àti àwọn òfin òtítọ́,+ àwọn ìlànà+ àti àwọn àṣẹ+ tí ó dára. 14  Sábáàtì+ rẹ mímọ́ ni o sì sọ di mímọ̀ fún wọn, àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà àti òfin ni o pa láṣẹ fún wọn nípasẹ̀ Mósè ìránṣẹ́ rẹ.+ 15  O sì fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run fún ebi wọn,+ o sì mú omi jáde fún wọn láti inú àpáta gàǹgà fún òùngbẹ wọn,+ o sì ń bá a lọ láti sọ fún wọn pé kí wọ́n wọnú+ rẹ̀, kí wọ́n sì fi ilẹ̀ náà tí o ti gbé ọwọ́ rẹ sókè nínú ìbúra láti fi fún wọn ṣe ìní.+ 16  “Àti pé àwọn fúnra wọn, àní àwọn baba ńlá wa, ti fi ìkùgbù+ gbé ìgbésẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí mú ọrùn wọn le,+ wọn kò sì fetí sí àwọn àṣẹ rẹ. 17  Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kọ̀ láti fetí sílẹ̀,+ wọn kò sì rántí+ àwọn ìṣe àgbàyanu tí o ṣe fún wọn, ṣùgbọ́n wọ́n mú ọrùn wọn le,+ wọ́n sì yan olórí kan+ sípò láti padà sí ìsìnrú wọn ní Íjíbítì. Ṣùgbọ́n ìwọ ni Ọlọ́run ìṣe ìdáríjì,+ olóore ọ̀fẹ́+ àti aláàánú,+ tí ń lọ́ra láti bínú,+ tí ó sì pọ̀ yanturu+ ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́, ìwọ kò sì fi wọ́n sílẹ̀.+ 18  Bẹ́ẹ̀ ni, nígbà tí wọ́n ṣe ère dídà ti ọmọ màlúù+ fún ara wọn, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, ‘Èyí ni Ọlọ́run rẹ tí ó mú ọ gòkè kúrò ní Íjíbítì,’+ wọ́n sì ń bá a lọ láti hu ìwà àìlọ́wọ̀ ńláǹlà, 19  ìwọ, àní ìwọ, nínú ọ̀pọ̀ yanturu àánú rẹ kò fi wọ́n sílẹ̀+ nínú aginjù. Ọwọ̀n àwọsánmà kò kúrò lórí wọn ní ọ̀sán láti ṣamọ̀nà wọn ní ọ̀nà,+ bẹ́ẹ̀ ni ọwọ̀n iná kò kúrò ní òru láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀nà tí wọn yóò rìn.+ 20  Ìwọ sì fún wọn ní ẹ̀mí+ rere rẹ láti sọ wọ́n di amòyemèrò, ìwọ kò sì fawọ́ mánà rẹ sẹ́yìn kúró ní ẹnu+ wọn, ìwọ sì fi omi fún wọn fún òùngbẹ+ wọn. 21  Ogójì+ ọdún ni ìwọ fi pèsè oúnjẹ fún wọn ní aginjù. Wọn kò ṣaláìní nǹkan kan.+ Ẹ̀wù wọn kò gbó,+ ẹsẹ̀ wọn kò sì wú.+ 22  “Ìwọ sì bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ìjọba+ àti àwọn ènìyàn fún wọn, o sì pín wọn ní ẹyọ-ẹyọ;+ tí wọ́n fi gba ilẹ̀ Síhónì,+ àní ilẹ̀ ọba Hẹ́ṣíbónì,+ àti ilẹ̀ Ógù+ ọba Báṣánì.+ 23  Àwọn ọmọ wọn ni ìwọ sì sọ di púpọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run.+ Lẹ́yìn náà, o mú wọn wá sí ilẹ̀+ tí o ti ṣèlérí fún àwọn baba ńlá+ wọn pé kí wọ́n wọ̀ láti gbà. 24  Nítorí náà, àwọn ọmọ+ wọn wá, wọ́n sì gba ilẹ̀ náà fi ṣe ìní,+ ìwọ sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹ àwọn olùgbé ilẹ̀ náà, àwọn ọmọ Kénáánì,+ lórí ba+ níwájú wọn, o sì fi wọ́n lé wọn lọ́wọ́, àní àwọn ọba+ wọn àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà,+ láti ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe fẹ́.+ 25  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gba àwọn ìlú ńlá olódi+ àti ilẹ̀ ọlọ́ràá,+ àwọn ilé tí ó kún fún gbogbo ohun rere+ ni wọ́n sì gbà fi ṣe ìní, àwọn ìkùdu tí a gbẹ́,+ àwọn ọgbà àjàrà àti àwọn oko ólífì+ àti àwọn igi fún oúnjẹ ní ọ̀pọ̀ yanturu, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ, wọ́n sì yó,+ wọ́n sì sanra,+ wọ́n sì ń ṣe fàájì nínú oore rẹ ńláǹlà.+ 26  “Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n di aláìgbọ́ràn,+ wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọ,+ wọ́n sì ń gbé òfin rẹ jù sí ẹ̀yìn wọn,+ wọ́n sì pa àwọn wòlíì rẹ,+ àwọn tí ó jẹ́rìí lòdì sí wọn láti mú wọn padà wá sọ́dọ̀ rẹ;+ wọ́n sì ń bá a lọ láti hu ìwà àìlọ́wọ̀ ńláǹlà.+ 27  Nítorí èyí, o fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn elénìní+ wọn, tí ń fa wàhálà bá wọn;+ ṣùgbọ́n ní àkókò wàhálà wọn, wọn a ké jáde sí ọ,+ ìwọ alára a sì gbọ́ láti ọ̀run;+ àti ní ìbámú pẹ̀lú ọ̀pọ̀ yanturu àánú+ rẹ, ìwọ a fún wọn ní olùgbàlà+ tí ó gbà wọ́n là kúrò lọ́wọ́ àwọn elénìní wọn.+ 28  “Ṣùgbọ́n ní gbàrà ti wọ́n bá ti wà nínú ìsinmi, wọn a tún ṣe ohun tí ó burú níwájú rẹ,+ ìwọ a sì fi wọ́n sílẹ̀ sọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, tí yóò tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.+ Lẹ́yìn náà, wọn a padà, wọn a sì ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́,+ ìwọ alára a sì gbọ́ láti ọ̀run,+ ìwọ a sì dá wọn nídè ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pọ̀ yanturu àánú rẹ, léraléra.+ 29  Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ a jẹ́rìí+ lòdì sí wọn láti mú wọn padà wá sínú òfin+ rẹ, àwọn fúnra wọn fi ìkùgbù+ gbé ìgbésẹ̀ pàápàá, wọn kò sì fetí sí àwọn àṣẹ rẹ; wọ́n sì ṣẹ̀+ lòdì sí àwọn ìpinnu ìdájọ́+ rẹ, èyí tí, bí ènìyàn bá pa wọ́n mọ́, yóò máa wà láàyè nípasẹ̀ wọn pẹ̀lú.+ Wọ́n sì ń gún èjìká,+ wọ́n sì mú ọrùn wọn le,+ wọn kò sì fetí sílẹ̀.+ 30  Ṣùgbọ́n ìwọ gbà wọ́n ní àyè fún ọ̀pọ̀ ọdún,+ o sì ń jẹ́rìí+ lòdì sí wọn nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ, wọn kò sì fi etí sílẹ̀.+ Níkẹyìn, o fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn ènìyàn àwọn ilẹ̀ náà.+ 31  Àti nínú ọ̀pọ̀ yanturu àánú rẹ, ìwọ kò pa wọ́n run pátápátá+ tàbí kí o fi wọ́n sílẹ̀;+ nítorí ìwọ jẹ́ Ọlọ́run olóore ọ̀fẹ́+ àti aláàánú.+ 32  “Wàyí o, ìwọ Ọlọ́run wa, Ọlọ́run títóbi,+ alágbára ńlá+ àti amúnikún-fún-ẹ̀rù,+ tí ń pa májẹ̀mú+ àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́+ mọ́, má ṣe jẹ́ kí gbogbo ìnira tí ó bá àwa,+ àwọn ọba+ wa, àwọn ọmọ aládé+ wa àti àwọn àlùfáà+ wa àti àwọn wòlíì+ wa àti àwọn baba ńlá+ wa àti gbogbo ènìyàn rẹ láti ọjọ́ àwọn ọba Ásíríà títí di òní+ yìí, dà bí ohun kékeré níwájú rẹ.+ 33  Ìwọ sì jẹ́ olódodo+ ní ti gbogbo ohun tí ó dé bá wa, nítorí ìwọ ti hùwà lọ́nà ìṣòtítọ́,+ ṣùgbọ́n àwa ni a hùwà burúkú.+ 34  Ní ti àwọn ọba wa, àwọn ọmọ aládé wa, àwọn àlùfáà wa àti àwọn baba ńlá+ wa, wọn kò pa òfin rẹ mọ́,+ bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fiyè sí àwọn àṣẹ+ rẹ tàbí sí gbólóhùn ẹ̀rí rẹ, èyí tí ó fi jẹ́rìí+ lòdì sí wọn. 35  Àti àwọn fúnra wọn—nígbà ìjọba+ wọn àti ní àárín ọ̀pọ̀ yanturu ohun rere+ rẹ tí o fi fún wọn àti ní ilẹ̀ fífẹ̀ tí ó lọ́ràá+ tí o mú wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún wọn, wọn kò sìn ọ́,+ wọn kò sì yí padà kúrò nínú ìṣe búburú wọn.+ 36  Wò ó! A jẹ́ ẹrú+ lónìí; àti ní ti ilẹ̀ tí o fi fún àwọn baba ńlá wa láti jẹ èso rẹ̀ àti ohun rere rẹ̀, wò ó! a jẹ́ ẹrú lórí rẹ̀,+ 37  èso rẹ̀ sì ń pọ̀ gidigidi+ fún àwọn ọba+ tí ìwọ fi ṣolórí wa nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀+ wa, wọ́n sì ń ṣàkóso lórí ara wa àti lórí àwọn ẹran agbéléjẹ̀ wa, bí wọ́n ṣe fẹ́, a sì wà nínú wàhálà ńláǹlà.+ 38  “Nítorí gbogbo èyí, àwa ń ṣe ètò tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé,+ èyí tí ó wà nínú àkọsílẹ̀ tí a sì fi èdìdì+ àwọn ọmọ aládé wa, àwọn ọmọ Léfì wa àti àwọn àlùfáà+ wa jẹ́rìí sí.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé