Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Nehemáyà 10:1-39

10  Wàyí o, àwọn tí ó fi èdìdì+ jẹ́rìí sí i ni: Nehemáyà,+ tí í ṣe Tíṣátà,+ ọmọkùnrin Hakaláyà,+ Àti Sedekáyà,  Seráyà,+ Asaráyà, Jeremáyà,  Páṣúrì, Amaráyà, Málíkíjà,  Hátúṣì, Ṣebanáyà, Málúkù,  Hárímù,+ Mérémótì, Ọbadáyà,  Dáníẹ́lì,+ Gínétónì, Bárúkù,  Méṣúlámù, Ábíjà, Míjámínì,  Maasáyà, Bílígáì àti Ṣemáyà, àwọn yìí jẹ́ àlùfáà.  Pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì: Jéṣúà+ ọmọkùnrin Asanáyà, Bínúì nínú àwọn ọmọ Hénádádì,+ Kádímíélì 10  àti arákùnrin wọn Ṣebanáyà,+ Hodáyà, Kélítà, Pẹláyà, Hánánì, 11  Máíkà, Réhóbù, Haṣabáyà, 12  Sákúrì, Ṣerebáyà,+ Ṣebanáyà, 13  Hodáyà, Bánì àti Bẹnínù. 14  Àwọn olórí àwọn ènìyàn náà: Páróṣì, Pahati-móábù,+ Élámù, Sátù, Bánì, 15  Búnì, Ásígádì, Bébáì, 16  Ádóníjà, Bígífáì, Ádínì, 17  Átérì, Hesekáyà, Ásúrì, 18  Hodáyà, Háṣúmù, Bísáì, 19  Hárífù, Ánátótì, Nébáì, 20  Mágípíáṣì, Méṣúlámù, Hésírì, 21  Meṣesábélì, Sádókù, Jádúà, 22  Pẹlatáyà, Hánánì, Ánáyà, 23  Hóṣéà, Hananáyà, Háṣúbù, 24  Hálóhéṣì, Pílíhà, Ṣóbékì, 25  Réhúmù, Háṣábínà, Maaseáyà, 26  àti Áhíjà, Hánánì, Ánánì, 27  Málúkù, Hárímù, Báánáhì. 28  Ní ti ìyókù àwọn ènìyàn náà, àwọn àlùfáà,+ àwọn ọmọ Léfì,+ àwọn aṣọ́bodè,+ àwọn akọrin,+ àwọn Nétínímù+ àti gbogbo ẹni tí ó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn àwọn ilẹ̀ náà+ fún òfin+ Ọlọ́run tòótọ́, àwọn aya wọn, àwọn ọmọkùnrin wọn àti ọmọbìnrin wọn, gbogbo ẹni tí ó ní ìmọ̀ àti òye,+ 29  wọ́n rọ̀ mọ́ àwọn arákùnrin+ wọn, àwọn ọlọ́lá ọba+ nínú wọn, wọ́n sì wá sínú ipò dídáhùn fún ègún+ àti ìbúra,+ láti rìn nínú òfin Ọlọ́run tòótọ́, èyí tí a fi fúnni láti ọwọ́ Mósè ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́,+ àti láti pa mọ́+ àti láti tẹ̀ lé gbogbo àṣẹ Jèhófà Olúwa+ wa àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀ àti àwọn ìlànà+ rẹ̀; 30  àti pé a kò gbọ́dọ̀ fi àwọn ọmọbìnrin wa fún àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, a kò sì gbọ́dọ̀ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin wa.+ 31  Ní ti àwọn ènìyàn ilẹ̀+ náà tí ń mú nǹkan títà àti gbogbo onírúurú hóró ọkà wá ní ọjọ́ sábáàtì láti tà, a kò gbọ́dọ̀ gba nǹkan kan lọ́wọ́ wọn ní sábáàtì+ tàbí ní ọjọ́ mímọ́,+ kí a sì mójú kúrò nínú ọdún keje+ àti gbèsè tí ó wà ní ọwọ́+ olúkúlùkù. 32  Pẹ̀lúpẹ̀lù, a gbé àṣẹ ka ara wa lórí pé, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa, yóò mú ìdá mẹ́ta ṣékélì wá lọ́dọọdún fún iṣẹ́ ìsìn ilé Ọlọ́run wa,+ 33  fún búrẹ́dì onípele+ àti ọrẹ ẹbọ ọkà ìgbà gbogbo+ àti ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo ti àwọn sábáàtì,+ àwọn òṣùpá tuntun,+ fún àwọn àsè+ tí a yàn kalẹ̀ àti fún àwọn ohun mímọ́+ àti fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ láti ṣe ètùtù fún Ísírẹ́lì àti gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa.+ 34  Pẹ̀lúpẹ̀lù, a ṣẹ́ kèké+ lórí ìpèsè igi+ tí àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì àti àwọn ènìyàn náà ní láti mú wá sí ilé Ọlọ́run wa,+ ní ìbámu pẹ̀lú ilé àwọn baba ńlá wa, ní àkókò tí a yàn kalẹ̀, ní ọdọọdún, láti máa fi dáná lórí pẹpẹ Jèhófà Ọlọ́run wa, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ sínú òfin;+ 35  àti láti mú àkọ́pọ́n èso ilẹ̀+ wa àti àkọ́pọ́n èso gbogbo onírúurú èso igi+ wá ní ọdọọdún, sí ilé Jèhófà; 36  àti àkọ́bí+ àwọn ọmọkùnrin wa àti ti ẹran agbéléjẹ̀+ wa, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ sínú òfin,+ àti àkọ́bí àwọn ọ̀wọ́ ẹran wa àti ti àwọn agbo ẹran+ wa, láti mú wọn wá sí ilé Ọlọ́run wa, sọ́dọ̀ àwọn àlùfáà tí wọ́n ń ṣe ìránṣẹ́ nínú ilé Ọlọ́run wa.+ 37  Pẹ̀lúpẹ̀lù, àkọ́so ẹ̀wẹ́ ọkà+ wa àti ọrẹ+ wa àti èso onírúurú igi,+ wáìnì tuntun+ àti òróró+ ni kí a mú wá fún àwọn àlùfáà ní àwọn gbọ̀ngàn ìjẹun+ ilé Ọlọ́run wa, àti ìdá mẹ́wàá láti ilẹ̀ wa fún àwọn ọmọ Léfì,+ níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé àwọn, ìyẹn àwọn ọmọ Léfì, ni wọ́n ń gba ìdá mẹ́wàá ní gbogbo ìlú ńlá wa tí ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀. 38  Kí àlùfáà, ọmọkùnrin Áárónì, sì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì nígbà tí àwọn ọmọ Léfì bá ń gba ìdá mẹ́wàá; kí àwọn ọmọ Léfì fúnra wọn fi ìdá mẹ́wàá rúbọ lára ìdá mẹ́wàá ilé Ọlọ́run wa+ ní àwọn gbọ̀ngàn ìjẹun+ ilé ìpèsè. 39  Nítorí àwọn gbọ̀ngàn ìjẹun ni kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ọmọ Léfì mú ọrẹ+ ọkà, wáìnì tuntun+ àti òróró wá, ibẹ̀ sì ni àwọn nǹkan èlò ibùjọsìn àti àwọn àlùfáà tí ń ṣe ìránṣẹ́,+ àti àwọn aṣọ́bodè+ àti àwọn akọrin+ wà; a kò sì gbọ́dọ̀ ṣàìnáání ilé Ọlọ́run wa.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé