Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Nehemáyà 1:1-11

1  Ọ̀rọ̀ Nehemáyà+ ọmọkùnrin Hakaláyà: Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ ní oṣù Kísíléfì,+ ní ọdún ogún,+ pé èmi fúnra mi wà ní Ṣúṣánì+ ilé aláruru.  Nígbà náà ni Hánáánì,+ ọ̀kan lára àwọn arákùnrin mi wọlé, òun àti àwọn ọkùnrin mìíràn láti Júdà, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè+ lọ́wọ́ wọn nípa àwọn Júù,+ àwọn tí ó sá àsálà,+ tí wọ́n ṣẹ́ kù lára àwọn òǹdè,+ àti nípa Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú.  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n sọ fún mi pé: “Àwọn tí ó ṣẹ́ kù, tí ó ṣẹ́ kù láti oko òǹdè, lọ́hùn-ún ní àgbègbè abẹ́ àṣẹ,+ wà nínú ipò ìṣòro tí ó burú gidigidi+ àti nínú ẹ̀gàn;+ ògiri+ Jerúsálẹ́mù ti wó lulẹ̀, àwọn ẹnubodè+ rẹ̀ pàápàá ni a ti fi iná sun.”  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, mo jókòó, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún, mo sì ń ṣọ̀fọ̀ fún ọjọ́ púpọ̀, mo sì ń bá a lọ ní gbígbààwẹ̀+ àti ní gbígbàdúrà níwájú Ọlọ́run ọ̀run.+  Mo sì ń bá a lọ láti wí pé: “Áà, Jèhófà Ọlọ́run ọ̀run, Ọlọ́run títóbi, tí ó sì ń múni kún fún ẹ̀rù,+ tí ń pa májẹ̀mú+ àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ mọ́ sí àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀,+ tí ó sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́,+  jọ̀wọ́, jẹ́ kí etí rẹ ṣí sílẹ̀,+ kí ojú rẹ sì là, láti fetí sí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ,+ tí mo ń gbà níwájú rẹ lónìí, tọ̀sán-tòru,+ nípa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìránṣẹ́ rẹ, ní gbogbo ìgbà yìí tí mo ti ń jẹ́wọ́+ nípa ẹ̀ṣẹ̀+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì èyí tí a ṣẹ̀ sí ọ. A ti ṣẹ̀, àti èmi àti ilé baba mi.+  Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, a ti hùwà ìbàjẹ́ sí ọ,+ a kò sì pa àwọn àṣẹ+ àti àwọn ìlànà+ àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ mọ́,+ èyí tí o ti pa láṣẹ fún Mósè ìránṣẹ́+ rẹ.  “Jọ̀wọ́, rántí+ ọ̀rọ̀ tí o pa láṣẹ fún Mósè ìránṣẹ́ rẹ pé, ‘Bí ẹ̀yin, ní tiyín bá ṣe àìṣòótọ́, èmi, ní tèmi yóò tú yín ká sáàárín àwọn ènìyàn.+  Nígbà tí ẹ bá ti padà sọ́dọ̀ mi,+ tí ẹ sì pa àwọn àṣẹ+ mi mọ́, tí ẹ sì tẹ̀ lé wọn,+ bí àwọn ènìyàn yín tí a fọ́n ká bá tílẹ̀ wà ní ìpẹ̀kun ọ̀run, láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti kó+ wọn jọ, tí èmi yóò sì mú+ wọn wá dájúdájú sí ibi tí mo ti yàn láti mú kí orúkọ mi máa gbé ibẹ̀.’+ 10  Àwọn sì ni ìránṣẹ́+ rẹ àti ènìyàn+ rẹ, tí o túnrà padà nípa agbára ńlá+ rẹ àti nípa ọwọ́ líle+ rẹ. 11  Áà, Jèhófà, jọ̀wọ́, jẹ́ kí etí rẹ ṣí sí àdúrà+ ìránṣẹ́ rẹ àti sí àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí ó ní inú dídùn sí bíbẹ̀rù orúkọ+ rẹ; jọ̀wọ́, sì yọ̀ǹda àṣeyọrí sí rere fún ìránṣẹ́ rẹ lónìí,+ kí o sì sọ ọ́ di ẹni ìṣojú-àánú-sí níwájú ọkùnrin yìí.”+ Wàyí o, èmi alára jẹ́ agbọ́tí+ ọba.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé