Nehemáyà 11:1-36
11 Wàyí o, àwọn ọmọ aládé+ àwọn ènìyàn náà ń gbé ní Jerúsálẹ́mù;+ ṣùgbọ́n ní ti ìyókù àwọn ènìyàn náà, wọ́n ṣẹ́ kèké+ láti mú ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú mẹ́wàá-mẹ́wàá wá láti máa gbé ní Jerúsálẹ́mù ìlú ńlá mímọ́,+ apá mẹ́sàn-án yòókù sì wà nínú àwọn ìlú ńlá mìíràn.
2 Síwájú sí i, àwọn ènìyàn náà súre+ fún gbogbo ọkùnrin tí wọ́n fínnú-fíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn+ láti máa gbé ní Jerúsálẹ́mù.
3 Ìwọ̀nyí sì ni àwọn olórí àgbègbè abẹ́ àṣẹ+ tí ń gbé ní Jerúsálẹ́mù;+ ṣùgbọ́n ní àwọn ìlú ńlá Júdà, olúkúlùkù ń gbé inú ohun ìní rẹ̀, nínú àwọn ìlú ńlá+ wọn, Ísírẹ́lì,+ àwọn àlùfáà+ àti àwọn ọmọ Léfì,+ àti àwọn Nétínímù+ àti àwọn ọmọkùnrin àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì.+
4 Pẹ̀lúpẹ̀lù, Jerúsálẹ́mù ni àwọn kan lára àwọn ọmọ Júdà ń gbé àti àwọn kan lára àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì.+ Lára àwọn ọmọ Júdà ni Átáyà ọmọkùnrin Ùsáyà ọmọkùnrin Sekaráyà ọmọkùnrin Amaráyà ọmọkùnrin Ṣẹfatáyà ọmọkùnrin Máhálálélì lára àwọn ọmọ Pérésì wà;+
5 àti Maaseáyà ọmọkùnrin Bárúkù ọmọkùnrin Kólíhósè ọmọkùnrin Hasáyà ọmọkùnrin Ádáyà ọmọkùnrin Jóyáríbù ọmọkùnrin Sekaráyà ọmọkùnrin ọmọ Ṣélà.
6 Gbogbo ọmọkùnrin Pérésì tí ń gbé ní Jerúsálẹ́mù jẹ́ ọ̀tà-lé-nírínwó ó lé mẹ́jọ, àwọn ọkùnrin tí ó dáńgájíá.
7 Ìwọ̀nyí sì ni àwọn ọmọkùnrin Bẹ́ńjámínì:+ Sáálù ọmọkùnrin Méṣúlámù+ ọmọkùnrin Jóédì ọmọkùnrin Pedáyà ọmọkùnrin Koláyà ọmọkùnrin Maaseáyà ọmọkùnrin Ítíélì ọmọkùnrin Jeṣáyà;
8 àti lẹ́yìn rẹ̀ ni Gábáì àti Sáláì, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n;
9 àti Jóẹ́lì ọmọkùnrin Síkírì, alábòójútó lórí wọn, àti Júdà ọmọkùnrin Hásénúà lórí ìlú ńlá náà gẹ́gẹ́ bí igbá-kejì.
10 Lára àwọn àlùfáà: Jedáyà ọmọkùnrin Jóyáríbù,+ Jákínì,+
11 Seráyà ọmọkùnrin Hilikáyà ọmọkùnrin Méṣúlámù+ ọmọkùnrin Sádókù+ ọmọkùnrin Méráótì ọmọkùnrin Áhítúbù,+ aṣáájú ilé Ọlọ́run tòótọ́;
12 àti àwọn arákùnrin wọn, àwọn olùṣe iṣẹ́ ilé,+ ẹgbẹ̀rin ó lé méjìlélógún; àti Ádáyà ọmọkùnrin Jéróhámù+ ọmọkùnrin Pẹlaláyà ọmọkùnrin Ámísì ọmọkùnrin Sekaráyà ọmọkùnrin Páṣúrì+ ọmọkùnrin Málíkíjà,+
13 àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn olórí ìdí ilé baba,+ òjìlúgba ó lé méjì, àti Ámáṣísáì ọmọkùnrin Ásárẹ́lì ọmọkùnrin Ásáì ọmọkùnrin Méṣílémótì ọmọkùnrin Ímérì,
14 àti àwọn arákùnrin wọn, àwọn ògbójú ọkùnrin alágbára ńlá,+ méjì-dín-láàádóje, alábòójútó+ kan sì wà lórí wọn, Sábídíẹ́lì ọmọkùnrin àwọn ẹni ńlá.
15 Àti lára àwọn ọmọ Léfì+ ni: Ṣemáyà ọmọkùnrin Háṣúbù, ọmọkùnrin Ásíríkámù ọmọkùnrin Haṣabáyà+ ọmọkùnrin Búnì,
16 àti Ṣábétáì+ àti Jósábádì,+ lára àwọn olórí àwọn ọmọ Léfì, tí wọ́n wà lórí iṣẹ́ àmójútó òde tí ó jẹ́ ti ilé Ọlọ́run tòótọ́;
17 Matanáyà+ alára, ọmọkùnrin Míkà ọmọkùnrin Sábídì ọmọkùnrin Ásáfù,+ olùdarí orin+ ìyìn, sì ṣe ìgbélárugẹ nígbà àdúrà,+ Bakibúkáyà sì jẹ́ èkejì nínú àwọn arákùnrin rẹ̀, àti Ábídà ọmọkùnrin Ṣámúà ọmọkùnrin Gálálì+ ọmọkùnrin Jédútúnì.+
18 Gbogbo àwọn ọmọ Léfì nínú ìlú ńlá+ mímọ́ jẹ́ ọ̀rìn-lérúgba ó lé mẹ́rin.
19 Àwọn aṣọ́bodè+ sì ni Ákúbù, Tálímónì+ àti àwọn arákùnrin wọn tí ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ ní àwọn ẹnubodè,+ méjì-lé-láàádọ́sàn-án.
20 Ìyókù Ísírẹ́lì, lára àwọn àlùfáà àti lára àwọn ọmọ Léfì sì wà nínú gbogbo àwọn ìlú ńlá mìíràn ní Júdà, olúkúlùkù nínú ohun ìní rẹ̀ àjogúnbá.+
21 Àwọn Nétínímù+ sì ń gbé ní Ófélì;+ Síhà àti Gíṣípà sì ń ṣolórí àwọn Nétínímù.
22 Alábòójútó+ àwọn ọmọ Léfì ní Jerúsálẹ́mù sì ni Úsáì ọmọkùnrin Bánì ọmọkùnrin Haṣabáyà ọmọkùnrin Matanáyà+ ọmọkùnrin Máíkà+ lára àwọn ọmọ Ásáfù,+ àwọn akọrin,+ nípa iṣẹ́ ilé Ọlọ́run tòótọ́.
23 Nítorí àṣẹ kan wá láti ọ̀dọ̀ ọba ní tìtorí wọn,+ ìpèsè tí a fi lélẹ̀ fún àwọn akọrin sì wà gẹ́gẹ́ bí ohun tí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan béèrè.+
24 Petaháyà ọmọkùnrin Meṣesábélì lára àwọn ọmọ Síírà ọmọkùnrin Júdà sì wà ní ẹ̀gbẹ́ ọba fún gbogbo ọ̀ràn àwọn ènìyàn.
25 Àti ní ti ibi ìtẹ̀dó+ nínú àwọn pápá wọn, àwọn kan lára àwọn ọmọ Júdà wà tí ń gbé ní Kiriati-ábà+ àti àwọn àrọko rẹ̀ àti ní Díbónì àti àwọn àrọko rẹ̀ àti ní Jekabúsélì+ àti ní àwọn ibi ìtẹ̀dó rẹ̀,
26 àti ní Jéṣúà àti ní Móládà+ àti ní Bẹti-pélétì+
27 àti ní Hasari-ṣúálì+ àti ní Bíá-ṣébà+ àti àwọn àrọko rẹ̀
28 àti ní Síkílágì+ àti ní Mékónà àti àwọn àrọko rẹ̀
29 àti ní Ẹ́ń-rímónì+ àti ní Sórà+ àti ní Jámútì,+
30 Sánóà,+ Ádúlámù+ àti àwọn ibi ìtẹ̀dó wọn, Lákíṣì+ àti àwọn pápá rẹ̀, Ásékà+ àti àwọn àrọko rẹ̀. Wọ́n sì dó láti Bíá-ṣébà títí lọ dé àfonífojì Hínómù.+
31 Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì sì wá láti Gébà,+ Míkímáṣì+ àti Áíjà+ àti Bẹ́tẹ́lì+ àti àwọn àrọko rẹ̀,
32 Ánátótì,+ Nóbù,+ Ananáyà,
33 Hásórì, Rámà,+ Gítáímù,+
34 Hádídì, Sébóímù, Nébálátì,
35 Lódì+ àti Ónò,+ àfonífojì àwọn oníṣẹ́ ọnà.
36 Lára àwọn ọmọ Léfì, àwọn ìpín Júdà wà tí ń bẹ ní Bẹ́ńjámínì.