Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Nehemáyà 13:1-31

13  Ní ọjọ́ yẹn, kíka+ ìwé+ Mósè sí etí àwọn ènìyàn wáyé; a sì rí i tí a kọ ọ́ sínú rẹ̀ pé àwọn ọmọ Ámónì+ àti ọmọ Móábù+ kò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Ọlọ́run tòótọ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin,+  nítorí wọn kò gbé oúnjẹ+ àti omi+ pàdé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n wọ́n háyà Báláámù+ láti pe ibi wá sórí wọn.+ Bí ó ti wù kí ó rí, Ọlọ́run wa yí ìfiré náà padà di ìsúre.+  Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí wọ́n gbọ́ òfin+ náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ya+ àwùjọ onírúurú ènìyàn sọ́tọ̀ kúrò lára Ísírẹ́lì.  Wàyí o, ṣáájú èyí, Élíáṣíbù+ àlùfáà tí ń bójú tó gbọ̀ngàn ìjẹun+ ilé Ọlọ́run wa jẹ́ ìbátan Tobáyà;+  ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gbọ̀ngàn ìjẹun títóbi+ kan fún un, níbi tí wọ́n ti máa ń fi ọrẹ ẹbọ ọkà,+ oje igi tùràrí àti àwọn nǹkan èlò àti ìdá mẹ́wàá ọkà, wáìnì tuntun+ àti òróró+ sí tẹ́lẹ̀ rí lọ́nà tí ó ṣe déédéé, èyí tí àwọn ọmọ Léfì+ àti àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́bodè lẹ́tọ̀ọ́ sí, àti ọrẹ fún àwọn àlùfáà.  Ní gbogbo àkókò yìí, èmi kò sì sí ní Jerúsálẹ́mù, nítorí ní ọdún kejìlélọ́gbọ̀n+ Atasásítà+ ọba Bábílónì, mo wá sọ́dọ̀ ọba, ní àkókò kan lẹ́yìn náà, mo béèrè ìyọ̀ǹda ìsinmi kúrò lẹ́nu iṣẹ́ lọ́dọ̀ ọba.+  Lẹ́yìn náà, mo wá sí Jerúsálẹ́mù, mo sì kíyè sí ìwà búburú tí Élíáṣíbù+ hù nítorí Tobáyà+ nípa ṣíṣe gbọ̀ngàn kan fún un ní àgbàlá ilé+ Ọlọ́run tòótọ́.  Ó sì burú gan-an lójú mi.+ Nítorí náà, mo da+ gbogbo ohun èlò ilé Tobáyà sóde gbọ̀ngàn ìjẹun.  Lẹ́yìn ìyẹn, mo sọ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n sì fọ+ àwọn gbọ̀ngàn ìjẹun+ náà mọ́; mo sì bẹ̀rẹ̀ sí dá àwọn nǹkan èlò+ ilé Ọlọ́run tòótọ́ padà, pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ ọkà àti oje igi tùràrí.+ 10  Mo sì wá rí i pé a kò fi ìpín+ àwọn ọmọ Léfì fún wọn, tí ó fi jẹ́ pé àwọn ọmọ Léfì àti àwọn akọrin tí ń ṣe iṣẹ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ, olúkúlùkù sí pápá rẹ̀.+ 11  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí rí àléébù+ lára àwọn ajẹ́lẹ̀,+ mo sì wí pé: “Èé ṣe tí a fi ṣàìnáání ilé Ọlọ́run tòótọ́?”+ Nítorí náà, mo kó wọn jọpọ̀, mo sì yàn wọ́n sí ibi ìdúró wọn. 12  Gbogbo Júdà, ní tiwọn, sì mú ìdá mẹ́wàá+ ọkà+ àti ti wáìnì tuntun+ àti ti òróró+ wá sí àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ sí.+ 13  Lẹ́yìn náà, mo fi Ṣelemáyà àlùfáà àti Sádókù adàwékọ àti Pedáyà lára àwọn ọmọ Léfì sí àbójútó àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ sí náà; lábẹ́ àkóso wọn sì ni Hánánì ọmọkùnrin Sákúrì ọmọkùnrin Matanáyà+ wà, nítorí a kà wọ́n sí olùṣòtítọ́;+ ó sì já lé wọn léjìká láti há+ nǹkan fún àwọn arákùnrin wọn. 14  Ọlọ́run mi, rántí mi+ nípa èyí, má sì nu+ ìṣe inú rere mi onífẹ̀ẹ́ kúrò, èyí tí mo ti ṣe nípa ilé+ Ọlọ́run mi àti iṣẹ́ ìṣètọ́jú rẹ̀. 15  Ní ọjọ́ wọnnì, ní Júdà,mo rí àwọn ènìyàn tí ń tẹ ìfúntí wáìnì ní sábáàtì,+ tí wọ́n sì ń mú òkìtì ọkà wá, tí wọ́n sì ń dì+ wọ́n lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,+ àti pẹ̀lú wáìnì, èso àjàrà àti ọ̀pọ̀tọ́+ àti gbogbo onírúurú ẹrù ìnira, wọ́n sì kó wọn wá sí Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ sábáàtì;+ mo sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ́rìí lòdì sí wọn ní ọjọ́ tí wọ́n ń ta ìpèsè oúnjẹ. 16  Àwọn ará Tírè+ sì ń gbé ní ìlú ńlá náà, wọ́n ń kó ẹja wá àti gbogbo onírúurú ọjà títà,+ wọ́n sì ń tajà ní sábáàtì fún àwọn ọmọ Júdà àti ní Jerúsálẹ́mù. 17  Bẹ́ẹ̀ ni mo bẹ̀rẹ̀ sí rí àléébù lára àwọn ọ̀tọ̀kùlú+ Júdà, mo sì wí fún wọn pé: “Ohun búburú wo ni ẹ ń ṣe yìí, ẹ tilẹ̀ ń sọ ọjọ́ sábáàtì di aláìmọ́? 18  Báyìí ha kọ́ ni àwọn baba ńlá yín ṣe,+ tí Ọlọ́run wa fi mú gbogbo ìyọnu àjálù+ yìí wá sórí wa, àti sórí ìlú ńlá yìí pẹ̀lú? Síbẹ̀ ẹ̀yin ń fi kún ìbínú jíjó fòfò sí Ísírẹ́lì nípa sísọ sábáàtì di aláìmọ́.”+ 19  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ẹnubodè Jerúsálẹ́mù yọ òjìji ṣáájú sábáàtì, mo sọ ọ̀rọ̀ náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, a sì bẹ̀rẹ̀ sí ti àwọn ilẹ̀kùn náà.+ Mo wí síwájú sí i pé wọn kò gbọ́dọ̀ ṣí wọn títí di ẹ̀yìn sábáàtì; àwọn kan lára àwọn ẹmẹ̀wà mi ni mo yàn sí àwọn ẹnubodè kí ẹrù kankan má bàa wọlé ní ọjọ́ sábáàtì.+ 20  Nítorí náà, àwọn oníṣòwò àti àwọn olùtà gbogbo onírúurú ọjà sùn mọ́jú lóde Jerúsálẹ́mù lẹ́ẹ̀kan àti lẹ́ẹ̀kejì. 21  Lẹ́yìn náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí jẹ́rìí+ lòdì sí wọn, mo sì wí fún wọn pé: “Èé ṣe tí ẹ fi sùn mọ́jú ní iwájú ògiri? Bí ẹ bá ṣe é lẹ́ẹ̀kan sí i, èmi yóò gbé ọwọ́ mi lé yín.”+ Láti ìgbà náà lọ, wọn kò wá ní sábáàtì mọ́. 22  Mo sì ń bá a lọ láti wí fún àwọn ọmọ Léfì+ pé kí wọ́n máa wẹ ara wọn mọ́ gaara+ déédéé, kí wọ́n máa wọlé, ní ṣíṣọ́ àwọn ẹnubodè+ láti sọ ọjọ́ sábáàtì di mímọ́.+ Rántí+ èyí pẹ̀lú sínú àkọsílẹ̀ mi, Ọlọ́run mi, kí o sì káàánú fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ yanturu inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́.+ 23  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ní ọjọ́ wọnnì, mo rí àwọn Júù tí wọ́n ti fi ibùgbé+ fún àwọn aya tí wọ́n jẹ́ ará Áṣídódì,+ ọmọ Ámónì àti ọmọ Móábù.+ 24  Ní ti àwọn ọmọ wọn, ìdajì ń sọ èdè ará Áṣídódì, kò sì sí ìkankan nínú wọn tí ó mọ bí a ti ń sọ èdè Júù,+ ṣùgbọ́n wọ́n ń sọ̀rọ̀ ní ahọ́n àwọn ènìyàn tí ó yàtọ̀. 25  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí rí àléébù lára wọn, mo sì pe ibi wá sórí wọn,+ mo sì lu àwọn ọkùnrin kan lára wọn,+ mo sì fa irun wọn tu, mo sì mú kí wọ́n fi Ọlọ́run búra+ pé: “Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ fi àwọn ọmọbìnrin yín fún àwọn ọmọkùnrin wọn, ẹ̀yin kò sì gbọ́dọ̀ tẹ́wọ́ gba èyíkéyìí nínú àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín tàbí fún ara yín.+ 26  Nítorí ìwọ̀nyí ha kọ́ ni Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì fi dẹ́ṣẹ̀?+ Kò sì sí ọba tí ó dà bí rẹ̀ láàárín ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè;+ ó jẹ́ ẹni tí Ọlọ́run rẹ̀ nífẹ̀ẹ́,+ tí Ọlọ́run fi sọ ọ́ di ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì. Àní òun ni àwọn aya ilẹ̀ òkèèrè mú dẹ́ṣẹ̀.+ 27  Kì í ha ṣe ohun kan tí kò ṣeé gbọ́ ni fún yín láti hu gbogbo ìwà búburú yìí ní ṣíṣe àìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wa nípa fífi ibùgbé fún àwọn aya ilẹ̀ òkèèrè?”+ 28  Ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin Jóyádà+ ọmọkùnrin Élíáṣíbù+ àlùfáà àgbà sì jẹ́ ọkọ ọmọ Sáńbálátì+ tí í ṣe Hórónì.+ Nítorí náà, mo lé e kúrò lọ́dọ̀ mi.+ 29  Jọ̀wọ́ rántí wọn, Ọlọ́run mi, ní tìtorí bí wọ́n ti sọ iṣẹ́ àlùfáà àti májẹ̀mú+ iṣẹ́ àlùfáà àti ti àwọn ọmọ Léfì+ dẹ̀gbin.+ 30  Mo sì wẹ̀ wọ́n mọ́ gaara+ kúrò nínú ohun gbogbo tí ó jẹ́ ti ilẹ̀ òkèèrè, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí yan iṣẹ́ lé àwọn àlùfáà àti lé àwọn ọmọ Léfì lọ́wọ́, olúkúlùkù nínú iṣẹ́ rẹ̀,+ 31  àní fún ìpèsè igi+ ní àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ àti fún àwọn àkọ́pọ́n èso. Jọ̀wọ́, Ọlọ́run mi, rántí+ mi fún rere.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé