Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Nehemáyà 3:1-32

3  Élíáṣíbù+ àlùfáà àgbà àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn àlùfáà, sì bẹ̀rẹ̀ sí dìde, wọ́n sì kọ́ Ẹnubodè Àgùntàn.+ Àwọn fúnra wọn sọ ọ́ di mímọ́,+ wọ́n sì gbé àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ nà ró; títí dé Ilé Gogoro Méà+ ni wọ́n sọ ọ́ di mímọ́, títí dé Ilé Gogoro Hánánélì.+  Lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn sì ni àwọn ọkùnrin Jẹ́ríkò+ ti mọlé. Lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn sì ni Sákúrì ọmọkùnrin Ímúrì ti mọlé.  Ẹnubodè Ẹja+ sì ni àwọn ọmọ Hásénà mọ; àwọn fúnra wọn fi ẹ̀là gẹdú+ kọ́ ọ, lẹ́yìn náà, wọ́n gbé àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ nà ró,+ àwọn ọ̀pẹẹrẹ rẹ̀ àti àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀.+  Lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn sì ni Mérémótì+ ọmọkùnrin Úríjà+ ọmọkùnrin Hákósì ti ṣe iṣẹ́ àtúnṣe, lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn sì ni Méṣúlámù+ ọmọkùnrin Berekáyà ọmọkùnrin Meṣesábélì ti ṣe iṣẹ́ àtúnṣe; lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn sì ni Sádókù ọmọkùnrin Báánà ti ṣe iṣẹ́ àtúnṣe.  Lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn sì ni àwọn ará Tékóà+ ti ṣe iṣẹ́ àtúnṣe; ṣùgbọ́n àwọn tí ó jẹ́ ọlọ́lá ọba+ nínú wọn pàápàá kò tẹ ẹ̀yìn ọrùn wọn ba láti ṣe iṣẹ́ ìsìn ọ̀gá wọn.  Ẹnubodè Ìlú Ńlá+ Àtijọ́ sì ni Jóyádà ọmọkùnrin Páséà àti Méṣúlámù ọmọkùnrin Besodeáyà tún ṣe; àwọn fúnra wọn fi ẹ̀là gẹdú kọ́ ọ, lẹ́yìn náà, wọ́n sì gbé àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ nà ró àti àwọn ọ̀pẹẹrẹ rẹ̀ àti àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀.+  Lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn sì ni Melatáyà ará Gíbéónì+ àti Jádónì ará Mérónótì+ ti ṣe iṣẹ́ àtúnṣe, àwọn ọkùnrin Gíbéónì+ àti ti Mísípà,+ tí wọ́n jẹ́ ti ìtẹ́ gómìnà+ ní ìkọjá Odò.+  Lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ sì ni Úsíélì ọmọkùnrin Háháyà, àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà,+ ti ṣe iṣẹ́ àtúnṣe; lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ sì ni Hananáyà tí í ṣe mẹ́ńbà àwọn olùpo òróró ìkunra,+ ti ṣe iṣẹ́ àtúnṣe; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi òkúta palaba-palaba tẹ́ Jerúsálẹ́mù títí dé Ògiri Fífẹ̀.+  Lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn sì ni Refáyà ọmọkùnrin Húrì, ọmọ aládé ìdajì àgbègbè Jerúsálẹ́mù, ti ṣe iṣẹ́ àtúnṣe. 10  Lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn sì ni Jedáyà ọmọkùnrin Hárúmáfù, ti ṣe iṣẹ́ àtúnṣe ní iwájú ilé òun fúnra rẹ̀;+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ sì ni Hátúṣì ọmọkùnrin Haṣabanéáyà ti ṣe iṣẹ́ àtúnṣe. 11  Ẹ̀ka mìíràn tí a díwọ̀n ni Málíkíjà ọmọkùnrin Hárímù+ àti Háṣúbù ọmọkùnrin Pahati-móábù+ tún ṣe, àti Ilé Gogoro Àwọn Ààrò Ìyan-nǹkan.+ 12  Lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ sì ni Ṣálúmù ọmọkùnrin Hálóhéṣì, ọmọ aládé+ ìdajì àgbègbè Jerúsálẹ́mù, ti ṣe iṣẹ́ àtúnṣe, òun àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀. 13  Ẹnubodè Àfonífojì+ ni Hánúnì àti àwọn olùgbé Sánóà+ tún ṣe; àwọn fúnra wọn kọ́ ọ, lẹ́yìn náà, wọ́n gbé ilẹ̀kùn rẹ̀+ nà ró, àwọn ọ̀pẹẹrẹ rẹ̀+ àti àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀,+ àti ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ ògiri títí dé Ẹnubodè Àwọn Òkìtì-eérú.+ 14  Ẹnubodè Àwọn Òkìtì-eérú sì ni Málíkíjà ọmọkùnrin Rékábù, ọmọ aládé àgbègbè Bẹti-hákérémù+ tún ṣe; òun fúnra rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ọ, ó sì gbé àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ nà ró, àwọn ọ̀pẹẹrẹ rẹ̀ àti àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀. 15  Ẹnubodè Ojúsun+ sì ni ohun tí Ṣálúnì ọmọkùnrin Kólíhósè, ọmọ aládé àgbègbè Mísípà,+ tún ṣe; òun fúnra rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ọ, ó sì fi òrùlé bò ó, ó sì gbé àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ nà ró,+ àwọn ọ̀pẹẹrẹ rẹ̀ àti àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, àti ògiri Odò Adágún+ ti Ipa Odò tí ó lọ sí Ọgbà Ọba+ àti títí dé Àtẹ̀gùn+ tí ó sọ̀ kalẹ̀ láti Ìlú Ńlá Dáfídì.+ 16  Lẹ́yìn rẹ̀ ni Nehemáyà ọmọkùnrin Ásíbúkì, ọmọ aládé ìdajì àgbègbè Bẹti-súrì,+ ṣe iṣẹ́ àtúnṣe títí dé iwájú Àwọn Ibi Ìsìnkú+ ti Dáfídì àti títí dé odò adágún+ tí a ti ṣe àti títí dé Ilé Àwọn Alágbára Ńlá.+ 17  Lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn ọmọ Léfì+ ṣe iṣẹ́ àtúnṣe, Réhúmù ọmọkùnrin Bánì;+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ sì ni Haṣabáyà, ọmọ aládé ìdajì àgbègbè Kéílà+ ti ṣe iṣẹ́ àtúnṣe fún àgbègbè rẹ̀. 18  Lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn arákùnrin wọn ṣe iṣẹ́ àtúnṣe, Báfáì ọmọkùnrin Hénádádì, ọmọ aládé ìdajì àgbègbè Kéílà. 19  Ésérì ọmọkùnrin Jéṣúà,+ ọmọ aládé Mísípà,+ sì bẹ̀rẹ̀ sí tún ẹ̀ka mìíràn tí a díwọ̀n ṣe lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ní iwájú ìgòkè lọ sí Ilé Ìhámọ́ra, ní ibi Ìtì Ògiri.+ 20  Lẹ́yìn rẹ̀ ni Bárúkù ọmọkùnrin Sábáì+ fi tẹ̀mí-tẹ̀mí ṣiṣẹ́,+ tí ó sì tún ẹ̀ka mìíràn tí a díwọ̀n ṣe, láti Ìtì Ògiri títí dé ẹnu ọ̀nà ilé Élíáṣíbù+ àlùfáà àgbà. 21  Lẹ́yìn rẹ̀ ni Mérémótì ọmọkùnrin Úríjà+ ọmọkùnrin Hákósì tún ẹ̀ka mìíràn tí a díwọ̀n ṣe, láti ẹnu ọ̀nà ilé Élíáṣíbù títí dé òpin ilé Élíáṣíbù. 22  Lẹ́yìn rẹ̀ sì ni àwọn àlùfáà, àwọn ọkùnrin Àgbègbè Jọ́dánì,+ ṣe iṣẹ́ àtúnṣe. 23  Lẹ́yìn wọn ni Bẹ́ńjámínì àti Háṣúbù ṣe iṣẹ́ àtúnṣe ní iwájú ilé tiwọn fúnra wọn. Lẹ́yìn wọn ni Asaráyà ọmọkùnrin Maaseáyà ọmọkùnrin Ananáyà ṣe iṣẹ́ àtúnṣe nítòsí ilé òun fúnra rẹ̀. 24  Lẹ́yìn rẹ̀ ni Bínúì ọmọkùnrin Hénádádì tún ẹ̀ka mìíràn tí a díwọ̀n ṣe, láti ilé Asaráyà títí dé Ìtì Ògiri+ àti títí dé igun odi. 25  [Lẹ́yìn rẹ̀] ni Pálálì ọmọkùnrin Úṣáì [ṣe iṣẹ́ àtúnṣe] ní iwájú Ìtì Ògiri àti ilé gogoro tí ó yọ jáde láti inú Ilé Ọba,+ ti apá òkè tí ó jẹ́ ti Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́.+ Lẹ́yìn rẹ̀ ni Pedáyà ọmọkùnrin Páróṣì+ wà. 26  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé àwọn Nétínímù+ fúnra wọn jẹ́ olùgbé Ófélì;+ wọ́n ṣe iṣẹ́ àtúnṣe títí dé iwájú Ẹnubodè Omi+ ní ìlà-oòrùn àti ilé gogoro tí ó yọ jáde. 27  Lẹ́yìn wọn ni àwọn ará Tékóà+ tún ẹ̀ka mìíràn tí a díwọ̀n ṣe, láti iwájú ilé gogoro ńlá tí ó yọ jáde títí dé ògiri Ófélì. 28  Lórí Ẹnubodè Ẹṣin+ ni àwọn àlùfáà ti ṣe iṣẹ́ àtúnṣe, olúkúlùkù ní iwájú ilé òun fúnra rẹ̀. 29  Lẹ́yìn wọn ni Sádókù+ ọmọkùnrin Ímérì ṣe iṣẹ́ àtúnṣe ní iwájú ilé òun fúnra rẹ̀. Lẹ́yìn rẹ̀ sì ni Ṣemáyà ọmọkùnrin Ṣẹkanáyà, olùṣọ́ Ẹnubodè Ìlà-Oòrùn,+ ṣe iṣẹ́ àtúnṣe. 30  Lẹ́yìn rẹ̀ ni Hananáyà ọmọkùnrin Ṣelemáyà àti Hánúnì ọmọkùnrin kẹfà ti Sáláfù tún ẹ̀ka mìíràn tí a díwọ̀n ṣe. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Méṣúlámù+ ọmọkùnrin Berekáyà ṣe iṣẹ́ àtúnṣe ní iwájú gbọ̀ngàn+ òun fúnra rẹ̀. 31  Lẹ́yìn rẹ̀ ni Málíkíjà, tí í ṣe mẹ́ńbà ẹgbẹ́ alágbẹ̀dẹ wúrà,+ ṣe iṣẹ́ àtúnṣe títí dé ilé Nétínímù+ àti àwọn oníṣòwò,+ ní iwájú Ẹnubodè Àbẹ̀wò àti títí dé ìyẹ̀wù òrùlé igun odi. 32  Àti láàárín ìyẹ̀wù òrùlé igun odi àti Ẹnubodè Àgùntàn+ ni àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà àti àwọn oníṣòwò ti ṣe iṣẹ́ àtúnṣe.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé