Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Númérì 4:1-49

4  Wàyí o, Jèhófà bá Mósè àti Áárónì sọ̀rọ̀, pé:  “Kí kíka iye àwọn ọmọ Kóhátì+ láti inú àwọn ọmọ Léfì wáyé, ní ìbámu pẹ̀lú ìdílé wọn ní ilé baba wọn,  láti ẹni ọgbọ̀n ọdún+ sókè sí ẹni àádọ́ta ọdún,+ gbogbo àwọn tí ń wọnú àwùjọ aṣiṣẹ́ ìsìn+ láti ṣe iṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé. 4  “Èyí ni iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọ Kóhátì nínú àgọ́ ìpàdé.+ Ó jẹ́ ohun mímọ́ jù lọ:  Kí Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì wọlé nígbà tí ibùdó náà bá ń lọ, kí wọ́n sì tú aṣọ ìkélé+ àtabojú kúrò, kí wọ́n sì fi í bo àpótí+ gbólóhùn ẹ̀rí.  Kí wọ́n sì fi ìbòrí awọ séálì+ bò ó, kí wọ́n sì na aṣọ tí ó jẹ́ ògédé àwọ̀ búlúù bò ó lókè, kí wọ́n sì ti ọ̀pá+ rẹ̀ bọ̀ ọ́.  “Wọn yóò sì na aṣọ aláwọ̀ búlúù bo tábìlì+ búrẹ́dì àfihàn, kí wọ́n sì kó àwọn àwo ìjẹun+ àti àwọn ife àti àwọn àwokòtò+ àti àwọn orù ọrẹ ẹbọ ohun mímu sórí rẹ̀; kí búrẹ́dì ìgbà gbogbo+ sì máa bá a lọ láti wà lórí rẹ̀.  Kí wọ́n sì na aṣọ aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì+ bò wọ́n, kí wọ́n sì fi ìbòrí awọ séálì+ bò ó, kí wọ́n sì ti ọ̀pá+ rẹ̀ bọ̀ ọ́.  Kí wọ́n sì mú aṣọ aláwọ̀ búlúù, kí wọ́n sì fi bo ọ̀pá fìtílà+ orísun ìmọ́lẹ̀ àti àwọn fìtílà+ rẹ̀ àti àwọn ẹ̀mú+ rẹ̀ àti àwọn ìkóná+ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ohun èlò+ rẹ̀ fún òróró èyí tí wọ́n máa fi ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ déédéé nídìí rẹ̀. 10  Kí wọ́n sì kó òun àti gbogbo nǹkan èlò rẹ̀ sínú ìbòrí awọ séálì,+ kí wọ́n sì gbé e sórí ọ̀pá gbọọrọ kan. 11  Àti pé, orí pẹpẹ+ wúrà náà ni wọn yóò na aṣọ aláwọ̀ búlúù kan bò, kí wọ́n sì fi ìbòrí awọ séálì+ bò ó, kí wọ́n sì ti ọ̀pá+ rẹ̀ bọ̀ ọ́. 12  Kí wọ́n sì mú gbogbo nǹkan èlò+ iṣẹ́ òjíṣẹ́ èyí tí wọ́n fi máa ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ déédéé nínú ibi mímọ́, kí wọ́n sì fi wọ́n sínú aṣọ aláwọ̀ búlúù, kí wọ́n sì fi ìbòrí awọ séálì+ bò wọ́n, kí wọ́n sì gbé wọn sórí ọ̀pá gbọọrọ kan. 13  “Kí wọ́n sì kó àwọn eérú ọlọ́ràá pẹpẹ+ dànù, kí wọ́n sì tẹ́ aṣọ irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró sórí rẹ̀. 14  Kí wọ́n sì kó gbogbo àwọn nǹkan èlò rẹ̀ èyí tí wọ́n fi máa ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ déédéé nídìí rẹ̀ sórí rẹ̀, àwọn ìkóná, àwọn àmúga àti àwọn ṣọ́bìrì àti àwọn àwokòtò, gbogbo nǹkan èlò pẹpẹ;+ kí wọ́n sì na ìbòrí awọ séálì bò ó lórí, kí wọ́n sì ti ọ̀pá+ rẹ̀ bọ̀ ọ́. 15  “Kí Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì parí bíbo ibi mímọ́+ náà àti gbogbo nǹkan èlò+ ibi mímọ́ nígbà tí ibùdó náà bá ń lọ, lẹ́yìn ìyẹn àwọn ọmọ Kóhátì yóò sì wọlé wá láti rù wọ́n,+ ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kan+ ibi mímọ́ kí wọ́n má bàa kú. Nǹkan wọ̀nyí ni ẹrù àwọn ọmọ Kóhátì nínú àgọ́ ìpàdé.+ 16  “Iṣẹ́ àbójútó+ Élíásárì ọmọkùnrin Áárónì àlùfáà sì jẹ́ lórí òróró+ orísun ìmọ́lẹ̀ àti tùràrí onílọ́fínńdà+ àti ọrẹ ẹbọ ọkà ìgbà gbogbo+ àti òróró àfiyanni,+ iṣẹ́ àbójútó gbogbo àgọ́ ìjọsìn àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀, èyíinì ni, ibi mímọ́ àti àwọn nǹkan èlò rẹ̀.” 17  Jèhófà tún bá Mósè àti Áárónì sọ̀rọ̀, pé: 18  “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ké ẹ̀yà àwọn ìdílé ọmọ Kóhátì+ kúrò láàárín àwọn ọmọ Léfì. 19  Ṣùgbọ́n ẹ ṣe èyí fún wọn kí wọ́n bàa lè máa wà láàyè nìṣó ní tòótọ́, kí wọ́n má bàa sì kú nítorí sísúnmọ́ àwọn ohun mímọ́ jù lọ.+ Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ yóò wọlé, kí wọ́n sì yan olúkúlùkù wọn sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ àti sí ẹrù rẹ̀. 20  Kí wọ́n má sì wọlé lọ wo àwọn ohun mímọ́ fún ìṣẹ́jú tí ó kéré jù lọ nínú àkókò, kí wọ́n sì wá tipa bẹ́ẹ̀ kú.”+ 21  Lẹ́yìn náà, Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: 22  “Kí kíka iye àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì+ wáyé, bẹ́ẹ̀ ni, àwọn, ní ìbámu pẹ̀lú ilé baba wọn gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn. 23  Láti ẹni ọgbọ̀n ọdún sókè sí ẹni àádọ́ta ọdún ni ìwọ yóò forúkọ wọn sílẹ̀,+ gbogbo àwọn tí wọ́n wá láti wọnú àwùjọ aṣiṣẹ́ ìsìn láti ṣe iṣẹ́ ìsìn nínú àgọ́ ìpàdé. 24  Èyí ni iṣẹ́ ìsìn ìdílé àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì nípa sísìn àti nípa rírẹrù.+ 25  Wọn yóò sì ru aṣọ àgọ́+ ti àgọ́ ìjọsìn àti ti àgọ́ ìpàdé,+ ìbòrí+ rẹ̀ àti ìbòrí+ awọ séálì tí ó wà lókè lórí rẹ̀, àti àtabojú+ ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, 26  àti àwọn àsokọ́+ àgbàlá àti àtabojú+ ẹnu ọ̀nà ti ẹnubodè àgbàlá tí ó yí àgọ́ àti pẹpẹ ká, àti àwọn okùn àgọ́ wọn àti gbogbo àwọn nǹkan èlò iṣẹ́ ìsìn wọn, àti gbogbo ohun tí a fi ń ṣiṣẹ́ déédéé. Bí wọn yóò ṣe máa sìn nìyí. 27  Nípa àṣẹ ìtọ́ni Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀+ ni kí gbogbo iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọkùnrin lára àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì+ di ṣíṣe ní ti gbogbo àwọn ẹrù wọn àti gbogbo iṣẹ́ ìsìn wọn, kí ẹ sì yan gbogbo ẹrù wọn fún wọn nípa iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe. 28  Èyí ni iṣẹ́ ìsìn ìdílé àwọn ọmọkùnrin lára àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì+ nínú àgọ́ ìpàdé, iṣẹ́ ìsìn àìgbọ́dọ̀máṣe wọn sì wà ní ìkáwọ́ Ítámárì+ ọmọkùnrin Áárónì àlùfáà. 29  “Ní ti àwọn ọmọ Mérárì,+ ìwọ yóò forúkọ wọn sílẹ̀ nípa ìdílé wọn nínú ilé baba wọn. 30  Láti ẹni ọgbọ̀n ọdún sókè sí ẹni àádọ́ta ọdún ni ìwọ yóò forúkọ wọn sílẹ̀, gbogbo àwọn tí ó wọnú àwùjọ aṣiṣẹ́ ìsìn láti ṣe iṣẹ́ ìsìn ti àgọ́ ìpàdé.+ 31  Èyí sì ni iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe wọn, ẹrù wọn,+ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ ìsìn wọn nínú àgọ́ ìpàdé: àwọn férémù+ àgọ́ ìjọsìn àti àwọn ọ̀pá ìdábùú+ rẹ̀ àti àwọn ọwọ̀n+ rẹ̀ àti àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀+ rẹ̀, 32  àti àwọn ọwọ̀n+ àgbàlá yíká-yíká àti àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀+ wọn àti àwọn ìkànlẹ̀+ àgọ́ wọn àti àwọn okùn àgọ́ wọn pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun ìṣiṣẹ́ wọn àti gbogbo iṣẹ́ ìsìn wọn. Ní ìbámu pẹ̀lú orúkọ wọn ni ìwọ yóò sì yan ohun ìṣiṣẹ́ náà èyí tí ó jẹ́ dandan fún wọn, gẹ́gẹ́ bí ẹrù wọn.+ 33  Èyí ni iṣẹ́ ìsìn ìdílé àwọn ọmọ Mérárì+ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ ìsìn wọn nínú àgọ́ ìpàdé, ní ìkáwọ́ Ítámárì ọmọkùnrin Áárónì àlùfáà.”+ 34  Mósè àti Áárónì àti àwọn ìjòyè+ àpéjọ náà sì bẹ̀rẹ̀ sí forúkọ àwọn ọmọkùnrin lára àwọn ọmọ Kóhátì+ sílẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìdílé wọn àti ní ìbámu pẹ̀lú ilé baba wọn, 35  láti ẹni ọgbọ̀n ọdún+ sókè sí àádọ́ta ọdún,+ gbogbo àwọn tí ó wọnú àwùjọ aṣiṣẹ́ ìsìn fún iṣẹ́ ìsìn nínú àgọ́ ìpàdé.+ 36  Àwọn tí a sì forúkọ wọn sílẹ̀ nípa ìdílé wọn wá jẹ́ àádọ́ta dín ní ẹgbẹ̀rìnlá.+ 37  Ìwọ̀nyí ni àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀+ nínú ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì, gbogbo àwọn tí ń sìn nínú àgọ́ ìpàdé, àwọn tí Mósè àti Áárónì forúkọ wọn sílẹ̀ nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà nípasẹ̀ Mósè. 38  Ní ti àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì+ ní ìbámu pẹ̀lú ìdílé wọn àti ní ìbámu pẹ̀lú ilé baba wọn, 39  láti ẹni ọgbọ̀n ọdún sókè sí àádọ́ta ọdún, gbogbo àwọn tí ó wọnú àwùjọ aṣiṣẹ́ ìsìn fún iṣẹ́ ìsìn nínú àgọ́ ìpàdé,+ 40  àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìdílé wọn, ní ìbámu pẹ̀lú ilé baba wọn, wá jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá ó lé ọgbọ̀n.+ 41  Ìwọ̀nyí ni àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ìdílé àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì, gbogbo àwọn tí ń sìn nínú àgọ́ ìpàdé, àwọn tí Mósè àti Áárónì forúkọ wọn sílẹ̀ nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà.+ 42  Ní ti àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ìdílé àwọn ọmọ Mérárì nípa ìdílé wọn, nípa ilé baba wọn, 43  láti ẹni ọgbọ̀n ọdún sókè sí ẹni àádọ́ta ọdún, gbogbo àwọn tí ó wọnú àwùjọ aṣiṣẹ́ ìsìn fún iṣẹ́ ìsìn nínú àgọ́ ìpàdé,+ 44  àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nípa ìdílé wọn wá jẹ́ ẹgbẹ̀rìndínlógún.+ 45  Ìwọ̀nyí ni àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ìdílé àwọn ọmọ Mérárì, àwọn tí Mósè àti Áárónì forúkọ wọn sílẹ̀ nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà nípasẹ̀ Mósè.+ 46  Gbogbo àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀, àwọn tí Mósè àti Áárónì àti àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì forúkọ wọn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Léfì nípa ìdílé wọn àti nípa ilé baba wọn, 47  láti ẹni ọgbọ̀n ọdún sókè sí ẹni àádọ́ta ọdún,+ gbogbo àwọn tí ń wá láti ṣe iṣẹ́ ìsìn tí a fi òpò ṣe àti iṣẹ́ ìsìn gbígbé àwọn ẹrù nínú àgọ́ ìpàdé,+ 48  àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn wá jẹ́ ẹgbẹ̀tàlélógójì  ó dín ogún.+ 49  Nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà ni a fi forúkọ wọn sílẹ̀ nípasẹ̀ Mósè, olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ àti ẹrù rẹ̀; a sì forúkọ wọn sílẹ̀ gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé