Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Nehemáyà 2:1-20

2  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní oṣù Nísàn,+ ní ọdún ogún+ Atasásítà+ Ọba, pé wáìnì wà níwájú rẹ̀, èmi, gẹ́gẹ́ bí ti àtẹ̀yìnwá, sì gbé wáìnì, mo sì fi í fún ọba.+ Ṣùgbọ́n kò ṣẹlẹ̀ rí pé ojú mi dá gùdẹ̀+ níwájú rẹ̀.  Nítorí náà, ọba wí fún mi pé: “Èé ṣe tí ojú rẹ fi dá gùdẹ̀+ nígbà tí ìwọ fúnra rẹ kò ṣàìsàn? Èyí kì í ṣe ohunkóhun bí kò ṣe ìdágùdẹ̀ ọkàn-àyà.”+ Látàrí èyí, àyà fò mí gidigidi.  Nígbà náà ni mo wí fún ọba pé: “Kí ọba kí ó pẹ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin!+ Èé ṣe tí ojú mi kò fi ní dá gùdẹ̀ nígbà tí ìlú ńlá+ náà, ilé àwọn ibi ìsìnkú àwọn baba ńlá+ mi pa run di ahoro, tí a sì ti fi iná jẹ àwọn ẹnubodè rẹ̀ pàápàá run?”+  Ẹ̀wẹ̀, ọba wí fún mi pé: “Kí ni ohun náà tí ìwọ ń wá?”+ Lójú-ẹsẹ̀, mo gbàdúrà+ sí Ọlọ́run ọ̀run.+  Lẹ́yìn ìyẹn, mo wí fún ọba pé: “Bí ó bá dára lójú ọba,+ bí ó bá sì jọ pé ìránṣẹ́ rẹ dára níwájú rẹ,+ kí o rán mi lọ sí Júdà, sí ìlú ńlá àwọn ibi ìsìnkú àwọn baba ńlá mi, kí n lè tún un kọ́.”+  Látàrí èyí, ọba wí fún mi, bí olorì rẹ̀ ti jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, pé: “Ìrìn àjò rẹ yóò ti pẹ́ tó, ìgbà wo sì ni ìwọ yóò padà?” Nítorí náà, ó dára+ lójú ọba pé kí ó rán mi, nígbà tí mo fún un ní àkókò tí a yàn kalẹ̀.+  Mo sì ń bá a lọ láti wí fún ọba pé: “Bí ó bá dára lójú ọba, kí a fún mi ní àwọn lẹ́tà+ sí àwọn gómìnà+ ní ìkọjá Odò,+ kí wọ́n lè jẹ́ kí ń kọjá títí èmi yóò fi dé Júdà;  pẹ̀lúpẹ̀lù, lẹ́tà kan sí Ásáfù olùṣọ́ ọgbà ọba, kí ó lè fún mi ní igi láti fi ẹ̀là gẹdú kọ́ àwọn ẹnubodè Ilé Aláruru+ tí ó jẹ́ ti ilé náà,+ àti fún ògiri+ ìlú ńlá náà àti fún ilé tí èmi yóò wọ̀.” Nítorí náà, ọba fí wọ́n fún mi, gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ rere Ọlọ́run mi lára mi.+  Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, mo dé ọ̀dọ̀ àwọn gómìnà+ ní ìkọjá Odò, mo sì fún wọn ní àwọn lẹ́tà ọba. Síwájú sí i, ọba rán àwọn olórí ẹgbẹ́ ológun àti àwọn ẹlẹ́ṣin pẹ̀lú mi. 10  Nígbà tí Sáńbálátì+ tí í ṣe Hórónì+ àti Tobáyà+ ìránṣẹ́, tí í ṣe ọmọ Ámónì,+ gbọ́ nípa rẹ̀, nígbà náà, ó dà bí ohun tí ó burú+ lójú wọn pé ọkùnrin kan wá láti wá ohun rere fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 11  Nígbà tí ó ṣe, mo dé Jerúsálẹ́mù, mo sì wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta. 12  Nígbà náà ni mo dìde ní òru, èmi àti àwọn ọkùnrin díẹ̀ pẹ̀lú mi, èmi kò sì sọ fún ènìyàn+ kankan nípa ohun tí Ọlọ́run mi ń fi sínú ọkàn-àyà mi láti ṣe fún Jerúsálẹ́mù,+ kò sì sí ẹran agbéléjẹ̀ kankan pẹ̀lú mi bí kò ṣe ẹran agbéléjẹ̀ tí mo ń gùn. 13  Mo sì gba Ẹnubodè Àfonífojì+ jáde ní òru àti ní iwájú Ojúsun Ejò Ńlá àti sí Ẹnubodè Àwọn Òkìtì-eérú,+ lemọ́lemọ́ ni mo sì ń yẹ ògiri+ Jerúsálẹ́mù wò, bí wọ́n ti wó lulẹ̀, iná sì ti jẹ àwọn ẹnubodè+ rẹ̀ run. 14  Mo sì kọjá lọ sí Ẹnubodè Ojúsun+ àti sí Odò Adágún Ọba, kò sì sí àyè kankan fún ẹran agbéléjẹ̀ tí ó wà lábẹ́ mi láti kọjá. 15  Ṣùgbọ́n mo ń bá a nìṣó láti gòkè lọ ní ojú ọ̀gbàrá+ àfonífojì ní òru, mo sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣàyẹ̀wò ògiri náà; lẹ́yìn èyí ni mo padà, mo sì gba Ẹnubodè Àfonífojì+ wọlé, bẹ́ẹ̀ ni mo sì padà. 16  Àwọn ajẹ́lẹ̀+ fúnra wọn kò sì mọ ibi tí mo lọ àti ohun tí mo ń ṣe; èmi kò sì tíì sọ ohunkóhun fún àwọn Júù àti àwọn àlùfáà àti àwọn ọ̀tọ̀kùlú àti àwọn ajẹ́lẹ̀ àti ìyókù àwọn olùṣe iṣẹ́ náà. 17  Níkẹyìn, mo wí fún wọn pé: “Ẹ rí ipò ìṣòro búburú tí a wà nínú rẹ̀, bí a ti pa Jerúsálẹ́mù run di ahoro, tí a sì fi iná sun àwọn ẹnubodè rẹ̀. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tún ògiri Jerúsálẹ́mù mọ, kí a má bàa jẹ́ ẹni ẹ̀gàn+ mọ́.” 18  Mo sí ń bá a lọ láti sọ fún wọn nípa ọwọ́+ Ọlọ́run mi, bí ó ti dára lára mi,+ àti nípa ọ̀rọ̀+ ọba tí ó sọ fún mi. Látàrí èyí, wọ́n wí pé: “Ẹ jẹ́ kí a dìde, kí a sì kọ́lé.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fún ọwọ́ wọn lókun fún iṣẹ́ rere náà.+ 19  Wàyí o, nígbà tí Sáńbálátì+ tí í ṣe Hórónì àti Tobáyà+ ìránṣẹ́,+ tí í ṣe ọmọ Ámónì,+ àti Géṣémù+ ọmọ ilẹ̀ Arébíà+ gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi wa ṣẹ̀sín,+ wọ́n sì ń fojú tẹ́ńbẹ́lú wa pé: “Kí ni ohun tí ẹ ń ṣe yìí? Ṣé ọba ni ẹ̀yin ń ṣọ̀tẹ̀ sí?”+ 20  Bí ó ti wù kí ó rí, mo fún wọn lésì, mo sì wí fún wọn pé: “Ọlọ́run ọ̀run+ ni Ẹni tí yóò yọ̀ǹda àṣeyọrí sí rere fún wa,+ àti pé àwa fúnra wa, tí a jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, yóò dìde, a ó sì kọ́lé; ṣùgbọ́n ẹ̀yin fúnra yín kò ní ìpín kankan,+ tàbí ẹ̀tọ́ tí ó bá ìdájọ́ òdodo mu, tàbí ìrántí+ ní Jerúsálẹ́mù.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé