Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Nehemáyà 12:1-47

12  Ìwọ̀nyí sì ni àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n gòkè lọ pẹ̀lú Serubábélì+ ọmọkùnrin Ṣéálítíẹ́lì+ àti Jéṣúà:+ Seráyà, Jeremáyà, Ẹ́sírà,  Amaráyà,+ Málúkù, Hátúṣì,  Ṣẹkanáyà, Réhúmù, Mérémótì,  Ídò, Gínétóì, Ábíjà,  Míjámínì, Maadáyà, Bílígà,  Ṣemáyà,+ àti Jóyáríbù, Jedáyà,+  Sáálù, Ámókì,+ Hilikáyà, Jedáyà.+ Ìwọ̀nyí ni àwọn olórí àwọn àlùfáà àti àwọn arákùnrin wọn ní ọjọ́ Jéṣúà.+  Àwọn ọmọ Léfì sì ni Jéṣúà,+ Bínúì,+ Kádímíélì,+ Ṣerebáyà, Júdà, Matanáyà,+ wọ́n ń ṣàbójútó ìdúpẹ́, òun àti àwọn arákùnrin rẹ̀.  Bakibúkáyà àti Únì, àwọn arákùnrin wọn sì wà ní òdì-kejì wọn fún iṣẹ́ ìṣọ́. 10  Jéṣúà bí Jóyákímù,+ Jóyákímù sì bí Élíáṣíbù,+ Élíáṣíbù sì bí Jóyádà.+ 11  Jóyádà sì bí Jónátánì, Jónátánì sì bí Jádúà.+ 12  Ní ọjọ́ Jóyákímù, àwọn àlùfáà sì wà, àwọn olórí àwọn ìdí ilé+ baba: fún Seráyà,+ Meráyà; fún Jeremáyà, Hananáyà; 13  fún Ẹ́sírà,+ Méṣúlámù; fún Amaráyà, Jèhóhánánì; 14  fún Málúkì, Jónátánì; fún Ṣebanáyà,+ Jósẹ́fù; 15  fún Hárímù,+ Ádúnà; fún Méráótì, Hélíkáì; 16  fún Ídò, Sekaráyà; fún Gínétónì, Méṣúlámù; 17  fún Ábíjà,+ Síkírì; fún Míníámínì,——; fún Moadáyà, Pílítáì; 18  fún Bílígà,+ Ṣámúà; fún Ṣemáyà, Jèhónátánì; 19  àti fún Jóyáríbù, Máténáì; fún Jedáyà,+ Úsáì; 20  fún Sáláì, Káláì; fún Ámókì, Ébérì; 21  fún Hilikáyà, Haṣabáyà; fún Jedáyà,+ Nétánélì. 22  Àwọn ọmọ Léfì ní ọjọ́ Élíáṣíbù,+ Jóyádà+ àti Jóhánánì àti Jádúà+ ni a kọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn olórí àwọn ìdí ilé baba, àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú, títí di ìgbà àkóso Dáríúsì ará Páṣíà. 23  Àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí àwọn olórí àwọn ìdí ilé baba+ ni a kọ sílẹ̀ nínú ìwé àlámọ̀rí ti àwọn àkókò náà, àní títí di ọjọ́ Jóhánánì ọmọkùnrin Élíáṣíbù. 24  Àwọn olórí àwọn ọmọ Léfì sì ni Haṣabáyà, Ṣerebáyà+ àti Jéṣúà ọmọkùnrin Kádímíélì+ àti àwọn arákùnrin wọn ní òdì-kejì wọn láti máa mú ìyìn wá àti láti dúpẹ́ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ+ Dáfídì ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́, tí àwùjọ àwọn ẹ̀ṣọ́ ṣe rẹ́gí pẹ̀lú àwùjọ àwọn ẹ̀ṣọ́. 25  Matanáyà+ àti Bakibúkáyà, Ọbadáyà, Méṣúlámù, Tálímónì, Ákúbù+ ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ gẹ́gẹ́ bí aṣọ́bodè,+ àwùjọ àwọn ẹ̀ṣọ́ ní ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ sí ti ẹnubodè. 26  Àwọn wọ̀nyí wà ní ọjọ́ Jóyákímù+ ọmọkùnrin Jéṣúà+ ọmọkùnrin Jósádákì+ àti ní ọjọ́ Nehemáyà+ gómìnà àti Ẹ́sírà+ àlùfáà, tí í ṣe adàwékọ.+ 27  Nígbà àyẹyẹ ṣíṣí+ ògiri Jerúsálẹ́mù, wọ́n wá àwọn ọmọ Léfì kiri, láti mú wọn kúrò ní gbogbo àyè wọn wá sí Jerúsálẹ́mù láti ṣe ayẹyẹ ṣíṣí i àti ayọ̀ yíyọ̀, àní pẹ̀lú ìdúpẹ́+ àti orin,+ àwọn aro àti àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín+ àti àwọn háàpù.+ 28  Àwọn ọmọ àwọn akọrin sì bẹ̀rẹ̀ sí kó ara wọn jọ àní láti Àgbègbè,+ láti gbogbo àyíká Jerúsálẹ́mù àti láti àwọn ibi ìtẹ̀dó àwọn ará Nétófà,+ 29  àti láti Bẹti-gílígálì+ àti láti àwọn pápá Gébà+ àti Ásímáfẹ́tì,+ nítorí àwọn ibi ìtẹ̀dó+ wà tí àwọn akọrin ti kọ́ fún ara wọn ní gbogbo àyíká Jerúsálẹ́mù. 30  Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì sì bẹ̀rẹ̀ sí wẹ ara wọn mọ́,+ wọ́n sì wẹ àwọn ènìyàn+ mọ́ àti ẹnubodè+ àti ògiri.+ 31  Lẹ́yìn náà, mo mú àwọn ọmọ aládé+ Júdà gòkè wá sórí ògiri náà. Síwájú sí i, mo yan ẹgbẹ́ akọrin+ ìdúpẹ́ méjì tí ó tóbi sípò àti ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń tọ́wọ̀ọ́rìn, [ọ̀kan sì ń rìn] sí ọ̀tún lórí ògiri lọ sí Ẹnubodè Àwọn Òkìtì-eérú.+ 32  Hóṣáyà àti ìdajì àwọn ọmọ aládé Júdà sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn tọ̀ wọ́n lẹ́yìn, 33  àti pẹ̀lú Asaráyà, Ẹ́sírà àti Méṣúlámù, 34  Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti Ṣemáyà àti Jeremáyà; 35  àti lára àwọn ọmọ àlùfáà tí wọ́n ní kàkàkí+ lọ́wọ́, Sekaráyà ọmọkùnrin Jónátánì ọmọkùnrin Ṣemáyà ọmọkùnrin Matanáyà ọmọkùnrin Mikáyà ọmọkùnrin Sákúrì+ ọmọkùnrin Ásáfù,+ 36  àti àwọn arákùnrin rẹ̀, Ṣemáyà àti Ásárẹ́lì, Míláláì, Gíláláì, Máì, Nétánélì àti Júdà, Hánáánì, pẹ̀lú ohun èlò+ orin Dáfídì ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́; àti Ẹ́sírà+ adàwékọ níwájú wọn. 37  Ní Ẹnubodè Ojúsun+ àti ní ọ̀kánkán wọn tààrà ni wọ́n gòkè lọ sórí Àtẹ̀gùn+ Ìlú Ńlá Dáfídì+ ní ìgòkè ògiri lórí Ilé Dáfídì títí lọ dé Ẹnubodè Omi+ ní ìlà-oòrùn. 38  Ẹgbẹ́ akọrin+ ìdúpẹ́ kejì sì ń rìn lọ ní iwájú, àti èmi lẹ́yìn rẹ̀, àti ìdajì àwọn ènìyàn náà, lórí ògiri lókè Ilé Gogoro Àwọn Ààrò Ìyan-nǹkan+ àti títí dé orí Ògiri Fífẹ̀,+ 39  àti lókè Ẹnubodè Éfúráímù+ títí dé Ẹnubodè Ìlú Ńlá Àtijọ́+ àti títí dé Ẹnubodè Ẹja+ àti Ilé Gogoro Hánánélì+ àti Ilé Gogoro Méà+ àti títí dé Ẹnubodè Àgùntàn;+ wọ́n sì dúró ní Ẹnubodè Ẹ̀ṣọ́. 40  Nígbà tí ó ṣe, ẹgbẹ́ akọrin+ ìdúpẹ́ méjèèjì sì dúró ní ilé+ Ọlọ́run tòótọ́, àti èmi, àti ìdajì àwọn ajẹ́lẹ̀ pẹ̀lú mi,+ 41  àti àwọn àlùfáà náà, Élíákímù, Maaseáyà, Míníámínì, Mikáyà, Élíóénáì, Sekaráyà, Hananáyà pẹ̀lú àwọn kàkàkí+ lọ́wọ́, 42  àti Maaseáyà àti Ṣemáyà, àti Élíásárì àti Úsáì àti Jèhóhánánì àti Málíkíjà àti Élámù àti Ésérì. Àwọn akọrin àti Isiráháyà alábòójútó sì ń mú kí a gbọ́ ohùn wọn.+ 43  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí rú àwọn ẹbọ ńláǹlà+ ní ọjọ́ yẹn,+ wọ́n sì ń yọ̀, nítorí Ọlọ́run tòótọ́ ti mú kí wọ́n máa yọ̀ pẹ̀lú ìdùnnú ńláǹlà.+ Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn obìnrin+ àti àwọn ọmọdé+ pàápàá sì yọ̀, tí ó fi jẹ́ pé a gbọ́ ayọ̀ yíyọ̀ Jerúsálẹ́mù ní ibi jíjìnnà réré.+ 44  Síwájú sí i, ní ọjọ́ yẹn, a yan àwọn ènìyàn sípò lórí àwọn gbọ̀ngàn+ náà fún àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ sí,+ fún àwọn ọrẹ,+ fún àwọn àkọ́so+ àti fún àwọn ìdá mẹ́wàá,+ láti kó àwọn tí ó wà nínú pápá àwọn ìlú ńlá náà jọ sínú wọn, àwọn ìpín tí òfin béèrè+ fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì;+ nítorí ayọ̀ yíyọ̀ Júdà jẹ́ nítorí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì+ tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ àbójútó. 45  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kíyè sí iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe+ ti Ọlọ́run wọn àti iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ìwẹ̀mọ́gaara,+ pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn akọrin+ àti àwọn aṣọ́bodè,+ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Dáfídì àti Sólómọ́nì ọmọkùnrin rẹ̀. 46  Nítorí ní ọjọ́ Dáfídì àti Ásáfù ní àkókò tí ó ti kọjá lọ, àwọn olórí akọrin+ wà àti orin ìyìn àti ìdúpẹ́ fún Ọlọ́run.+ 47  Gbogbo Ísírẹ́lì ní ọjọ́ Serubábélì+ àti ní ọjọ́ Nehemáyà+ sì ń fúnni ní ìpín àwọn akọrin+ àti àwọn aṣọ́bodè+ ní ìbámu pẹ̀lú àìní ojoojúmọ́, wọ́n sì ń sọ wọ́n di mímọ́ fún àwọn ọmọ Léfì;+ àwọn ọmọ Léfì sì ń sọ wọ́n di mímọ́ fún àwọn ọmọ Áárónì.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé