Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Númérì 8:1-26

8  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé:  “Bá Áárónì sọ̀rọ̀, kí o sì wí fún un pe, ‘Nígbàkigbà tí o bá tan àwọn fìtílà, kí àwọn fìtílà méje náà tàn sí àyè ilẹ̀ tí ó wà níwájú ọ̀pá fìtílà náà.’”+  Áárónì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bẹ́ẹ̀. Ó tan àwọn fìtílà ibẹ̀ fún àyè ilẹ̀ tí ó wà níwájú ọ̀pá fìtílà náà,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè.  Wàyí o, èyí ni iṣẹ́ ọnà ọ̀pá fìtílà náà. Ó jẹ́ iṣẹ́ òòlù tí a fi wúrà ṣe. Ó jẹ́ iṣẹ́ òòlù+ títí dé àwọn ìhà rẹ̀ àti títí dé àwọn ìtànná rẹ̀. Ní ìbámu pẹ̀lú ìran+ náà tí Jèhófà ti fi han Mósè, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe ọ̀pá fìtílà náà.  Jèhófà sì bá Mósè sọ̀rọ̀ síwájú sí i, pé:  “Mú àwọn ọmọ Léfì kúrò láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì wẹ̀ wọ́n mọ́.+  Èyí sì ni ohun tí ìwọ yóò ṣe fún wọn láti wẹ̀ wọ́n mọ́: Wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ ẹ̀ṣẹ̀ sórí wọn ṣẹ̀rẹ̀ṣẹ̀rẹ̀,+ kí wọ́n sì jẹ́ kí abẹ fẹ́lẹ́ kọjá ní gbogbo ara wọn,+ kí wọ́n sì fọ ẹ̀wù+ wọn, kí wọ́n sì wẹ ara wọn mọ́.+  Lẹ́yìn náà, kí wọ́n mú ẹgbọrọ akọ màlúù+ kan àti ọrẹ ẹbọ ọkà+ rẹ̀ ti ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, kí o sì mú ẹgbọrọ akọ màlúù mìíràn fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.+  Kí o sì mú àwọn ọmọ Léfì wá síwájú àgọ́ ìpàdé, kí o sì pe gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọpọ̀.+ 10  Kí o sì mú àwọn ọmọ Léfì wá síwájú Jèhófà, kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì gbé ọwọ́ wọn lé+ àwọn ọmọ Léfì.+ 11  Kí Áárónì sì mú kí àwọn ọmọ Léfì lọ síwá-sẹ́yìn níwájú Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fífì+ láti ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí wọ́n sì wà fún ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.+ 12  “Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Léfì yóò gbé ọwọ́ wọn lé orí àwọn akọ màlúù+ náà. Lẹ́yìn ìyẹn, fi ọ̀kan rúbọ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ìkejì gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun sí Jèhófà láti ṣe ètùtù+ fún àwọn ọmọ Léfì. 13  Kí o sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Léfì dúró níwájú Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, kí o sì mú kí wọ́n lọ síwá-sẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fífì sí Jèhófà. 14  Kí o sì ya àwọn ọmọ Léfì sọ́tọ̀ kúrò láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn ọmọ Léfì yóò sì di tèmi.+ 15  Lẹ́yìn ìgbà náà sì ni àwọn ọmọ Léfì yóò wọlé wá láti sìn ní àgọ́ ìpàdé.+ Nítorí náà, kí o wẹ̀ wọ́n mọ́, kí o sì mú kí wọ́n lọ síwá-sẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fífì.+ 16  Nítorí wọ́n jẹ́ àwọn ẹni tí a fi fúnni, tí a fi fún mi láti inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ Dípò àwọn tí ó ṣí gbogbo ilé ọlẹ̀, gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ èmi yóò mú wọn fún ara mi. 17  Nítorí olúkúlùkù àkọ́bí láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ tèmi, láàárín ènìyàn àti láàárín ẹranko.+ Ọjọ́ tí mo kọlu olúkúlùkù àkọ́bí ní ilẹ̀ Íjíbítì+ ni mo sọ wọ́n di mímọ́ fún ara mi.+ 18  Èmi yóò sì mú àwọn ọmọ Léfì dípò gbogbo àkọ́bí láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 19  Èmi yóò sì fi àwọn ọmọ Léfì fún Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹni tí a fi fúnni láti àárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú àgọ́ ìpàdé+ àti láti máa ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí ìyọnu àjàkálẹ̀ má bàa ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ nítorí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sún mọ́ ibi mímọ́.” 20  Mósè àti Áárónì àti gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bẹ́ẹ̀ sí àwọn ọmọ Léfì. Ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Jèhófà ti pa láṣẹ fún Mósè ní ti àwọn ọmọ Léfì, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe sí wọn. 21  Nítorí náà, àwọn ọmọ Léfì wẹ ara wọn mọ́ gaara,+ wọ́n sì fọ aṣọ wọn, lẹ́yìn èyí tí Áárónì mú kí wọ́n lọ síwá-sẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fífì níwájú Jèhófà.+ Lẹ́yìn náà, Áárónì ṣe ètùtù fún wọn láti wẹ̀ wọ́n mọ́.+ 22  Kété lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ọmọ Léfì wọlé láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn nínú àgọ́ ìpàdé níwájú Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀.+ Gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè nípa àwọn ọmọ Léfì, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe sí wọn. 23  Wàyí o, Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: 24  “Èyí ni ohun tí ó kan àwọn ọmọ Léfì: Láti ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sókè ni yóò wá láti wọnú àwùjọ ẹgbẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn àgọ́ ìpàdé. 25  Ṣùgbọ́n lẹ́yìn àádọ́ta ọdún ni yóò fẹ̀yìn tì kúrò nínú àwùjọ ẹgbẹ́ aṣiṣẹ́ ìsìn, kì yóò sì tún sìn mọ́. 26  Kí ó sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ nínú àgọ́ ìpàdé ní bíbójútó iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe náà, ṣùgbọ́n kí ó má ṣe iṣẹ́ ìsìn kankan. Ní ìbámu pẹ̀lú èyí ni kí o ṣe sí àwọn ọmọ Léfì nínú iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe wọn.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé