Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Nehemáyà 4:1-23

4  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Sáńbálátì+ gbọ́ pé a ń tún ògiri náà mọ, ó bínú,+ ó sì fara ya gidigidi, ó sì ń fi àwọn Júù ṣẹ̀sín+ ṣáá.  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ níwájú àwọn arákùnrin+ rẹ̀ àti ẹgbẹ́ ológun Samáríà, bẹ́ẹ̀ ni, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Kí ni àwọn Júù ahẹrẹpẹ ń ṣe? Wọn yóò ha gbára lé ara wọn bí? Wọn yóò ha rúbọ bí?+ Wọn yóò ha parí rẹ̀ ní ọjọ́ kan ṣoṣo bí? Wọn yóò ha mú àwọn òkúta sọ jí láti inú òkìtì pàǹtí+ nígbà tí a bá sun wọ́n?”  Wàyí o, Tobáyà+ ọmọ Ámónì+ wà ní ẹ̀bá ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì ń bá a lọ láti wí pé: “Àní ohun tí wọ́n ń mọ, bí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀+ bá gùn ún, dájúdájú, yóò wó ògiri òkúta wọn lulẹ̀.”  Gbọ́,+ ìwọ Ọlọ́run wa, nítorí a ti di ẹni ìfojú-tín-ín-rín;+ dá ẹ̀gàn+ wọn padà sórí wọn, kí o sì fi wọn fún ìpiyẹ́ ní ilẹ̀ oko òǹdè.  Kí o má sì bo ìṣìnà+ wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò níwájú rẹ. Má ṣe jẹ́ kí a nù ún kúrò, nítorí wọ́n ti ṣe ohun ìmúnibínú sí àwọn tí ń mọ ògiri náà.  Nítorí náà, a ń mọ ògiri náà nìṣó, gbogbo ògiri náà pátá ni a sì mọ pọ̀ mọ́ra títí lọ dé ìdajì gíga rẹ̀, àwọn ènìyàn sì ń bá a lọ láti ní ọkàn-àyà fún iṣẹ́ ṣíṣe.+  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Sáńbálátì+ àti Tobáyà+ àti àwọn ọmọ ilẹ̀ Arébíà+ àti àwọn ọmọ Ámónì+ àti àwọn ará Áṣídódì+ gbọ́ pé títún ògiri Jerúsálẹ́mù ṣe ti tẹ̀ síwájú, nítorí a ti bẹ̀rẹ̀ sí dí àwọn àlàfo náà, wọ́n bínú gidigidi.  Gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun+ pa pọ̀ láti wá bá Jerúsálẹ́mù jà, kí wọ́n sì fa ìyọlẹ́nu fún mi.  Ṣùgbọ́n a gbàdúrà+ sí Ọlọ́run wá, a sì yan ẹ̀ṣọ́ tì wọ́n tọ̀sán-tòru ní tìtorí wọn. 10  Júdà sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Agbára arẹrù+ ti kọsẹ̀, pàǹtí+ púpọ̀ gan-an sì wà; àwa fúnra wa kò sì lè mọ sórí ògiri náà.” 11  Síwájú sí i, àwọn elénìní wa ń wí pé: “Wọn kì yóò mọ̀,+ wọn kì yóò sì rí i títí a ó fi dé àárín wọn gan-an, dájúdájú, àwa yóò sì pa wọ́n, a ó sì fi òpin sí iṣẹ́ náà.” 12  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbàkigbà tí àwọn Júù tí ń gbé nítòsí wọn bá wọlé, wọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí wí fún wa ní ìgbà mẹ́wàá pé: “[Wọn yóò wá] láti ibi gbogbo tí ẹ̀yin yóò ti padà tọ̀ wá wá.” 13  Nítorí náà, mo yan àwọn ènìyàn dúró sí apá ìsàlẹ̀ pátápátá níbi tí ó wà lẹ́yìn ògiri níbi gbayawu náà, mo sì yan àwọn ènìyàn náà sí ìdúró nípa ìdílé wọn, ti àwọn ti idà+ wọn, aṣóró+ wọn àti ọrun wọn. 14  Nígbà tí mo rí ìbẹ̀rù wọn, mo dìde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, mo sì wí fún àwọn ọ̀tọ̀kùlú+ àti àwọn ajẹ́lẹ̀+ àti ìyókù àwọn ènìyàn náà pé: “Ẹ má fòyà+ ní tìtorí wọn. Jèhófà Ẹni ńlá+ tí ń múni kún fún ẹ̀rù+ ni kí ẹ fi sọ́kàn yín; kí ẹ sì jà fún àwọn arákùnrin+ yín, àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín, àwọn aya yín àti ilé yín.” 15  Wàyi o, ó ṣẹlẹ̀ pé gbàrà tí àwọn ọ̀tá wa ti gbọ́ pé o ti di mímọ̀ fún wa, tí Ọlọ́run tòótọ́ sì ti mú ète+ wọn já sí pàbó, tí gbogbo wa sì ti padà lọ síbi ògiri náà, olúkúlùkù síbi iṣẹ́ rẹ̀, 16  bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣẹlẹ̀ pé láti ọjọ́ yẹn lọ, ìdajì àwọn ọ̀dọ́kùnrin+ mi jẹ́ aláápọn lẹ́nu iṣẹ́ náà, ìdajì wọn sì di aṣóró, apata àti ọrun àti ẹ̀wù tí a fi àdàrọ irin ṣe+ mú; àwọn ọmọ aládé+ sì wà lẹ́yìn gbogbo ilé Júdà. 17  Ní ti àwọn tí ń mọ ògiri, tí wọ́n wà lórí ògiri àti àwọn tí ń ru ẹrù ìnira ti àwọn arẹrù, olúkúlùkù ni ọwọ́ rẹ̀ kan dí fún iṣẹ́ nígbà tí ọwọ́+ kejì di ohun ọṣẹ́+ mú. 18  Àwọn tí ń mọ ògiri náà di àmùrè, olúkúlùkù pẹ̀lú idà rẹ̀ ní ìgbáròkó+ rẹ̀, bí ó ti ń mọlé;+ ẹni tí yóò fun ìwo+ sì wà lẹ́bàá ọ̀dọ̀ mi. 19  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn ọ̀tọ̀kùlú àti àwọn ajẹ́lẹ̀+ àti ìyókù àwọn ènìyàn náà pé: “Iṣẹ́ náà pọ̀, ó sì gbòòrò, a sì wà lórí ògiri náà káàkiri ní jíjìnnà síra lẹ́nì kìíní-kejì. 20  Ní ibi tí ẹ bá ti gbọ́ ìró ìwo, ibẹ̀ ni kí ẹ kó ara yín jọpọ̀ sí lọ́dọ̀ wa. Ọlọ́run wa fúnra rẹ̀ yóò jà fún wa.”+ 21  Bí ọwọ́ wa ti dí fún iṣẹ́, ìdajì yòókù nínú wọn di aṣóró mú, láti ìgbà tí ọ̀yẹ̀ ti là títí di ìgbà tí ìràwọ̀ yọ. 22  Yàtọ̀ sí èyí, ní àkókò yẹn, mo wí fún àwọn ènìyàn náà pé: “Kí àwọn ọkùnrin, olúkúlùkù pẹ̀lú ẹmẹ̀wà rẹ̀, wà ní àárín Jerúsálẹ́mù+ mọ́jú, kí wọ́n sì di ẹ̀ṣọ́ wa ní òru àti òṣìṣẹ́ ní ọ̀sán.” 23  Ní ti èmi+ àti àwọn arákùnrin+ mi àti àwọn ẹmẹ̀wà+ mi àti àwọn ẹ̀ṣọ́+ tí wọ́n wà lẹ́yìn mi, a kì í bọ́ ẹ̀wù wa, olúkúlùkù ní ohun ọṣẹ́+ rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé