Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Númérì 33:1-56

33  Ìwọ̀nyí ni ipele-ipele ìrìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì+ ní ẹgbẹ́ ọmọ ogun+ wọn nípa ọwọ́ Mósè àti Áárónì.+  Mósè sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣe àkọsílẹ̀ àwọn ibi ìjádelọ ní ipele-ipele ìrìn wọn nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà; ìwọ̀nyí sì ni àwọn ipele-ipele ìrìn wọn láti ibi ìjádelọ kan sí òmíràn:+  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣí kúrò ní Rámésésì+ ní oṣù kìíní, ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kìíní.+ Ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé ìrékọjá+ gan-an ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde lọ pẹ̀lú ọwọ́ ríròkè lójú gbogbo àwọn ará Íjíbítì.+  Ní gbogbo ìgbà náà, àwọn ará Íjíbítì ń sin àwọn tí Jèhófà ti kọlù lára wọn, èyíinì ni, gbogbo àkọ́bí;+ Jèhófà sì ti mú ìdájọ́+ ṣẹ ní kíkún lórí àwọn ọlọ́run wọn.  Nítorí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣí kúrò ní Rámésésì,+ wọ́n sì dó sí Súkótù.+  Nígbà náà, wọ́n ṣí kúrò ní Súkótù, wọ́n sì dó sí Étámù,+ èyí tí ó wà ní etí aginjù.  Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣí kúrò ní Étámù, wọ́n sì yí padà síhà Píháhírótì,+ èyí tí ó dojú kọ Baali-séfónì;+ wọ́n sì dó síwájú Mígídólì.+  Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n ṣí kúrò ní Píháhírótì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí la àárín òkun+ kọjá lọ sí aginjù,+ wọ́n sì ń lọ ní ìrìn àjò ọlọ́jọ́ mẹ́ta ní aginjù Étámù,+ wọ́n sì dó sí Máráhì.+  Nígbà náà, wọ́n ṣí kúrò ní Máráhì, wọ́n sì wá sí Élímù.+ Wàyí o, ìsun omi méjì lá àti àádọ́rin igi ọ̀pẹ wà ní Élímù. Nítorí náà, wọ́n dó síbẹ̀. 10  Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣí kúrò ní Élímù, wọ́n sì dó sẹ́bàá Òkun Pupa. 11  Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n ṣí kúrò ní Òkun Pupa, wọ́n sì dó sí aginjù Sínì.+ 12  Nígbà náà, wọ́n ṣí kúrò ní aginjù Sínì, wọ́n sì dó sí Dófíkà. 13  Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣí kúrò ní Dófíkà, wọ́n sì dó sí Álúṣì. 14  Wọ́n ṣí kúrò ní Álúṣì lẹ́yìn náà, wọ́n sì dó sí Réfídímù.+ Kò sì sí omi níbẹ̀ fún àwọn ènìyàn náà láti mú. 15  Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n ṣí kúrò ní Réfídímù, wọ́n sì dó sí aginjù Sínáì.+ 16  Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣí kúrò ní aginjù Sínáì, wọ́n sì dó sí Kiburoti-hátááfà.+ 17  Nígbà náà, wọ́n ṣí kúrò ní Kiburoti-hátááfà, wọ́n sì dó sí Hásérótì.+ 18  Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n ṣí kúrò ní Hásérótì, wọ́n sì dó sí Rítímà. 19  Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣí kúrò ní Rítímà, wọ́n sì dó sí Rimoni-pérésì. 20  Nígbà náà, wọ́n ṣí kúrò ní Rimoni-pérésì, wọ́n sì dó sí Líbínà. 21  Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣí kúrò ní Líbínà, wọ́n sì dó sí Rísà. 22  Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣí kúrò ní Rísà, wọ́n sì dó sí Kéhélátà. 23  Nígbà náà, wọ́n ṣí kúrò ní Kéhélátà, wọ́n sì dó sí Òkè Ńlá Ṣéférì. 24  Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n ṣí kúrò ní Òkè Ńlá Ṣéférì, wọ́n sì dó+ sí Hárádà. 25  Nígbà náà, wọ́n ṣí kúrò ní Hárádà, wọ́n sì dó sí Mákélótì. 26  Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣí kúrò+ ní Mákélótì, wọ́n sì dó sí Táhátì. 27  Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n ṣí kúrò ní Táhátì, wọ́n sì dó sí Térà. 28  Nígbà náà, wọ́n ṣí kúrò ní Térà, wọ́n sì dó sí Mítíkà. 29  Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣí kúrò ní Mítíkà, wọ́n sì dó sí Háṣímónà. 30  Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣí kúrò ní Háṣímónà, wọ́n sì dó sí Mósérótì. 31  Nígbà náà, wọ́n ṣí kúrò ní Mósérótì, wọ́n sì dó sí Bẹne-jáákánì.+ 32  Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n ṣí kúrò ní Bẹne-jáákánì, wọ́n sì dó sí Hoori-hágígádì. 33  Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣí kúrò ní Hoori-hágígádì, wọ́n sì dó sí Jótíbátà.+ 34  Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣí kúrò ní Jótíbátà, wọ́n sì dó sí Ábúrónà. 35  Nígbà náà, wọ́n ṣí kúrò ní Ábúrónà, wọ́n sì dó sí Esioni-gébérì.+ 36  Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n ṣí kúrò ní Esioni-gébérì, wọ́n sì dó sí aginjù Síínì,+ èyíinì ni, Kádéṣì. 37  Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣí kúrò ní Kádéṣì, wọ́n sì dó sí Òkè Ńlá Hóórì,+ ní ààlà ilẹ̀ ti ilẹ̀ Édómù. 38  Áárónì àlùfáà sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ sí Òkè Ńlá Hóórì nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà, kí ó sì kú níbẹ̀ ní ọdún ogójì  tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, ní oṣù karùn-ún, ní ọjọ́ kìíní oṣu náà.+ 39  Áárónì sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́fà nígbà ikú rẹ̀ ní Òkè Ńlá Hóórì. 40  Wàyí o, ọmọ Kénáánì náà, ọba Árádì,+ bí ó ti jẹ́ pé ó ń gbé ní Négébù,+ ní ilẹ̀ Kénáánì, wá gbọ́ nípa dídé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 41  Nígbà tí ó ṣe, wọ́n ṣí kúrò ní Òkè Ńlá Hóórì,+ wọ́n sì dó sí Sálímónà. 42  Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n ṣí kúrò ní Sálímónà, wọ́n sì dó sí Púnónì. 43  Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣí kúrò ní Púnónì, wọ́n sì dó sí Óbótì.+ 44  Nígbà náà, wọ́n ṣí kúrò ní Óbótì, wọ́n sì dó sí Iye-ábárímù ní ojú ààlà Móábù.+ 45  Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣí kúrò ní Íyímù, wọ́n sì dó sí Diboni-gádì.+ 46  Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n ṣí kúrò ní Diboni-gádì, wọ́n sì dó sí Alimoni-díbílátáímù.+ 47  Nígbà náà, wọ́n ṣí kúrò ní Alimoni-díbílátáímù, wọ́n sì dó sí àwọn òkè ńlá Ábárímù+ níwájú Nébò.+ 48  Níkẹyìn, wọ́n ṣí kúrò ní àwọn òkè ńlá Ábárímù, wọ́n sì dó sí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ Móábù+ sẹ́bàá Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò. 49  Wọ́n sì ń bá a lọ láti dó sẹ́bàá Jọ́dánì láti Bẹti-jẹ́ṣímótì+ dé Ebẹli-ṣítímù+ ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ Móábù. 50  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí bá Mósè sọ̀rọ̀ ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ Móábù lẹ́bàá Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò,+ pé: 51  “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin ń sọdá Jọ́dánì sí ilẹ̀ Kénáánì.+ 52  Kí ẹ sì lé gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ náà kúrò níwájú yín, kí ẹ sì pa gbogbo àwòrán àfòkútaṣe+ wọn run, gbogbo àwọn ère wọn tí a fi irin+ dídà ṣe sì ni kí ẹ pa run, gbogbo àwọn ibi gíga ọlọ́wọ̀ wọn sì ni kí ẹ pa rẹ́ ráúráú.+ 53  Kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà, kí ẹ sì máa gbé nínú rẹ̀, nítorí pé ẹ̀yin ni èmi yóò fi ilẹ̀ náà fún dájúdájú láti gbà á.+ 54  Kí ẹ sì pín ilẹ̀ náà fún ara yín gẹ́gẹ́ bí ohun ìní nípa kèké+ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìdílé yín.+ Fún ẹni tí ó jẹ́ elénìyàn púpọ̀, kí ẹ bù sí ogún rẹ̀, fún ẹni tí ó jẹ́ díẹ̀, kí ẹ sì dín ogún rẹ̀ kù.+ Ibi tí kèké bá jáde sí fún un, ibẹ̀ ni yóò di tirẹ̀.+ Nípa ẹ̀yà àwọn baba yín ni kí ẹ pèsè ilẹ̀ ìní fún ara yín.+ 55  “‘Bí ó ti wù kí ó rí, bí ẹ kò bá lé àwọn olùgbé ilẹ̀ náà kúrò níwájú yín,+ nígbà náà, àwọn tí ẹ bá fi sílẹ̀ lára wọn dájúdájú yóò di àwọn ohun ṣóṣóró ní ojú yín àti gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀gún ní ìhà yín, ní tòótọ́, wọn yóò sì fòòró yín lórí ilẹ̀ náà tí ẹ̀yin yóò máa gbé.+ 56  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé gẹ́gẹ́ bí mo ti gbèrò gan-an láti ṣe sí wọn ni èmi yóò ṣe sí yín.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé