Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Númérì 36:1-13

36  Àwọn olórí àwọn baba ti ìdílé àwọn ọmọ Gílíádì ọmọkùnrin Mákírù+ ọmọkùnrin Mánásè ti ìdílé àwọn ọmọ Jósẹ́fù sì bẹ̀rẹ̀ sí sún mọ́ tòsí, wọ́n sì sọ̀rọ̀ níwájú Mósè àti àwọn ìjòyè, àwọn olórí àwọn baba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,  wọ́n sì wí pé: “Jèhófà pàṣẹ fún olúwa mi láti fi ilẹ̀ náà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ogún nípa kèké;+ Jèhófà sì pàṣẹ fún olúwa mi láti fi ogún Sélóféhádì arákùnrin wa fún àwọn ọmọbìnrin+ rẹ̀.  Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ ẹ̀yà mìíràn nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi wọ́n ṣe aya, a ó yọ ogún àwọn obìnrin náà kúrò nínú ogún àwọn baba wa, a ó sì fi kún ogún ti ẹ̀yà tí wọ́n lè wá jẹ́ apá kan rẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé a ó yọ ọ́ kúrò nínú ìpín ogún wa.+  Wàyí o, bí Júbílì+ bá wáyé fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ogún àwọn obìnrin náà pẹ̀lú ni a ó fi kún ogún ti ẹ̀yà tí wọ́n lè wá jẹ́ apá kan rẹ̀; tí ó fi jẹ́ pé a ó yọ ogún wọn kúrò nínú ogún ti ẹ̀yà àwọn baba wa.”  Nígbà náà ni Mósè pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà, pé: “Ẹ̀yà àwọn ọmọ Jósẹ́fù ń sọ ohun tí ó tọ́.  Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà pa láṣẹ fún àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì,+ pé, ‘Ẹni tí ó bá dára ní ojú wọn ni wọ́n lè di aya fún. Kì kì pé kí wọ́n di aya+ fún ìdílé ẹ̀yà àwọn baba wọn.  Kí ogún kankan tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì má ṣe lọ láti ẹ̀yà sí ẹ̀yà, nítorí olúkúlùkù àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti rọ̀ mọ́ ogún ti ẹ̀yà àwọn baba ńlá rẹ̀.  Olúkúlùkù ọmọbìnrin tí ó bá sì rí ogún gbà nínú ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ọ̀kan nínú ìdílé ẹ̀yà baba rẹ̀ ni kí ó di aya+ fún, kí olúkúlùkù ọmọ Ísírẹ́lì lè gba ogún nínú ti àwọn baba ńlá rẹ̀.  Kí ogún kankan má ṣe lọ láti ẹ̀yà kan sí ẹ̀yà mìíràn, nítorí olúkúlùkù ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti rọ̀ mọ́ ogún tirẹ̀.’” 10  Gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì ṣe.+ 11  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Málà, Tírísà àti Hógílà àti Mílíkà àti Nóà, àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì,+ di aya àwọn ọmọkùnrin tí ó jẹ́ arákùnrin baba wọn. 12  Wọ́n di aya fún àwọn kan lára àwọn ìdílé ọmọ Mánásè ọmọkùnrin Jósẹ́fù, kí ogún wọn lè máa wà nìṣó pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀yà ìdílé baba wọn. 13  Ìwọ̀nyí ni àṣẹ+ àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ tí Jèhófà pa láṣẹ nípasẹ̀ Mósè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ Móábù lẹ́bàá Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé