Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Númérì 9:1-23

9  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti bá Mósè sọ̀rọ̀ ní aginjù Sínáì ní ọdún kejì  tí wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, ní oṣù kìíní,+ pé:  “Wàyí o, kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pèsè ẹbọ ìrékọjá+ sílẹ̀ ní àkókò rẹ̀ tí a yàn kalẹ̀.+  Ọjọ́ kẹrìnlá ní oṣù yìí láàárín àwọn ìrọ̀lẹ́ méjèèjì + ni kí ẹ pèsè rẹ̀ sílẹ̀ ní àkókò rẹ̀ tí a yàn kalẹ̀. Ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbogbo ọ̀nà tí a ń gbà ṣe é ni kí ẹ pèsè rẹ̀ sílẹ̀.”+  Nítorí náà, Mósè bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ pé kí wọ́n máa pèsè ẹbọ ìrékọjá sílẹ̀.  Nígbà náà ni wọ́n pèsè ẹbọ ìrékọjá sílẹ̀ ní oṣù kìíní, ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù náà láàárín àwọn ìrọ̀lẹ́ méjèèjì , ní aginjù Sínáì. Ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Jèhófà ti pa láṣẹ fún Mósè, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe.+  Wàyí o, àwọn ọkùnrin kan báyìí wà tí ọkàn+ ẹ̀dá ènìyàn ti sọ di aláìmọ́, tí wọn kò fi lè pèsè ẹbọ ìrékọjá sílẹ̀ ní ọjọ́ yẹn. Nítorí náà, wọ́n wá sọ́dọ̀ Mósè àti Áárónì ní ọjọ́ náà.+  Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin wọ̀nyẹn wí fún un pé: “Ọkàn ẹ̀dá ènìyàn ti sọ wá di aláìmọ́. Èé ṣe tí a ó fi dí wa lọ́wọ́ mímú ọrẹ ẹbọ+ wá fún Jèhófà ní àkókò rẹ̀ tí a yàn kalẹ̀ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?”  Látàrí èyí, Mósè wí fún wọn pé: “Ẹ dúró síbẹ̀ yẹn, kí ẹ sì jẹ́ kí n gbọ́ ohun tí Jèhófà yóò pa láṣẹ nípa yín.”+  Nígbà náà ni Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: 10  “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, pé, ‘Bí ó bá tilẹ̀ ṣẹlẹ̀ pé ọkàn+ kan sọ ọkùnrin èyíkéyìí nínú yín tàbí nínú àwọn ìran yín di aláìmọ́ tàbí pé ó rin ìrìn àjò jíjì nnà, kí òun pẹ̀lú pèsè ẹbọ ìrékọjá sílẹ̀ fún Jèhófà. 11  Ní oṣù kejì ,+ ní ọjọ́ kẹrìnlá láàárín àwọn ìrọ̀lẹ́ méjèèjì , ni kí wọ́n pèsè rẹ̀ sílẹ̀. Kí wọ́n jẹ ẹ́ pa pọ̀ pẹ̀lú àkàrà aláìwú àti ewébẹ̀ kíkorò.+ 12  Kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí èyíkéyìí nínú rẹ̀ ṣẹ́ kù títí di òwúrọ̀,+ kí wọ́n má sì ṣe fọ́ egungun kankan nínú rẹ̀.+ Ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ìlànà àgbékalẹ̀ ìrékọjá ni kí wọ́n pèsè rẹ̀ sílẹ̀.+ 13  Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà bá mọ́ tàbí tí kò ṣẹlẹ̀ pé ó rin ìrìn àjò, tí ó sì ṣàìnáání pípèsè ẹbọ ìrékọjá sílẹ̀, nígbà náà, ọkàn yẹn ni kí a ké kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀,+ nítorí pé ọrẹ ẹbọ Jèhófà ni kò mú wá ní àkókò rẹ̀ tí a yàn kalẹ̀. Ọkùnrin yẹn yóò dáhùn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.+ 14  “‘Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé àtìpó kan ń ṣe àtìpó lọ́dọ̀ yín, kí òun pẹ̀lú pèsè ẹbọ ìrékọjá sílẹ̀ fún Jèhófà.+ Ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà àgbékalẹ̀ ìrékọjá àti ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí a ń gbà ṣe é ni kí ó ṣe é.+ Ìlànà àgbékalẹ̀ kan ni kí ó wà fún yín, fún àtìpó àti fún ọmọ ìbílẹ̀ ti ilẹ̀ náà.’”+ 15  Wàyí o, ní ọjọ́ gbígbé àgọ́ ìjọsìn+ nà ró, àwọsánmà bo àgọ́ ìjọsìn ti àgọ́ Gbólóhùn Ẹ̀rí,+ ṣùgbọ́n ní ìrọ̀lẹ́ ohun tí ó fara jọ iná+ ń bá a lọ láti wà lórí àgọ́ ìjọsìn títí di òwúrọ̀. 16  Bí ó ṣe ń bá a lọ nígbà gbogbo nìyẹn: Àwọsánmà a bò ó ní ọ̀sán, àti ohun tí ó fara jọ iná ní òru.+ 17  Nígbàkigbà tí àwọsánmà bá sì gòkè kúrò lórí àgọ́ náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì a ṣí kété lẹ́yìn ìgbà náà,+ ibi tí àwọsánmà náà bá sì gbé, ibẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì a dó sí.+ 18  Nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì a ṣí, nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà, wọn a sì dó.+ Ní gbogbo ọjọ́ tí àwọsánmà bá fi gbé lórí àgọ́ ìjọsìn, wọn a wà ní ibùdó. 19  Nígbà tí àwọsánmà bá sì dúró pẹ́ lórí àgọ́ ìjọsìn ní ọjọ́ púpọ̀, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú a máa pa iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe wọn mọ́ sí Jèhófà pé kí wọ́n má ṣe ṣí.+ 20  Nígbà mìíràn àwọsánmà a sì máa bá a lọ fún ọjọ́ díẹ̀ lórí àgọ́ ìjọsìn. Nípa àṣẹ ìtọ́ni+ Jèhófà, wọn a wà ní ibùdó, nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà, wọn a sì ṣí. 21  Nígbà mìíràn àwọsánmà+ a sì máa bá a lọ láti ìrọ̀lẹ́ di òwúrọ̀; àwọsánmà náà a sì gbé ara rẹ̀ sókè ní òwúrọ̀, wọn a sì ṣí. Ì báà jẹ́ ọ̀sán tàbí òru ni àwọsánmà náà gbé ara rẹ̀ sókè, wọn a ṣí pẹ̀lú.+ 22  Ì báà jẹ́ ọjọ́ méjì  tàbí oṣù kan tàbí ọjọ́ púpọ̀ sí i ni àwọsánmà fi dúró pẹ́ lórí àgọ́ ìjọsìn nípa gbígbé lórí rẹ̀, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì a wà ní ibùdó, wọn kì yóò sì ṣí, ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá gbé ara rẹ̀ sókè, wọn a ṣí.+ 23  Nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà, wọn a dó, nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà, wọn a sì ṣí. Wọ́n pa iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe+ wọn mọ́ sí Jèhófà nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà nípasẹ̀ Mósè.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé