Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Númérì 35:1-34

35  Jèhófà sì ń bá a lọ láti bá Mósè sọ̀rọ̀ ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ Móábù lẹ́bàá Jọ́dánì+ ní Jẹ́ríkò, pé:  “Pa àṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n fún àwọn ọmọ Léfì ní àwọn ìlú ńlá+ láti máa gbé nínú ogún ìní wọn, kí wọ́n sì fún àwọn ọmọ Léfì ní ilẹ̀ ìjẹko àwọn ìlú ńlá tí ó yí wọn ká.+  Kí àwọn ìlú ńlá náà sì wà fún wọn láti máa gbé, nígbà tí ilẹ̀ ìjẹko wọn yóò wà fún àwọn ẹran agbéléjẹ̀ wọn àti àwọn ẹrù wọn àti fún gbogbo ẹranko wọn.  Ilẹ̀ ìjẹko àwọn ìlú ńlá náà, èyí tí ẹ ó fi fún àwọn ọmọ Léfì, yóò sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ yí ká láti ògiri ìlú ńlá náà sóde.  Kí ẹ sì díwọ̀n ẹgbàá ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà ìlà-oòrùn òde ìlú ńlá náà àti ẹgbàá ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà gúúsù àti ẹgbàá ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà ìwọ̀-oòrùn àti ẹgbàá ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà àríwá, ìlú ńlá náà yóò wà ní àárín. Èyí yóò wà fún wọn gẹ́gẹ́ bí àwọn ilẹ̀ ìjẹko àwọn ìlú ńlá náà.  “Ìwọ̀nyí ni àwọn ìlú ńlá tí ẹ ó fi fún àwọn ọmọ Léfì: ìlú ńlá mẹ́fà fún ìsádi,+ èyí tí ẹ ó fi fún apànìyàn láti sá lọ síbẹ̀,+ yàtọ̀ sí wọn, ẹ ó sì fi àwọn ìlú ńlá méjì -lé-lógójì mìíràn fún wọn.  Gbogbo ìlú ńlá tí ẹ ó fi fún àwọn ọmọ Léfì yóò jẹ́ ìlú ńlá méjì -dín-láàádọ́ta, àwọn pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko wọn.+  Àwọn ìlú ńlá tí ẹ ó fi fún wọn yóò jẹ́ láti inú ohun ìní àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ Nínú àwọn púpọ̀ ni ẹ ó ti mú púpọ̀, àti nínú àwọn díẹ̀ ni ẹ ó ti mú díẹ̀.+ Olúkúlùkù, ní ìwọ̀n ogún rẹ̀ tí yóò gbà gẹ́gẹ́ bí ohun ìní, ni yóò ti fún àwọn ọmọ Léfì nínú àwọn ìlú ńlá rẹ̀.”  Jèhófà sì ń bá a lọ láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: 10  “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ ń sọdá Jọ́dánì lọ sí ilẹ̀ Kénáánì.+ 11  Kí ẹ sì yan àwọn ìlú ńlá tí ó wọ̀ fún ara yín. Wọn yóò jẹ́ àwọn ìlú ńlá ìsádi fún yín, kí apànìyàn tí ó kọlu ọkàn kan lọ́nà tí ó yọrí sí ikú láìmọ̀ọ́mọ̀+ sì sá lọ sí ibẹ̀. 12  Kí àwọn ìlú ńlá náà sì jẹ́ ibi ìsádi fún yín kúrò lọ́wọ́ olùgbẹ̀san+ ẹ̀jẹ̀, kí apànìyàn náà má bàa kú títí yóò fi dúró níwájú àpéjọ fún ìdájọ́.+ 13  Àwọn ìlú ńlá tí ẹ óò fún wọn, ìlú ńlá mẹ́fà fún ìsádi, yóò sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún ìlò yín. 14  Ìlú ńlá mẹ́ta ni ẹ óò fún wọn ní ìhà ìhín Jọ́dánì,+ ìlú ńlá mẹ́ta ni ẹ ó sì fún wọn ní ilẹ̀ Kénáánì.+ Wọn yóò wà gẹ́gẹ́ bí àwọn ìlú ńlá ìsádi. 15  Ìlú ńlá mẹ́fà wọ̀nyí yóò jẹ́ ibi ìsádi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti fún àtìpó+ àti fún olùtẹ̀dó sí àárín wọn, fún ẹnikẹ́ni tí ó kọlu ọkàn kan lọ́nà tí ó yọrí sí ikú láìmọ̀ọ́mọ̀+ láti sá lọ sí ibẹ̀. 16  “‘Wàyí o, bí ó bá jẹ́ ohun èlò irin ni ó fi kọlù ú tí ó fi kú, òṣìkàpànìyàn+ ni. Láìkùnà, òṣìkàpànìyàn náà ni kí a fi ikú pa.+ 17  Bí ó bá sì jẹ́ òkúta kékeré tí ó lè ṣekú pa á ni ó fi kọlù ú tí ó fi kú, òṣìkàpànìyàn ni. Láìkùnà, òṣìkàpànìyàn náà ni kí a fi ikú pa. 18  Bí ó bá sì jẹ́ ohun èlò kékeré tí ó jẹ́ igi tí ó lè ṣekú pa á ni ó fi kọlù ú tí ó fi kú, òṣìkàpànìyàn ni. Láìkùnà, òṣìkàpànìyàn náà ni kí a fi ikú pa. 19  “‘Olùgbẹ̀san+ ẹ̀jẹ̀ ni ẹni tí yóò fi ikú pa òṣìkàpànìyàn náà. Nígbà tí ó bá rí i lọ́nà àkọsẹ̀bá, òun fúnra rẹ̀ yóò fi ikú pa á. 20  Bí ó bá sì jẹ́ pé láti inú ìkórìíra ni ó fi tì í+ tàbí tí ó sọ nǹkan lù ú nígbà tí ó lùgọ+ dè é kí ó bàa lè kú, 21  tàbí láti inú ìṣọ̀tá ni ó ti fi ọwọ́ lù ú kí ó bàa lè kú, láìkùnà, akọluni náà ni kí a fi ikú pa. Òṣìkàpànìyàn ni. Olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ yóò fi ikú pa òṣìkàpànìyàn náà nígbà tí ó bá rí i lọ́nà àkọsẹ̀bá.+ 22  “‘Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ ní àìròtẹ́lẹ̀ láìsí ìṣọ̀tá ni ó tì í tàbí ni ó sọ ohun èlò èyíkéyìí sí i láìlúgọ+ dè é, 23  tàbí òkúta èyíkéyìí èyí tí ó lè ṣekú pa á láìrí i tàbí tí ó bá mú kí ó ṣubú lù ú, tí ó fi kú, nígbà tí kò bá a ṣọ̀tá, tí kò sì wá ìṣeléṣe rẹ̀, 24  nígbà náà ni kí àpéjọ ṣe ìdájọ́ láàárín akọluni àti olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìdájọ́ wọ̀nyí.+ 25  Kí àpéjọ+ sì dá apànìyàn náà nídè kúrò ní ọwọ́ olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀, kí àpéjọ sì dá a padà sí ìlú ńlá ìsádi rẹ̀ inú èyí tí ó sá sí, kí ó sì máa gbé nínú rẹ̀ títí di ìgbà ikú àlùfáà àgbà tí a fi òróró mímọ́ yàn.+ 26  “‘Ṣùgbọ́n, láìkùnà, bí apànìyàn náà bá jáde kúrò ní ààlà ìlú ńlá ìsádi rẹ̀ inú èyí tí ó sá sí, 27  tí olùgbẹ̀san+ ẹ̀jẹ̀ sì rí i ní òde ààlà ìlú ńlá ìsádi rẹ̀, tí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ sì pa apànìyàn náà, òun kò ní ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. 28  Nítorí ó yẹ kí ó máa gbé nínú ìlú ńlá ìsádi rẹ̀ títí di ìgbà ikú+ àlùfáà àgbà, lẹ́yìn ikú àlùfáà àgbà, apànìyàn náà lè padà sí ilẹ̀ ìní rẹ̀. 29  Kí ìwọ̀nyí sì jẹ́ ìlànà àgbékalẹ̀ ìdájọ́ fún yín jálẹ̀ ìran-ìran yín ní gbogbo àwọn ibi gbígbé yín. 30  “‘Olúkúlùkù ẹni tí ó kọlu ọkàn kan lọ́nà tí ó yọrí sí ikú ni kí a pa gẹ́gẹ́ bí òṣìkàpànìyàn+ ní ẹnu àwọn ẹlẹ́rìí,+ ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo kì yóò jẹ́rìí lòdì sí ọkàn kan fún un láti kú. 31  Kí ẹ má sì gba ìràpadà fún ọkàn òṣìkàpànìyàn tí ó yẹ kí ó kú,+ nítorí láìkùnà, kí a fi ikú pa á.+ 32  Kí ẹ má sì gba ìràpadà fún ẹnì kan tí ó sá lọ sí ìlú ńlá ìsádi rẹ̀, láti tún bẹ̀rẹ̀ sí máa gbé nínú ilẹ̀ náà ṣáájú ikú àlùfáà àgbà. 33  “‘Kí ẹ má sì sọ ilẹ̀ tí ẹ wà nínú rẹ̀ di eléèérí; nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ní ń sọ ilẹ̀ di eléèérí,+ kò sì sí ètùtù tí a lè ṣe sí ilẹ̀ ní ti ẹ̀jẹ̀ tí a ta sórí rẹ̀ bí kò ṣe nípa ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó ta á sílẹ̀.+ 34  Kí o má sì sọ ilẹ̀ tí ẹ ń gbé inú rẹ̀ di ẹlẹ́gbin, ní àárín èyí tí èmi ń gbé; nítorí èmi Jèhófà ń gbé ní àárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé