Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Númérì 7:1-89

7  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé ní ọjọ́ tí Mósè parí gbígbé àgọ́ ìjọsìn+ nà ró ni ó wá bẹ̀rẹ̀ sí fòróró yàn án,+ tí ó sì sọ ọ́ di mímọ́ àti gbogbo ohun èlò inú rẹ̀ àti pẹpẹ àti gbogbo nǹkan èlò rẹ̀. Báyìí ni ó fòróró yàn wọ́n, ó sì sọ wọ́n di mímọ́.+  Lẹ́yìn náà, àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì,+ olórí ilé àwọn baba wọn, mú ọrẹ-ẹ̀bùn wá,+ nítorí tí wọ́n jẹ́ ìjòyè àwọn ẹ̀yà náà, tí wọ́n sì ń dúró fún àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀,  wọ́n sì kó ọrẹ ẹbọ wọn wá síwájú Jèhófà, kẹ̀kẹ́ mẹ́fà tí a bò lórí àti màlúù méjì lá, kẹ̀kẹ́ kan fún àwọn ìjòyè méjì  àti akọ màlúù kan fún ẹnì kọ̀ọ̀kan; wọ́n sì kó wọn wá síwájú àgọ́.  Látàrí èyí, Jèhófà wí fún Mósè pé:  “Gbà wọ́n lọ́wọ́ wọn, níwọ̀n bí wọn yóò ti wà fún ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn àgọ́ ìpàdé, kí o sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ Léfì, olúkúlùkù ní ìwọ̀n iṣẹ́ ìsìn tirẹ̀.”  Nítorí náà, Mósè gba àwọn kẹ̀kẹ́ àti màlúù náà, ó sì kó wọ́n fún àwọn ọmọ Léfì.  Kẹ̀kẹ́ méjì  àti màlúù mẹ́rin ni ó kó fún àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì ní ìwọ̀n iṣẹ́ ìsìn wọn,+  kẹ̀kẹ́ mẹ́rin àti màlúù mẹ́jọ ni ó sì kó fún àwọn ọmọ Mérárì ní ìwọ̀n iṣẹ́ ìsìn wọn,+ ní ìkáwọ́ Ítámárì ọmọkùnrin Áárónì àlùfáà.+  Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Kóhátì ni kò fún ní nǹkan kan, nítorí pé iṣẹ́ ìsìn ibi mímọ́ wà lọ́rùn wọn.+ Èjì ká ni wọn fi ń gbé tiwọn.+ 10  Wàyí o, àwọn ìjòyè náà mú ọrẹ-ẹ̀bùn wọn wá sí ibi ayẹyẹ ṣíṣí+ pẹpẹ ní ọjọ́ tí a fòróró yàn án, àwọn ìjòyè náà sì bẹ̀rẹ̀ sí mú ọrẹ ẹbọ wọn wá síwájú pẹpẹ. 11  Nítorí náà, Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Ìjòyè kan ní ọjọ́ kan àti ìjòyè mìíràn ní ọjọ́ mìíràn ni ọ̀nà tí wọn yóò gbà máa mú ọrẹ ẹbọ wọn wá fún ayẹyẹ ṣíṣí pẹpẹ náà.”+ 12  Wàyí o, ẹni tí ó mú ọrẹ ẹbọ rẹ̀ wá ní ọjọ́ àkọ́kọ́ ni Náṣónì+ ọmọkùnrin Ámínádábù ti ẹ̀yà Júdà. 13  Ọrẹ ẹbọ rẹ̀ sì jẹ́ àwo ìjẹun fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì, àwokòtò fàdákà kan tí ó jẹ́ àádọ́rin ṣékélì gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́,+ tí méjèèjì  kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ fún ọrẹ ẹbọ ọkà;+ 14  ife wúrà kan tí ó jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí ó kún fún tùràrí;+ 15  ẹgbọrọ akọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan ọlọ́dún kan, fún ọrẹ ẹbọ sísun;+ 16  ọmọ ewúrẹ́ kan fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+ 17  àti fún ẹbọ ìdàpọ̀,+ màlúù méjì , àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan. Èyí ni ọrẹ ẹbọ Náṣónì ọmọkùnrin Ámínádábù.+ 18  Ní ọjọ́ kejì , Nétánélì+ ọmọkùnrin Súárì, ìjòyè Ísákárì, mú ọrẹ-ẹ̀bùn wá. 19  Gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ rẹ̀, ó mú àwopọ̀kọ́ fàdákà kan wá, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì, àwokòtò fàdákà kan tí ó jẹ́ àádọ́rin ṣékélì gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́, tí méjèèjì  kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ fún ọrẹ ẹbọ ọkà;+ 20  ife wúrà kan tí ó jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí ó kún fún tùràrí; 21  ẹgbọrọ akọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan ọlọ́dún kan, fún ọrẹ ẹbọ sísun;+ 22  ọmọ ewúrẹ́ kan fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+ 23  àti fún ẹbọ ìdàpọ̀,+ màlúù méjì , àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan. Èyí ni ọrẹ ẹbọ Nétánélì ọmọkùnrin Súárì. 24  Ọjọ́ kẹta ni ti ìjòyè àwọn ọmọ Sébúlúnì, Élíábù+ ọmọkùnrin Hélónì. 25  Ọrẹ ẹbọ rẹ̀ jẹ́ àwopọ̀kọ́ fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì, àwokòtò fàdákà kan tí ó jẹ́ àádọ́rin ṣékélì gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́, tí méjèèjì  kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ fún ọrẹ ẹbọ ọkà; 26  ife wúrà kan tí ó jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí ó kún fún tùràrí; 27  ẹgbọrọ akọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan ọlọ́dún kan, fún ọrẹ ẹbọ sísun;+ 28  ọmọ ewúrẹ́ kan fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+ 29  àti fún ẹbọ ìdàpọ̀,+ màlúù méjì , àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan. Èyí ni ọrẹ ẹbọ Élíábù ọmọkùnrin Hélónì.+ 30  Ọjọ́ kẹrin ni ti ìjòyè àwọn ọmọkùnrin Rúbẹ́nì, Élísúrì+ ọmọkùnrin Ṣédéúrì. 31  Ọrẹ ẹbọ rẹ̀ jẹ́ àwopọ̀kọ́ fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì, àwokòtò fàdákà kan tí ó jẹ́ àádọ́rin ṣékélì gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́, tí méjèèjì  kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ fún ọrẹ ẹbọ ọkà;+ 32  ife wúrà kan tí ó jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí ó kún fún tùràrí; 33  ẹgbọrọ akọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan ọlọ́dún kan, fún ọrẹ ẹbọ sísun;+ 34  ọmọ ewúrẹ́ kan fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+ 35  àti fún ẹbọ ìdàpọ̀,+ màlúù méjì , àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan. Èyí ni ọrẹ ẹbọ Élísúrì ọmọkùnrin Ṣédéúrì.+ 36  Ọjọ́ karùn-ún ni ti ìjòyè àwọn ọmọ Síméónì, Ṣẹ́lúmíẹ́lì+ ọmọkùnrin Súríṣádáì. 37  Ọrẹ ẹbọ rẹ̀ jẹ́ àwopọ̀kọ́ fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì, àwokòtò fàdákà kan tí ó jẹ́ àádọ́rin ṣékélì gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́, tí méjèèjì  kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ fún ọrẹ ẹbọ ọkà;+ 38  ife wúrà kan tí ó jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí ó kún fún tùràrí; 39  ẹgbọrọ akọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan ọlọ́dún kan, fún ọrẹ ẹbọ sísun;+ 40  ọmọ ewúrẹ́ kan fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+ 41  àti fún ẹbọ ìdàpọ̀,+ màlúù méjì , àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan. Èyí ni ọrẹ ẹbọ Ṣẹ́lúmíẹ́lì ọmọkùnrin Súríṣádáì.+ 42  Ọjọ́ kẹfà ni ti ìjòyè àwọn ọmọ Gádì, Élíásáfù+ ọmọkùnrin Déúélì. 43  Ọrẹ ẹbọ rẹ̀ jẹ́ àwopọ̀kọ́ fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì, àwokòtò fàdákà kan tí ó jẹ́ àádọ́rin ṣékélì gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́, tí méjèèjì  kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ fún ọrẹ ẹbọ ọkà;+ 44  ife wúrà kan tí ó jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí ó kún fún tùràrí;+ 45  ẹgbọrọ akọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan ọlọ́dún kan, fún ọrẹ ẹbọ sísun;+ 46  ọmọ ewúrẹ́ kan fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+ 47  àti fún ẹbọ ìdàpọ̀,+ màlúù méjì , àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan. Èyí ni ọrẹ ẹbọ Élíásáfù ọmọkùnrin Déúélì.+ 48  Ọjọ́ keje ni ti ìjòyè àwọn ọmọ Éfúráímù, Élíṣámà+ ọmọkùnrin Ámíhúdù. 49  Ọrẹ ẹbọ rẹ̀ jẹ́ àwopọ̀kọ́ fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì, àwokòtò fàdákà kan tí ó jẹ́ àádọ́rin ṣékélì gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́, tí méjèèjì  kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ fún ọrẹ ẹbọ ọkà;+ 50  ife wúrà kan tí ó jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí ó kún fún tùràrí; 51  ẹgbọrọ akọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan ọlọ́dún kan, fún ọrẹ ẹbọ sísun;+ 52  ọmọ ewúrẹ́ kan fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+ 53  àti fún ẹbọ ìdàpọ̀,+ màlúù méjì , àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan. Èyí ni ọrẹ ẹbọ Élíṣámà ọmọkùnrin Ámíhúdù.+ 54  Ọjọ́ kẹjọ ni ti ìjòyè àwọn ọmọ Mánásè, Gàmálíẹ́lì+ ọmọkùnrin Pédásúrì. 55  Ọrẹ ẹbọ rẹ̀ jẹ́ àwopọ̀kọ́ fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì, àwokòtò fàdákà kan tí ó jẹ́ àádọ́rin ṣékélì gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́, tí méjèèjì  kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ fún ọrẹ ẹbọ ọkà;+ 56  ife wúrà kan tí ó jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí ó kún fún tùràrí;+ 57  ẹgbọrọ akọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan ọlọ́dún kan, fún ọrẹ ẹbọ sísun;+ 58  ọmọ ewúrẹ́ kan fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+ 59  àti fún ẹbọ ìdàpọ̀,+ màlúù méjì , àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan. Èyí ni ọrẹ ẹbọ Gàmálíẹ́lì ọmọkùnrin Pédásúrì.+ 60  Ọjọ́ kẹsàn-án ni ti ìjòyè+ àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì, Ábídánì+ ọmọkùnrin Gídíónì. 61  Ọrẹ ẹbọ rẹ̀ jẹ́ àwopọ̀kọ́ fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì, àwokòtò fàdákà kan tí ó jẹ́ àádọ́rin ṣékélì gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́, tí méjèèjì  kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ fún ọrẹ ẹbọ ọkà;+ 62  ife wúrà kan tí ó jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí ó kún fún tùràrí; 63  ẹgbọrọ akọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan ọlọ́dún kan, fún ọrẹ ẹbọ sísun;+ 64  ọmọ ewúrẹ́ kan fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+ 65  àti fún ẹbọ ìdàpọ̀,+ màlúù méjì , àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan. Èyí ni ọrẹ ẹbọ Ábídánì ọmọkùnrin Gídíónì.+ 66  Ọjọ́ kẹwàá ni ti ìjòyè àwọn ọmọ Dánì, Áhíésérì+ ọmọkùnrin Ámíṣádáì. 67  Ọrẹ ẹbọ rẹ̀ jẹ́ àwopọ̀kọ́ fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì, àwokòtò fàdákà kan tí ó jẹ́ àádọ́rin ṣékélì gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́, tí méjèèjì  kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ fún ọrẹ ẹbọ ọkà;+ 68  ife wúrà kan tí ó jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí ó kún fún tùràrí; 69  ẹgbọrọ akọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan ọlọ́dún kan, fún ọrẹ ẹbọ sísun;+ 70  ọmọ ewúrẹ́ kan fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+ 71  àti fún ẹbọ ìdàpọ̀,+ màlúù méjì , àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan. Èyí ni ọrẹ ẹbọ Áhíésérì ọmọkùnrin Ámíṣádáì.+ 72  Ọjọ́ kọkànlá ni ti ìjòyè àwọn ọmọ Áṣérì, Págíẹ́lì+ ọmọkùnrin Ókíránì. 73  Ọrẹ ẹbọ rẹ̀ jẹ́ àwopọ̀kọ́ fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì, àwokòtò fàdákà kan tí ó jẹ́ àádọ́rin ṣékélì gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́, tí méjèèjì  kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ fún ọrẹ ẹbọ ọkà;+ 74  ife wúrà kan tí ó jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí ó kún fún tùràrí;+ 75  ẹgbọrọ akọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan ọlọ́dún kan, fún ọrẹ ẹbọ sísun;+ 76  ọmọ ewúrẹ́ kan fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+ 77  àti fún ẹbọ ìdàpọ̀,+ màlúù méjì , àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan. Èyí ni ọrẹ ẹbọ Págíẹ́lì ọmọkùnrin Ókíránì.+ 78  Ọjọ́ kejì lá ni ti ìjòyè àwọn ọmọ Náfútálì, Áhírà+ ọmọkùnrin Énánì. 79  Ọrẹ ẹbọ rẹ̀ jẹ́ àwopọ̀kọ́ fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì, àwokòtò fàdákà kan tí ó jẹ́ àádọ́rin ṣékélì gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́, tí méjèèjì  kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ fún ọrẹ ẹbọ ọkà;+ 80  ife wúrà kan tí ó jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí ó kún fún tùràrí;+ 81  ẹgbọrọ akọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan ọlọ́dún kan, fún ọrẹ ẹbọ sísun;+ 82  ọmọ ewúrẹ́ kan fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+ 83  àti fún ẹbọ ìdàpọ̀,+ màlúù méjì , àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan. Èyí ni ọrẹ ẹbọ Áhírà ọmọkùnrin Énánì.+ 84  Èyí ni ọrẹ ẹbọ ayẹyẹ ṣíṣí+ pẹpẹ ní ọjọ́ tí a fòróró yàn án, ní ìhà ọ̀dọ̀ àwọn ìjòyè+ Ísírẹ́lì: àwopọ̀kọ́+ fàdákà méjì lá, àwokòtò fàdákà méjì lá, ife wúrà méjì lá; 85  àwopọ̀kọ́ fàdákà kọ̀ọ̀kan jẹ́ àádóje ṣékélì, àwokòtò kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ àádọ́rin, gbogbo fàdákà àwọn ohun èlò jẹ́ egbèjì lá ṣékélì gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́;+ 86  àwọn ife+ wúrà méjì lá náà tí ó kún fún tùràrí jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá fún ife kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́, gbogbo wúrà àwọn ife náà jẹ́ ọgọ́fà ṣékélì; 87  gbogbo màlúù fún ọrẹ ẹbọ sísun+ jẹ́ akọ màlúù méjì lá, àgbò méjì lá, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méjì lá tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan àti àwọn ọrẹ ẹbọ ọkà+ wọn, àti àwọn ọmọ ewúrẹ́ méjì lá fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+ 88  gbogbo màlúù fún ẹbọ ìdàpọ̀+ sì jẹ́ akọ màlúù mẹ́rìnlélógún, ọgọ́ta àgbò, ọgọ́ta òbúkọ, ọgọ́ta akọ ọ̀dọ́ àgùntàn tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan. Èyí ni ọrẹ ẹbọ ayẹyẹ ṣíṣí+ pẹpẹ náà lẹ́yìn fífòróró yàn án.+ 89  Wàyí o, nígbàkigbà tí Mósè bá lọ sínú àgọ́ ìpàdé láti bá a sọ̀rọ̀,+ nígbà náà, òun yóò gbọ́ ohùn tí ń bá a sọ̀rọ̀ pọ̀ láti òkè ìbòrí+ náà tí ó wà lórí àpótí gbólóhùn ẹ̀rí, láti àárín àwọn kerubu+ méjèèjì ; yóò sì bá a sọ̀rọ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé