Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Nehemáyà 6:1-19

6  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí a sọ fún Sáńbálátì+ àti Tobáyà+ àti fún Géṣémù+ ọmọ ilẹ̀ Arébíà+ àti ìyókù àwọn ọ̀tá wa pé mo ti tún ògiri+ náà mọ àti pé a kò fi àlàfo kan sílẹ̀ nínú rẹ̀ (bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé títí di àkókò yẹn, èmi kò tíì gbé àwọn ilẹ̀kùn+ nà ró sí àwọn ẹnubodè náà),+  Sáńbálátì àti Géṣémù ránṣẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ sí mi pé: “Wá, jẹ́ kí a pàdé+ pọ̀ nípasẹ̀ àdéhùn ní àwọn abúlé pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì Ónò.”+ Ṣùgbọ́n ṣe ni wọ́n ń pète-pèrò láti ṣe ìpalára fún mi.+  Nítorí náà, mo rán àwọn ońṣẹ́ sí wọn+ pé: “Iṣẹ́ ńlá ni mo ń ṣe,+ èmi kò sì lè sọ̀ kalẹ̀ wá. Èé ṣe tí iṣẹ́ náà yóò fi dúró nígbà tí mo bá ṣíwọ́ kúrò lẹ́nu rẹ̀, tí mo sì sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín?”+  Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n fi ọ̀rọ̀ kan náà ránṣẹ́ sí mi ní ìgbà mẹ́rin, mo sì ń fi ọ̀rọ̀ kan náà fún wọn lésì.  Níkẹyìn, Sáńbálátì+ fi ọ̀rọ̀ kan náà rán ẹmẹ̀wà rẹ̀ sí mi ní ìgbà karùn-ún, pẹ̀lú lẹ́tà tí a kò lẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀.  A kọ ọ́ sínu rẹ̀ pé: “A ti gbọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, Géṣémù+ sì ń sọ ọ́ pé, ìwọ àti àwọn Júù ń pète-pèrò láti ṣọ̀tẹ̀.+ Ìdí nìyẹn tí o fi ń mọ ògiri náà; ìwọ a sì di ọba fún wọn,+ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.  Àní àwọn wòlíì sì wà tí o ti yàn sípò láti ké jáde nípa rẹ jákèjádò Jerúsálẹ́mù pé, ‘Ọba wà ní Júdà!’ Wàyí o, ohun bí ìwọ̀nyí ni a ó sọ fún ọba. Ǹjẹ́ wá nísinsìnyí, jẹ́ kí a jọ fikùnlukùn.”+  Bí ó ti wù kí ó rí, mo ránṣẹ́ sí i pé: “Irú ohun tí o ń sọ kò ṣẹlẹ̀,+ ṣùgbọ́n láti inú ọkàn-àyà ìwọ fúnra rẹ ni o ti ń hùmọ̀ wọn.”+  Nítorí gbogbo wọn ń gbìyànjú láti mú wa fòyà, wọ́n ń wí pé: “Ọwọ́+ wọn yóò rọ jọwọrọ kúrò lẹ́nu iṣẹ́ náà tí ó fi jẹ́ pé a kì yóò ṣe é.” Ṣùgbọ́n, nísinsìnyí, fún ọwọ́+ mi lókun. 10  Èmi alára sì wọ ilé Ṣemáyà ọmọkùnrin Deláyà ọmọkùnrin Méhétábélì nígbà tí a sé e mọ́.+ Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Jẹ́ kí a jọ pàdé nípasẹ̀ àdéhùn+ ní ilé Ọlọ́run tòótọ́, láàárín tẹ́ńpìlì,+ sì jẹ́ kí a ti àwọn ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì; nítorí wọ́n ń wọlé bọ̀ láti wá pa ọ́, àní ní òru,+ wọ́n ń wọlé bọ̀ láti wá pa ọ́.” 11  Ṣùgbọ́n mo wí pé: “Ó ha yẹ kí ènìyàn bí èmi fẹsẹ̀ fẹ bí?+ Ta ni ó sì wà tí ó dà bí èmi tí ó lè wọnú tẹ́ńpìlì, kí ó sì wà láàyè?+ Èmi kì yóò wọ̀ ọ́!” 12  Nítorí náà, mo ṣe àyẹ̀wò, sì kíyè sí i, kì í ṣe Ọlọ́run+ ni ó rán an, ṣùgbọ́n, ó sọ+ àsọtẹ́lẹ̀ yìí lòdì sí mi gẹ́gẹ́ bí Tobáyà àti Sáńbálátì+ fúnra wọn ti háyà rẹ̀.+ 13  Fún ìdí yìí ni a fi háyà rẹ̀,+ kí n bàa lè fòyà,+ kí n sì ṣe bẹ́ẹ̀, kí n sì ṣẹ̀+ ní tòótọ́, yóò sì di òkìkí búburú+ lọ́dọ̀ wọn dájúdájú, kí wọ́n lè gàn mí.+ 14  Ọlọ́run mi, rántí+ Tobáyà+ àti Sáńbálátì, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn wọ̀nyí àti Noadáyà wòlíì obìnrin+ àti ìyókù àwọn wòlíì tí ń bá a lọ ní gbígbìyànjú láti mú mi fòyà. 15  Nígbà tí ó ṣe, ògiri+ náà parí ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n Élúlì, ní ọjọ́ méjì-lé-láàádọ́ta. 16  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí gbogbo ọ̀tá+ wa gbọ́ nípa rẹ̀, tí gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká sì rí i, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ojú wọn rẹ̀wẹ̀sì púpọ̀, wọ́n sì wá mọ̀ pé láti ọwọ́ Ọlọ́run+ wa ni a ti ṣe iṣẹ́ yìí. 17  Ní ọjọ́ wọnnì pẹ̀lú, àwọn ọ̀tọ̀kùlú+ Júdà mú lẹ́tà wọn tí ń lọ sọ́dọ̀ Tobáyà+ pọ̀ níye, àti àwọn ti Tobáyà tí ń wọlé wá sọ́dọ̀ wọn. 18  Nítorí ọ̀pọ̀ ní Júdà búra fún un, nítorí ọkọ ọmọ ni ó jẹ́ fún Ṣẹkanáyà ọmọkùnrin Áráhì;+ Jèhóhánánì ọmọkùnrin rẹ̀ alára sì fẹ́ ọmọbìnrin Méṣúlámù+ ọmọkùnrin Berekáyà. 19  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ohun rere nípa rẹ̀ ni wọ́n ń sọ níwájú mi nígbà gbogbo.+ Àwọn ọ̀rọ̀ mi ni wọ́n sì ń mú lọ fún un nígbà gbogbo. Àwọn lẹ́tà wà tí Tobáyà fi ránṣẹ́ láti mú mi fòyà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé