Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Númérì 5:1-31

5  Jèhófà sì bá Mósè sọ̀rọ̀ síwájú sí i, pé:  “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n rán gbogbo àwọn adẹ́tẹ̀+ jáde kúrò ní ibùdó àti gbogbo àwọn tí ó ní àsunjáde+ àti gbogbo àwọn tí ọkàn tí ó ti di olóògbé+ ti sọ di aláìmọ́.  Yálà ọkùnrin ni tàbí obìnrin ni kí ẹ rán wọn jáde. Kí ẹ rán wọn jáde sí òde ibùdó,+ kí wọ́n má bàa kó èérí bá+ ibùdó àwọn ẹni tí mo pàgọ́ sí+ àárín wọn.”  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bẹ́ẹ̀, àní ní rírán wọn sí òde ibùdó. Gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ fún Mósè gan-an, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe.  Jèhófà sì ń bá a lọ láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé:  “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ní ti ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n dá èyíkéyìí nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ aráyé ní híhu ìwà àìṣòótọ́ kan sí Jèhófà, ọkàn yẹn ti jẹ̀bi pẹ̀lú.+  Kí wọ́n sì jẹ́wọ́+ ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí wọ́n ti dá, kí ó sì dá iye ẹ̀bi rẹ̀ padà ní ojú-owó rẹ̀, ní fífi ìdá márùn-ún rẹ̀ kún un pẹ̀lú,+ kí ó sì fi í fún ẹni náà tí ó ṣe àìtọ́ sí.  Ṣùgbọ́n bí ẹni tí a mẹ́nu kàn kẹ́yìn yìí kò bá ní ìbátan tí ó sún mọ́ ọn tí a óò dá iye ẹ̀bi náà padà fún, iye ẹ̀bi náà tí a ń dá padà fún Jèhófà jẹ́ ti àlùfáà, àyàfi àgbò ètùtù èyí tí òun yóò fi ṣe ètùtù fún un.+  “‘Àti olúkúlùkù ọrẹ+ nínú gbogbo ohun mímọ́+ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èyí tí wọn yóò mú wá fún àlùfáà, yóò di tirẹ̀.+ 10  Àwọn ohun mímọ́ olúkúlùkù yóò sì máa jẹ́ tirẹ̀. Ohun yòówù tí olúkúlùkù bá fi fún àlùfáà, ìyẹn ni yóò di tirẹ̀.’” 11  Jèhófà sì ń bá a lọ láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: 12  “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé aya ọkùnrin èyíkéyìí yapa ní ti pé ó hu ìwà àìṣòótọ́ kan sí i,+ 13  tí ọkùnrin mìíràn sì sùn tì í ní ti gidi, tí ó sì da àtọ̀,+ tí ó sì ti fara sin kúrò ní ojú ọkọ rẹ̀,+ tí kò sì hàn síta, tí obìnrin náà, ní tirẹ̀, sì ti sọ ara rẹ̀ di ẹlẹ́gbin ṣùgbọ́n tí kò sí ẹlẹ́rìí kankan lòdì sí i, tí a kò sì tíì mú òun fúnra rẹ̀; 14  tí ẹ̀mí owú+ sì ti dé sí ọkùnrin náà, tí ó sì wá ń fura sí ìṣòtítọ́ aya rẹ̀, tí obìnrin náà sì ti sọ ara rẹ̀ di ẹlẹ́gbin ní tòótọ́, tàbí tí ẹ̀mí owú ti dé sí ọkùnrin náà, tí ó sì wá ń fura sí ìṣòtítọ́ aya rẹ̀, ṣùgbọ́n tí obìnrin náà kò tíì sọ ara rẹ̀ di ẹlẹ́gbin ní tòótọ́; 15  nígbà náà, kí ọkùnrin náà mú aya rẹ̀ wá sọ́dọ̀ àlùfáà+ kí ó sì mú ọrẹ ẹbọ obìnrin náà wá pẹ̀lú rẹ̀, ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà ìyẹ̀fun ọkà bálì. Kí ó má da òróró sórí rẹ̀ tàbí kí ó fi oje igi tùràrí+ sórí rẹ̀, nítorí pé ọrẹ ẹbọ ọkà owú ni, ọrẹ ẹbọ ọkà ìrántí tí ń mú ìṣìnà wá sí ìrántí. 16  “‘Kí àlùfáà sì mú un wá síwájú, kí ó sì mú un dúró níwájú Jèhófà.+ 17  Kí àlùfáà sì bu omi mímọ́ sínú ohun èlò kan tí a fi amọ̀ ṣe, àlùfáà náà yóò sì bu díẹ̀ lára ekuru tí ó bá wà ní ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀ àgọ́ àjọ, kí ó sì fi sínú omi náà. 18  Kí àlùfáà sì mú kí obìnrin náà dúró níwájú Jèhófà, kí ó sì tú irun orí obìnrin náà, kí ó sì gbé ọrẹ ẹbọ ọkà ìrántí lé àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, èyíinì ni, ọrẹ ẹbọ ọkà owú,+ kí omi kíkorò tí ń mú ègún+ wá sì wà ní ọwọ́ àlùfáà. 19  “‘Kí àlùfáà sì mú kí ó búra, kí ó sì wí fún obìnrin náà pé: “Bí ọkùnrin kankan kò bá sùn tì ọ́ àti nígbà tí o wà lábẹ́ ọkọ rẹ+ bí o kò bá tíì yapa sínú ohun àìmọ́ èyíkéyìí, kí o bọ́ lọ́wọ́ ìyọrísí omi kíkorò yìí tí ń mú ègún wá. 20  Ṣùgbọ́n ìwọ, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o ti yapa nígbà tí o wà lábẹ́ ọkọ rẹ,+ bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé o ti sọ ara rẹ di ẹlẹ́gbin, tí ọkùnrin kan sì ti fi àtọ̀+ tí ó dà lára rẹ̀ sínú rẹ, yàtọ̀ sí ọkọ rẹ,—” 21  Wàyí o, kí àlùfáà mú kí obìnrin náà fi ìbúra tí ó mú ègún+ lọ́wọ́ búra, kí àlùfáà sì wí fún obìnrin náà pé: “Kí Jèhófà ṣe ọ́ ní ẹni tí ó wà fún ègún àti ìbúra ní àárín àwọn ènìyàn rẹ nípa jíjẹ́ tí Jèhófà yóò jẹ́ kí itan+ rẹ joro, kí ikùn rẹ sì wú. 22  Kí omi yìí tí ń mú ègún wá sì wọnú ìfun rẹ lọ láti mú kí ikùn rẹ wú, kí itan rẹ sì joro.” Kí obìnrin náà sì fèsì pé: “Àmín! Àmín!” 23  “‘Kí àlùfáà sì kọ àwọn ègún wọ̀nyí sínú ìwé,+ kí ó sì nù+ wọ́n sínú omi kíkorò náà. 24  Kí ó sì mú kí obìnrin náà mu omi kíkorò tí ń mú ègún+ wá, kí omi náà tí ń mú ègún wá sì wọnú rẹ̀ lọ gẹ́gẹ́ bí nǹkan kíkorò. 25  Kí àlùfáà sì gba ọrẹ ẹbọ+ ọkà owú lọ́wọ́ obìnrin náà, kí ó sì fi ọrẹ ẹbọ ọkà náà síwá-sẹ́yìn níwájú Jèhófà, kí ó sì gbé e sún mọ́ pẹpẹ. 26  Kí àlùfáà sì mú díẹ̀ lára ọrẹ ẹbọ ọkà náà gẹ́gẹ́ bí aránnilétí+ rẹ̀, kí ó sì mú un rú èéfín lórí pẹpẹ, lẹ́yìn ìgbà náà, kí ó sì mú kí obìnrin náà mu omi náà. 27  Nígbà tí ó bá ti mú kí obìnrin náà mu omi náà, yóò sì ṣẹlẹ̀ pé bí ó bá ti sọ ara rẹ̀ di ẹlẹ́gbin ní ti pé ó hu ìwà àìṣòótọ́ kan sí ọkọ rẹ̀,+ nígbà náà, omi tí ń mú ègún wá náà yóò wọnú rẹ̀ lọ gẹ́gẹ́ bí nǹkan kíkorò, ikùn rẹ̀ yóò sì wú, itan rẹ̀ yóò sì joro, obìnrin náà yóò sì di ẹni ègún láàárín àwọn ènìyàn rẹ̀.+ 28  Bí ó ti wù kí ó rí, bí obìnrin náà kò bá sọ ara rẹ̀ di ẹlẹ́gbin ṣùgbọ́n tí ó mọ́, nígbà náà, yóò bọ́ lọ́wọ́ irú ìyà bẹ́ẹ̀;+ àtọ̀ yóò sì mú un lóyún. 29  “‘Èyí ni òfin nípa owú,+ nígbà tí obìnrin kan bá yapa+ nígbà tí ó wà lábẹ́ ọkọ rẹ̀,+ tí ó sì sọ ara rẹ̀ di ẹlẹ́gbin, 30  tàbí nínú ọ̀ràn ọkùnrin kan nígbà tí ẹ̀mí owú bá dé sí i, tí ó sì fura pé aya òun ṣe àìṣòótọ́; kí ó sì mú kí aya náà dúró níwájú Jèhófà, kí àlùfáà sì mú gbogbo òfin yìí ṣẹ sí i. 31  Ọkùnrin náà yóò sì jẹ́ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ ìṣìnà, ṣùgbọ́n aya yẹn yóò dáhùn fún ìṣìnà rẹ̀.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé