Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Númérì 34:1-29

34  Jèhófà sì bá Mósè sọ̀rọ̀ síwájú sí i, pé:  “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin ń lọ sí ilẹ̀ Kénáánì.+ Èyí ni ilẹ̀ tí yóò bọ́ sọ́wọ́ yín nípa ogún,+ ilẹ̀ Kénáánì gẹ́gẹ́ bí àwọn ààlà rẹ̀.+  “‘Kí ìhà gúúsù yín sì jẹ́ láti aginjù Síínì lẹ́gbẹ̀ẹ́ Édómù,+ kí ààlà gúúsù yín sì jẹ́ láti ìkángun Òkun Iyọ̀+ ní ìlà-oòrùn.  Kí ààlà yín sì yí láti gúúsù ti ìgòkè Ákírábímù,+ kí ó sì sọdá lọ sí Síínì, kí ibi ìdópinsí rẹ̀ sì jẹ́ ní gúúsù Kadeṣi-báníà;+ kí ó sì lọ dé Hasari-ádáárì+ àti ré kọjá lọ sí Ásímónì.  Kí ààlà náà sì yí ní Ásímónì lọ dé àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Íjíbítì,+ kí ibi ìdópinsí rẹ̀ sì jẹ́ Òkun.+  “‘Ní ti ààlà ìwọ̀-oòrùn,+ kí ó wà ní Òkun Ńlá àti ilẹ̀ èbúté fún yín. Èyí ni yóò jẹ́ ààlà ìwọ̀-oòrùn yín.  “‘Wàyí o, èyí ni yóò jẹ́ ààlà àríwá yín: Kí ẹ sàmì sí i láti Òkun Ńlá dé Òkè Ńlá Hóórì+ gẹ́gẹ́ bí ààlà fún ara yín.  Kí ẹ sàmì sí ààlà náà láti Òkè Ńlá Hóórì dé àtiwọ Hámátì,+ kí ibi ìdópinsí ààlà náà sì jẹ́ Sédádì.+  Kí ààlà náà sì lọ dé Sífírónì, kí ibi ìdópinsí rẹ̀ sì jẹ́ Hasari-énánì.+ Èyí ni yóò jẹ́ ààlà àríwá yín. 10  “‘Nígbà náà ni kí ẹ sàmì sí i láti Hasari-énánì dé Ṣẹ́fámù fún ara yín gẹ́gẹ́ bí ààlà yín ní ìlà-oòrùn. 11  Kí ààlà náà sì sọ̀ kalẹ̀ láti Ṣẹ́fámù lọ dé Ríbúlà ní ìlà-oòrùn Áyínì, kí ojú ààlà náà sì sọ̀ kalẹ̀ dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ìhà ìlà-oòrùn òkun Kínérétì.+ 12  Kí ojú ààlà náà sì sọ̀ kalẹ̀ lọ dé Jọ́dánì, kí ibi ìdópinsí rẹ̀ sì jẹ́ Òkun Iyọ̀.+ Èyí ni yóò jẹ́ ilẹ̀ yín+ gẹ́gẹ́ bí ààlà rẹ̀ gbogbo yí ká.’” 13  Nítorí náà, Mósè pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, pé: “Èyí ni ilẹ̀ náà tí ẹ ó pín nípa kèké+ fún ara yín gẹ́gẹ́ bí ohun ìní, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ láti fi fún ẹ̀yà mẹ́sàn-án àti ààbọ̀ náà.+ 14  Nítorí ẹ̀yà àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ní ìbámu pẹ̀lú ilé àwọn baba wọn àti ẹ̀yà àwọn ọmọ Gádì ní ìbámu pẹ̀lú ilé àwọn baba wọn ti mú, ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè sì ti mú ogún tiwọn.+ 15  Ẹ̀yà méjèèjì àti ààbọ̀ ti gba ogún wọn ní ẹkùn ilẹ̀ Jọ́dánì lẹ́bàá Jẹ́ríkò níhà ìlà-oòrùn níhà yíyọ oòrùn.”+ 16  Jèhófà sì bá Mósè sọ̀rọ̀ síwájú sí i, pé: 17  “Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọkùnrin tí yóò pín ilẹ̀ náà fún yín gẹ́gẹ́ bí ohun ìní, Élíásárì+ àlùfáà àti Jóṣúà ọmọkùnrin Núnì.+ 18  Ẹ̀yin yóò sì mú ìjòyè kan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan láti pín ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ohun ìní.+ 19  Ìwọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn ọkùnrin náà: Láti inú ẹ̀yà Júdà,+ Kálébù ọmọkùnrin Jéfúnè;+ 20  àti láti inú ẹ̀yà àwọn ọmọ Síméónì,+ Ṣẹ́múẹ́lì ọmọkùnrin Ámíhúdù; 21  láti inú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì,+ Élídádì ọmọkùnrin Kísílónì; 22  àti láti inú ẹ̀yà àwọn ọmọ Dánì,+ ìjòyè kan, Búkì ọmọkùnrin Jógílì; 23  láti inú ẹ̀yà àwọn ọmọ Jósẹ́fù,+ láti inú ẹ̀yà àwọn ọmọ Mánásè,+ ìjòyè kan, Háníélì ọmọkùnrin Éfódì; 24  àti láti inú ẹ̀yà àwọn ọmọ Éfúráímù,+ ìjòyè kan, Kémúélì ọmọkùnrin Ṣífútánì; 25  àti láti inú ẹ̀yà àwọn ọmọ Sébúlúnì,+ ìjòyè kan, Élísáfánì ọmọkùnrin Pánákì; 26  àti láti inú ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísákárì,+ ìjòyè kan, Pálítíélì ọmọkùnrin Ásánì; 27  àti láti inú ẹ̀yà àwọn ọmọ Áṣérì,+ ìjòyè kan, Áhíhúdù ọmọkùnrin Ṣẹ́lómì; 28  àti láti inú ẹ̀yà àwọn ọmọ Náfútálì,+ ìjòyè kan, Pédáhélì ọmọkùnrin Ámíhúdù.” 29  Ìwọ̀nyí ni àwọn tí Jèhófà pàṣẹ fún pé kí wọ́n sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di olùni ilẹ̀ ní ilẹ̀ Kénáánì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé