Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Nehemáyà 8:1-18

8  Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí kó ara wọn jọ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ṣoṣo+ sí ojúde ìlú+ tí ó wà ní àtidé Ẹnubodè Omi.+ Nígbà náà ni wọ́n sọ fún Ẹ́sírà+ adàwékọ láti mú ìwé òfin+ Mósè+ wá, èyí tí Jèhófà pa láṣẹ fún Ísírẹ́lì.+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Ẹ́sírà àlùfáà+ mú òfin náà wá síwájú ìjọ+ àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin àti gbogbo àwọn tí ó ní làákàyè tó láti fetí sílẹ̀,+ ní ọjọ́ kìíní oṣù keje.+  Ó sì ń bá a lọ láti kà+ á sókè ní ojúde ìlú tí ó wà ní àtidé Ẹnubodè Omi, láti àfẹ̀mọ́jú+ títí di ọjọ́kanrí, ní iwájú àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin àti àwọn yòókù tí ó ní làákàyè; etí+ gbogbo ènìyàn náà sì ṣí+ sí ìwé òfin náà.  Ẹ́sírà adàwékọ sì dúró lórí ibi ìdúró-sọ̀rọ̀ tí a fi igi ṣe,+ tí wọ́n ṣe fún àṣeyẹ àkànṣe náà; àwọn tí wọ́n dúró sí ẹ̀bá rẹ̀ ni Matitáyà àti Ṣémà àti Ánáyà àti Ùráyà àti Hilikáyà àti Maaseáyà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, àti ní òsì rẹ̀ ni Pedáyà àti Míṣáẹ́lì àti Málíkíjà+ àti Háṣúmù+ àti Haṣi-bádánà, Sekaráyà àti Méṣúlámù.  Ẹ́sírà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣí+ ìwé lójú gbogbo ènìyàn, nítorí ó yọ sókè ju gbogbo ènìyàn náà; bí ó sì ti ṣí i, gbogbo ènìyàn dìde dúró.+  Nígbà náà ni Ẹ́sírà fi ìbùkún fún Jèhófà+ Ọlọ́run tòótọ́, Ẹni ńlá, tí gbogbo àwọn ènìyàn dáhùn pé, “Àmín! Àmín!”+ pẹ̀lú gbígbé ọwọ́+ wọn sókè. Nígbà náà ni wọ́n tẹrí ba mọ́lẹ̀,+ wọ́n sì wólẹ̀ fún Jèhófà ní ìdojúbolẹ̀.+  Jéṣúà àti Bánì àti Ṣerebáyà,+ Jámínì, Ákúbù, Ṣábétáì, Hodáyà, Maaseáyà, Kélítà, Asaráyà, Jósábádì,+ Hánánì, Pẹláyà,+ àní àwọn ọmọ Léfì, sì ń ṣàlàyé òfin fún àwọn ènìyàn,+ bí àwọn ènìyàn náà ti wà ní ìdúró.+  Wọ́n sì ń bá a lọ láti ka ìwé+ náà sókè, láti inú òfin Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n ń làdí rẹ̀, wọ́n sì ń fi ìtumọ̀ sí i; wọ́n sì ń mú kí ìwé kíkà náà yéni.+  Nehemáyà,+ èyíinì ni, Tíṣátà,+ àti Ẹ́sírà+ àlùfáà, adàwékọ, àti àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n ń fún àwọn ènìyàn ní ìtọ́ni sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé: “Ọjọ́ yìí gan-an jẹ́ mímọ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run+ yín. Ẹ má ṣọ̀fọ̀ tàbí kí ẹ sunkún.”+ Nítorí gbogbo àwọn ènìyàn náà ń sunkún bí wọ́n ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ òfin náà.+ 10  Ó sì ń bá a lọ láti wí fún wọn pé: “Ẹ lọ, ẹ jẹ àwọn ohun ọlọ́ràá, kí ẹ sì mu àwọn ohun dídùn, kí ẹ sì fi ìpín+ ránṣẹ́ sí ẹni tí a kò pèsè nǹkan kan sílẹ̀ fún; nítorí ọjọ́ yìí jẹ́ mímọ́ lójú Olúwa wa, ẹ má sì ba inú jẹ́, nítorí ìdùnnú Jèhófà ni odi agbára yín.” 11  Àwọn ọmọ Léfì sì ń mú àwọn ènìyàn náà dákẹ́ pé: “Ẹ dákẹ́! nítorí ọjọ́ yìí jẹ́ mímọ́; ẹ má sì ba inú jẹ́.” 12  Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ènìyàn náà lọ láti jẹ, àti láti mu, àti láti fi ìpín+ ránṣẹ́, wọ́n sì ń bá a lọ nínú ayọ̀ yíyọ̀ ńláǹlà,+ nítorí wọ́n lóye ọ̀rọ̀ tí a ti sọ di mímọ̀ fún wọn.+ 13  Ní ọjọ́ kejì, àwọn olórí àwọn baba gbogbo àwọn ènìyàn náà, àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ Ẹ́sírà adàwékọ, àní láti ní ìjìnlẹ̀ òye nínú ọ̀rọ̀ òfin náà.+ 14  Nígbà náà ni wọ́n wá rí i pé a ti kọ ọ́ sínú òfin pé Jèhófà ti pàṣẹ nípasẹ̀ Mósè+ pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa gbé nínú àwọn àtíbàbà+ nígbà àjọyọ̀ ní oṣù keje,+ 15  pé kí wọ́n sì pòkìkí,+ kí wọ́n sì mú kí ìpè kan la gbogbo ìlú ńlá wọn já, kí ó sì la Jerúsálẹ́mù+ já pé: “Ẹ lọ sí ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá,+ kí ẹ sì mú ewé ólífì+ àti ewé igi òróró àti ewé igi mátílì àti imọ̀ ọ̀pẹ àti ewé igi ẹlẹ́ka púpọ̀ láti fi ṣe àwọn àtíbàbà, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ̀wé rẹ̀.” 16  Àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde lọ láti mú wọn wá láti ṣe àwọn àtíbàbà fún ara wọn, olúkúlùkù sórí òrùlé+ rẹ̀ àti ní àgbàlá+ wọn àti ní àgbàlá ilé Ọlọ́run tòótọ́ àti ní ojúde ìlú+ ní Ẹnubodè Omi+ àti ní ojúde ìlú ní Ẹnubodè Éfúráímù.+ 17  Nípa báyìí, gbogbo ìjọ àwọn tí wọ́n padà láti oko òǹdè ṣe àwọn àtíbàbà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé inú àtíbàbà; nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò tíì ṣe bẹ́ẹ̀ láti ọjọ́ Jóṣúà ọmọkùnrin Núnì+ títí di ọjọ́ yẹn, bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ yíyọ̀ ńláǹlà+ wà. 18  Kíka ìwé òfin Ọlọ́run tòótọ́ sókè sì wà láti ọjọ́ dé ọjọ́,+ láti ọjọ́ kìíní títí di ọjọ́ tí ó kẹ́yìn; wọ́n sì ń ṣe àjọyọ̀ fún ọjọ́ méje, ní ọjọ́ kẹjọ, àpéjọ tí ó ní ọ̀wọ̀ sì wà, gẹ́gẹ bí ìlànà àfilélẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé