Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Númérì 6:1-27

6  Jèhófà sì bá Mósè sọ̀rọ̀ síwájú sí i, pé:  “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan jẹ́ àkànṣe ẹ̀jẹ́ láti gbé gẹ́gẹ́ bí Násírì+ fún Jèhófà,  kí ó yẹra fún wáìnì àti ọtí tí ń pani. Kí ó má mu ọtí kíkan tí a fi wáìnì ṣe tàbí ọtí kíkan tí a fi ọtí tí ń pani+ ṣe, tàbí kí ó mu ohun olómi èyíkéyìí tí a fi èso àjàrà ṣe, tàbí kí ó jẹ èso àjàrà yálà tútù tàbí gbígbẹ.  Ní gbogbo ọjọ́ jíjẹ́ Násírì rẹ̀ kí ó má jẹ ohunkóhun tí a fi àjàrà wáìnì ṣe rárá, láti orí àwọn èso àjàrà aláìpọ́n títí dórí èèpo rẹ̀.  “‘Ní gbogbo ọjọ́ ẹ̀jẹ́ ipò Násírì rẹ̀, kí abẹ fẹ́lẹ́ kankan má kọjá ní orí+ rẹ̀; títí ọjọ́ tí a ó fi yà á sọ́tọ̀ fún Jèhófà yóò fi pé, kí ó jẹ́ mímọ́ nípa jíjẹ́ kí ìdìpọ̀+ irun orí rẹ̀ hù.  Ní gbogbo ọjọ́ yíya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Jèhófà, kò gbọ́dọ̀ sún mọ òkú ọkàn+ èyíkéyìí.  Òun kò lè tìtorí baba rẹ̀ pàápàá tàbí ìyá rẹ̀ tàbí arákùnrin rẹ̀ tàbí arábìnrin rẹ̀ sọ ara rẹ̀ di ẹlẹ́gbin nígbà tí wọ́n bá kú,+ nítorí pé àmì jíjẹ́ Násírì rẹ̀ fún Ọlọ́run rẹ̀ wà ní orí rẹ̀.  “‘Ó jẹ́ mímọ́ lójú Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ jíjẹ́ Násírì rẹ̀.  Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnikẹ́ni tí ń kú lọ ṣàdédé kú lójijì lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀+ tí ó fi sọ orí ipò jíjẹ́ Násírì rẹ̀ di ẹlẹ́gbin, nígbà náà, kí ó fá+ orí rẹ̀ ní ọjọ́ fífi ìdí ìwẹ̀mọ́gaara rẹ̀ múlẹ̀. Kí ó fá a ní ọjọ́ keje. 10  Ní ọjọ́ kẹjọ, kí ó sì mú oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì wá fún àlùfáà sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.+ 11  Kí àlùfáà sì ṣe ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ àti ìkejì gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun,+ kí ó sì ṣe ètùtù fún un, níwọ̀n bí ó ti ṣẹ̀ nítorí òkú ọkàn náà. Nígbà náà ni kí ó sọ orí rẹ̀ di mímọ́ ní ọjọ́ yẹn. 12  Kí ó sì gbé gẹ́gẹ́ bí Násírì+ fún Jèhófà ní àwọn ọjọ́ jíjẹ́ Násírì rẹ̀, kí ó sì mú ẹgbọrọ àgbò ọlọ́dún kan wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi;+ àwọn ọjọ́ ti àtẹ̀yìnwá ni a kì yóò sì kà nítorí pé ó sọ jíjẹ́ Násírì rẹ̀ di ẹlẹ́gbin. 13  “‘Wàyí o, èyí ni òfin nípa Násírì: Ní ọjọ́ tí àwọn ọjọ́ jíjẹ́ Násírì rẹ̀ bá pé,+ a óò mú un wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 14  Òun yóò sì mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ rẹ̀ fún Jèhófà, ẹgbọrọ àgbò ọlọ́dún kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun+ àti abo ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ àti àgbò kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìdàpọ̀,+ 15  àti apẹ̀rẹ̀ àkàrà aláìwú onírìísí òrùka ti ìyẹ̀fun kíkúnná,+ tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́,+ àti àdíngbẹ àkàrà aláìwú pẹlẹbẹ tí a fi òróró pa,+ àti ọrẹ ẹbọ ọkà+ wọn àti ọrẹ ẹbọ ohun mímu wọn.+ 16  Kí àlùfáà sì gbé wọn wá síwájú Jèhófà, kí ó sì rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ sísun+ rẹ̀. 17  Yóò sì fi àgbò náà rúbọ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ+ ìdàpọ̀ sí Jèhófà pa pọ̀ pẹ̀lú apẹ̀rẹ̀ àkàrà aláìwú náà; kí àlùfáà sì fi ọrẹ ẹbọ ọkà+ rẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ ohun mímu rẹ̀ rúbọ. 18  “‘Kí Násírì náà sì fá+ orí ipò jíjẹ́ Násírì rẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, kí ó sì mú irun orí ipò jíjẹ́ Násírì rẹ̀, kí ó sì fi í sórí iná tí ó wà lábẹ́ ẹbọ ìdàpọ̀. 19  Kí àlùfáà sì mú èjì ká tí a bọ̀+ lára àgbò náà àti àkàrà aláìwú kan tí ó ní ìrísí òrùka láti inú apẹ̀rẹ̀ náà, àti àdíngbẹ+ àkàrà aláìwú pẹlẹbẹ kan, kí ó sì kó wọn lé àtẹ́lẹwọ́ Násírì náà lẹ́yìn tí ó ti fá àmì jíjẹ́ Násírì rẹ̀ kúrò. 20  Kí àlùfáà sì fì wọ́n síwá-sẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fífì níwájú Jèhófà.+ Ohun mímọ́ ni fún àlùfáà náà, pa pọ̀ pẹ̀lú igẹ̀+ ọrẹ ẹbọ fífì náà àti ẹsẹ̀ ọrẹ+ náà. Lẹ́yìn ìgbà náà, Násírì náà lè mu wáìnì.+ 21  “‘Èyí ni òfin nípa Násírì+ ẹni tí ó jẹ́jẹ̀ẹ́—ọrẹ ẹbọ rẹ̀ sí Jèhófà lórí jíjẹ́ Násírì rẹ̀, yàtọ̀ sí èyí tí agbára rẹ̀ gbé. Ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tí ó bá jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kí ó ṣe nítorí òfin jíjẹ́ Násírì rẹ̀.’” 22  Lẹ́yìn náà, Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: 23  “Bá Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sọ̀rọ̀, pé, ‘Báyìí ni kí ẹ ṣe máa súre+ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ní wíwí fún wọn pé: 24  “Kí Jèhófà bù kún ọ,+ kí ó sì pa ọ́ mọ́.+ 25  Kí Jèhófà mú kí ojú rẹ̀ tàn sí ọ,+ kí ó sì ṣe ojú rere sí ọ.+ 26  Kí Jèhófà gbé ojú rẹ̀ sókè sí ọ,+ kí ó sì fi àlàáfíà fún ọ.”’+ 27  Kí wọ́n sì fi orúkọ mi+ sára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí èmi fúnra mi lè bù kún wọn.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé